A máa tó gba ọkọ̀ òfurufú láti dá ààbò bo ìpínlẹ̀ Oyo, a tún máa ṣí àwọn ilé ẹ̀kọ́ padà láìpẹ́ - Makinde

Seyi Makinde wọ aṣọ alawọ paali, gbohungbohun wa niwaju rẹ

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kede pe ọkọ ofurufu ti ipinlẹ naa lati pọnkun eto aabo kaakiri ipinlẹ naa ti wa ni ipele to kẹyin ti wọn fi maa gbe ọkọ ofurufu naa wọ ipinlẹ Oyo.

Makinde sọ eyi ninu atẹjade rẹ fun ti oṣu Kẹfa, ọdun 2026 nibi to ti sọrọ nipa eto aabo ni ipinlẹ Oyo atawọn igbesẹ ti wọn n gbe lati gba itusilẹ awọn akẹkọọ ati olukọ tawọn ajinigbe ji gbe ni ilu Esinele ati Yawota ni ijọba ibilẹ Oriire.

Gomina naa ṣalaye pe awọn nnkan diẹ to ku ti wọn nilo lati ṣe ki wọn to gba ọkọ ofurufu naa ni wọn n ṣe lọwọ, ohun lo si fa a to fi jẹ pe wọn ko ni le gba ọkọ ofurufu naa ninu oṣu Kẹfa gẹgẹ bi wọn se ti gbero rẹ tẹlẹ.

O sọ pe awọn igbesẹ ti wọn n se lọwọ naa ṣe pataki lati le ri pe gbogbo eto aabo to yẹ ni wọn ṣe ki ọkọ ofurufu naa to bẹrẹ iṣẹ.

O ni pe kete ti wọn ba ọkọ ofurufu naa lo maa bẹrẹ iṣẹ lẹyẹ o sọka.

Gomina Makinde fi igbagbọ han pe ọkọb ofurufu naa maa ṣatilẹyin fun riri tibu toro ipinlẹ Oyo patapata, tete mojuto iṣẹlẹ pajawiri, to si maa mu alekun ba eto aabo ipinlẹ naa ti wọn ba ti bẹrẹ lilo rẹ.

O fi da awọn araalu loju pe awọn yoo fi to gbogbo eeyan leti ni kete ti wọn ba ti gba ọkọ ofurufu naa.

Nigba to n sọrọ lori eto aabo ni ijọba ibilẹ Oriire, Makinde ni awọn ẹṣọ aabo n ṣiṣẹ takuntakun lati gba itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ tawọn agbebọn naa ji gbe layọ ati alaafia pẹlu atilẹyin to peye lati ọdọ ijọba.

O fi kun pe ofin konile-o-gbile oni wakati mẹrindinlogun ti ijọba kede ni ijọba ibilẹ mẹwaa ti wọn yi igbo Old Oyo National Park ka fun ọjọ meji jẹ ojuna lati pọnkun eto aabo ni awọn agbegbe naa, to si jẹ ohun ti wọn nilo lati mu aabo gbopọn ni agbegbe naa.

O tẹsiwaju pe igbiyanju tun ti n lọ lati ṣi awọn ile ẹkọ ijọba tawọn olukọ tig be ilẹkun rẹ ti pa pada, bo ṣe woye pe nnkan to ṣe pataki ni eto ẹkọ ati pe gbogbo igbesẹ awọn jẹ ojuna lati da aabo to peye bo awọn akẹkọọ.

Makinde tun dupẹ lọwọ awọn awọn eeyan ipinlẹ Oyo fun atilẹyin ati aduroti wọn, to si jẹjẹẹ atilẹyin iṣejọba rẹ lati ri daju pe ipinlẹ Oyo ni itẹsiwaju, ti abbo to si peye fi ibẹ ṣe ibugbe.