Amẹ́ríkà kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní Nàíjíríà, ohun tó fàá rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka eto aabo ti ti bẹrẹ sii sọrọ lori ipinnu ilẹ Amẹrika lati ko ikọ ọmọ ogun rẹ kuro nilẹ Naijiria lori ajọṣepọ lati gbogun ti awọn agbesunmọmi lẹkun Lake Chad.
Awọn akọṣẹmọṣẹ naa lo n sọrọ lẹyin ọrọ ti ọgagun ilẹ Amẹrika nilẹ Afrika ati Yuroopu, Ọgagun Dagvin RM Anderson, lasiko ipade awọn oniroyin to waye nibi ipade eto aabo ilẹ Afrika ti ọdun 2026 to waye.
Lasiko ipade awọn akọroyin naa, Labaran ṣalaye pe ilẹ Amẹrika ti ko ipa tirẹ nipa pinpin awọn ohun to mọ, ninu igbiyanju orileede naa lati gbogun ti awọn agbesunmọmi lodi ti ISIS ati Daesh.
Ni ibẹrẹ ọdun yii, ilẹ Amẹrika ran ikọ ọmọ ogun rẹ lọ si Naijiria, lojuna lati wa iyanju si bi wọn ṣe n pa awọn ẹlẹsin Kristiẹni nipakupa.
'A ti yanju wahala bi wọn ṣe n pa awọn Kristiẹni ni Naijiria'
Igbesẹ naa lo waye lẹyin ti Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donal Trump sọ laipẹ yii pe Amẹrika ti yanju gbogbo ohun to n jẹ ipaniyan awọn Kristiẹni nilẹ Naijiria.
Ninu oṣu Karun-un, ọdun yii, ileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika pa olori ikọ agbesunmọmi ISIS, Abu Bilal Almainuki, nibi ikọlu ti awọn ọmọ naa ṣe nipa ajọṣepọ pẹlu awọn ọmọ ogun Naijiria.
Lọdun to kọja, Aarẹ Trump sọrọ lori bi wọn ṣe n pa awọn Kristiẹni nilẹ Naijiria, to si ṣeleri wi pe oun yoo mu iyanju sii.
Ṣugbọn ṣa, ijọba ilẹ Naijiria sọ pe ko sohun to jọ pe wọn n ṣe ikọlu s'awọn ẹlẹsin Kristiẹni lorileede naa.
Njẹ wiwa ọmọ ogun Amẹrika si Naijiria so eso rere bi?
Ọmọwe Audu Bulama Bukarti, to jẹ akọṣẹmọṣẹ lẹka eto aabo nilẹ Afrika, sọ fun BBC pe oun nigbagbọ wi pe bi awọn ọmọ ogun ṣe wa ni Naijiria kii ṣe ọna abayọ.
O sọ pe, "Mo tiẹ lero wi pe awọn ọmọ ogun naa yoo duro pẹ ni Naijiria ni, nitori ohun ti wọn sọ ni pe awọn wa lati ran Naijiria lọwọ lati gbogun ti awọn Boko Haram. Ṣugbọn ohun ti a mọ ni pe nnkan gboogi ti wọn ṣe ninu igbiyanju lati gbogun ti Boko Haram ni wọn ṣe pa Abu Bilal al Mainoki, ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ.
"Bi wọn ṣe pa awọn ọmọ ogun Boko Haram yii jẹ ọkan pataki lati tẹsiwaju, to si jẹ ifasẹyin fun ikọ naa," ọ sọ bẹẹ.
Bukarti sọ pe, "A nigbagbọ pe awọn ọmọ ogun ilẹ Amẹrika yii yoo tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ naa, titi digba ti wọn yoo fi kapa ikọ Boko Haram patapata, ti wọn yoo si kede pe awọn ti juwọ silẹ."
O sọ pe "Ko da, ni iwo Naijiria, a le sọ pe rirẹwa kọ lo n san owo ọṣẹ, ṣugbọn bi wọn ba ṣi tẹsiwaju lati maa gbe nibi titi digba ti wọn yoo fi kapa awọn Boko Haram ati agbebọn-aṣekupani, igba naa la ṣẹṣẹ le sọ pe rirẹwa lo n san owo ọṣẹ.
"Ṣugbọn lọdọ awọn Amẹrika, rirẹwa ti san owo ọṣẹ, nitori pe ni kete ti wọn ti kede wi pe awọn n bọ, a sọ pe anfaani oṣelu lo jẹ fun aarẹ lati san owo gbogbo awọn nnkan to nilo," o sọ bẹẹ.
Akọṣẹmọṣẹ eleto aabo naa sọ pe, "Ni bayii, mo lero wi pe ikọ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika yoo fi Naijiria siẹ, ohun ti wọn nilo ni pe ki ilẹ Amẹrika ati Naijiria ni ibaṣepọ, awọn orileede to wa ni Guusu, lati ta awọn ohun elo ti Naijiria nilo lati gbogun ti awọn agbebọn ati agbesunmọmi fun wọn, ati pe bi ohunkohun ba wa ti Naijiria ko ni, ki wọn dide iranwọ fun wọn,"
Ninu oṣu Keji, ọdun 2026, ilẹ Amẹrika kede pe ohun yoo ran ikọ ọmọ ogun ti ko din ni igba si Naijiria, lati kọ awọn ọmọ ogun wọn lọna ti wọn yoo gba lati gbogun ti awọn agbebọn aṣekupani.
Iṣoro eto aabo to n koju orileede Naijiria bayii lo wa nipasẹ ikọlu awọn agbebọn aṣekupani.
Pupọ ninu awọn ikọ akogunja yii ni wọn wa ibi aabo lawọn inu igbo, ori oke, ati paapaa ninu agbami okun bii Lake Chad, nibi ti igbagbọ wa wi pe ibẹ ni awọn Boko Haram ati ISWAP fi ṣe itẹdo.
Ibi yii gan an ni ikọ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika dara si, nitori pe wọn le wọ ibẹ, ki wọn si ṣe aṣeyọri.


























