Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí mẹ́fà lórí ikú Emir Ajagungbade l'Osun

Oríṣun àwòrán, others/getty images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti fi oju awọn afurasi mẹfa to lọwọ ninu iku gbajugbaja ọmọ ẹyin oloṣelu kan ti wọn pe ni Olalekan Oyeyemi han fawọn akọroyin.
Laipẹ yii ni ọlọpaa sọ pe iwadii kikun ti awọn ṣe lori ikọlu ti wọn ti ṣeku pa Oyeyemi, ẹni tọpọ mọ si Emir Ajagungbade lo tu aṣiri awọn mẹfa naa.
Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2026 ni rogbodiyan to ṣeku pa Emir Ajagungbade waye ni agbegbe Mayfair to wa niluu Ile-Ife, ipinlẹ naa.
Asiko ti wọn sọ pe eto lati bura fun oloogbe naa gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awakọ nipinlẹ naa n lọ lọwọ, wọn ṣeku pa a.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni wọn fẹẹ bura fun Emir Ajagungbade lati maa tukọ ẹgbẹ awakọ, ni wọn lawọn janduku lọ ṣe ikọlu si i, ti wọn si gbẹmi rẹ.
Latigba naa lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii wọn, ko to di pe ọwọ tẹ gbogbo awọn afurasi ọhun.
Nigba ti ọlọpaa n foju awọn afurasi naa han laipẹ yii niluu Osogbo, ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Ibrahim Zungura sọ pe wọn ko nii lọ lai jiya labẹ ofin, lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.Ọga olọpaa naa naa sọ pe awọn ri ibọn ilewọ kan gba lọwọ awọn afurasi naa, lasiko tọwọ palaba wọn segi.
Tijani Ismail, Akinsola Ekundayo, Sijuade Moruf Oyinlola, Ayeni Adegbola Olalekan, Hammed Olalekan Dauda tọpọ mọ si Jagban, ati Waliu Adejare ti wọn tun n pe ni JayJay, lawọn afurasi tọwọ tẹ naa.
Báwo lọwọ́ ṣe tẹ̀ wọ́n?
Zungura nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, sọ pe, "lọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni awọn gba ipe pajawiri wi pe awọn agbebọn ti ko ogun wọ garaaji Mayfair to wa niluu Ile-Ife, ti wọ si n yinbọn lakọklakọ.
"Nibẹ ni ibọn ti ba oloogbe naa, to si ku loju ẹsẹ. A tun gbọ ijamba ọkọ kan tun ti ṣẹlẹ ni ile-epo Energy to wa loju ọna marosẹ Ile-Ife si Ibadan.
"Nipasẹ iṣẹ iwadii kikun ti ọlọpaa ṣe, a rọwọ to awọn afurasi mẹrin to lọwọ ninu iwa ọdaran naa, pẹlu iranlọwọ ọga agba Amotekun.
"Iwadii siwaju sii lo tun jẹ kọwọ tẹ afurasi kan to n jẹ Hammed Olalekan Dauda, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Jagaban, ọwọ rẹ la si ti gba ibọn ilewọ kan."
Siwaju sii ni Zungura ṣalaye pe lasiko ti wọn n fọwọ wa Jagaban lẹnu wo, lo ti jẹ ko di mimọ pe ẹnikan to n jẹ Nurudeen Alowonle, toun naa jẹ alabaṣiṣẹpọ Gomina Ademola Adeleke lo foun ni ibọn ọhun.
"Iwadii ti a ṣe lo pada jẹ ki ọwọ tẹ Waliu Adejare ti inagijẹ rẹ n jẹ JayJay, amugbalẹgbẹ Nurudeen Alowonle lori iṣẹlẹ naa.
"Gbogbo awọn afurasi yii ni Nurudeen Alowonle ati Adeyemi Ojo ti wọn tun n pe ni Sibi n gbe dide fun ikọlu naa," Zungura fi kun ọrọ rẹ.
Afurasí tó bá BBC sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé...
Ọkan lara awọn afurasi naa, lasiko ti wọn n dahun ibeere jẹ ko di mimọ pe Nurudeen Alowonle ni awọn n ṣiṣẹ fun, oun si lo ṣagbatẹru awọn lọ sibi ti wọn ti lọ ṣe ikọlu.
Olalekan Dauda, ọkan lara awọn afurasi naa sọ pe ibọn ti wọn gba lọwọ oun, kii ṣe toun, bi ko ṣe pe ọga oun Nurudeen Alowonle lo mu foun.
"Kii ṣe emi ni mo ni ibọn ti awọn ọlọpaa ba lọwọ mi. Ọga mi, Nurudeen Alowonle lo fun mi, nigba ti Asiri Eniba fẹẹ gba garaaji," Dauda sọ bẹẹ.
"Alowonle lo fun mi ni ibọn naa lati fi si ara mi lọjọ ti wọn ja ija ni garaaji to wa ni agbegbe aregbe niluu Osogbo. Awọn Asiri Eniba lo n bọ lati wa gba garaaji gẹgẹ bi a ṣe mọ pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni wọ jẹ.
"Bi mo ṣe gbọ eyi, ni mo ti fi gbogbo awọn to wa ni garaaji lọkan balẹ pe ko sewu fun wọn rara. Mo ni ki onikaluku maa ba iṣẹ rẹ lọ, emi naa si duro deedee lọjọ naa.
"Ṣugbọn nigba ti awọn janduku Asiri Eniba de lati mu mi lọ, awọn ọlọpaa ti wọ ni ki wọn maa ṣọ garaaji lo gba mi silẹ lọwọ wọn.
"Nibi ti a ti n fa ọrọ naa ni wọn ti ba ibọn ni ara mi, ibọn naa lo si jẹ ti ọga mi, Nurudeen Alowonle, eyi to ni ki n mu dani. Ibọn yii lo si gbe mi de ahaamọ ọlọpaa," O sọ bẹẹ fun BBC.
"Èmi kọ́ ni mo pa Emir Ajagungbade"
Afurasi miran, Sijuade Oyinlola Moruf to jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ eleto aabo Amotekun nipinlẹ Osun, ẹni ti wọn fi sẹyin Alowonle tii ṣe alaga ẹgbẹ awakọ naa tun ba BBC sọrọ, to si ni oun ko mọ nnkankan nipa iku Emir Ajagungbade.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ fun BBC pe, "Mo wa nibẹ lọjọ ti wọn pa Emir Ajagungbade nitori pe ọga ti oun wa lẹyin rẹ ni. Nurudeen Alowonle lo sọ pe ka lọ sibi ipade ti wọn fẹẹ ṣe pẹlu Emir Ajagungbade ni ilu Ile-Ife lọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan, ọdun yii.
"Mo gbera lati ilu Osogbo lọ si ilu Ile-Ife lọjọ naa, ṣugbọn bi mo ṣe debẹ ni mo ba awọn janduku ti wọn ti duro sibi ti ipade ti fẹẹ waye, bẹẹ si lawọn janduku miran tun wa ba wa nibẹ.
"Ko pẹ rara ni mo bẹrẹ sii gbọ iro ibọn, to n dun lakọlakọ. Ka too diju ka la, wọn ti yinbọn fun Emir Ajagungbade. Eyi lo jẹ ki awa naa daabo bo ara wa, ti a si tete gbe mọto wa kuro nibẹ," o ṣalaye.
Siwaju sii lo tun jẹ ko di mimọ pe oun kọ ohunkohun nipa iku Emir Ajagungbade, ṣugbọn nitori pe oun jẹ oṣiṣẹ Amotekun to wa lẹyin Alowonle ni wọn ṣe fẹẹ koba oun.
"Emi kọ ni mo pa Emir Ajagungbade, ṣugbọn nitori pe mo jẹ ẹṣọ aabo Amotẹkun, ati pe ẹyin Nurudeen Alowonle ni mo wa, oun si lo ran mi lọ sibẹ lọjọ naa niluu Ile-Ife ni wọn ṣe lero wi pe emi ni mo pa a," o sọ bẹẹ fun BBC.
Taa ni Nurudeen Alowonle?
Nurudeen Alowonle jẹ alaga fun ẹgbẹ awọn awakọ ero nipinlẹ Ọsun, bakan naa lo tun jẹ janduku oloṣelu, to si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Accord.
Alowonle ni ẹni ti wọn fẹẹ gba ipo alaga naa lọwọ rẹ, lati gbe e fun Olalekan Oyeyemi tii ṣe Emir Ajagungbade.
Lọjọ ti iṣẹlẹ iku Emir Ajagungbade waye ni Nurudeen Alowonle ti ṣe fọnran kan sita wi pe oun ko kuro niluu Osogbo lọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan, ọdun yii.
O loun ko mọ ohunkohun nipa iku Emir Ajagungbade, nitori pe oun ko si nibi ti wọn ti pa a.
Ṣugbọn ni bayii, ninu ọrọ ti awọn afurasi naa sọ, wọn jẹ ko di mimọ pe Alowonle lo ran oun niṣẹ lọ siluu Ile-Ife lọjọ ti wọn pa Emir Ajagungbade.


























