Ooni Ile Ife fi oyè àti ọkọ̀ tuntun dá Baba Ijesha lọ́lá

Oríṣun àwòrán, Baba Ijesha
Gbajumọ oṣẹre tiata Yoruba to ṣẹṣẹ ti ẹwọn de, Olanrewaju Omiyinka James, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti di oloye tuntun niluu Ile Ife.
Eyii ko ṣẹyin bi Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ṣe fi oye "Baba Awada Konge Oduwa" da lọla.
Yatọ si oye yii, Baba Ijẹsha ni Kabiyesi Ọọni tun fun Baba oun ni ọkọ ayọkẹlẹ tuntun atawọn nnkan mii.
Baba Ijesha funra rẹ lo fi ikede naa sita ninu atẹjade kan to fi soju opo Facebook rẹ.
Ninu atẹjade ọhun, Ijesha sọ pe "Ọpẹ mi pataki lọwọ Alayeluwa, Ooni Ife.
"Baba, mo dupẹ lọwọ yin fun ayẹsi, ifẹ baba ati igbagbọ ti ẹ fi han si iyawo mi, Afolashade Omiyinka ati emi.
"Mo dupe fun oniruru ẹbun pataki ti ẹ fun wa ati ọkọ tuntun – o jọ mi loju pupọ.
"Gẹgẹ bi ọmọ onilẹ, ẹ tun fun mi ni oye Baba Awada Konge Oduwa."
Baba Ijesha fi atẹjade naa dupẹ lọwọ Ooni, gbogbo oloye ilu Ile Ife ti gbogbo Ile Ife patapata.
Ti ẹ ko ba gbabe, ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2022 ni ile ẹjọ giga kan niluu Eko sọ Baba Ijesha si ẹwọn ọdun mẹta lẹyin to jẹbi ẹsun fifi ọwọ kan ọmọde lọna ti ko tọ.
Ijesha pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa amọ gbogbo atikiyan rẹ lati wọgi le idajọ ọhun lo ja si pabo.
Leyin to pari ẹwọn rẹ tan lo gba itusilẹ ti iroyin itusilẹ rẹ si fa ori ayelujara ya lọjọ karundinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2025.
Damilola Adekoya, ti ọpọ mọ si Princess lo fi ẹsun kan Baba Ijesha pe o ba ọmọ ti oun gba tọ ni ibalopọ ni ọna ti ko tọ lasiko ti ọmọ naa ṣi wa ni majesin.
Ẹwẹ, lẹyin oṣu diẹ ti Baba Ijesha jade kuro ninu ẹwọn lo kede pe Eledua fi ọmọkunrin tuntun ta oun ati iyawo oun lọrẹ.
Ikede naa mi igboro titi, ti ọpọ si n bere pe boya asiko ti Ijesha wa ninu ọgba ẹwọn ni wọn ṣere ọmọ naa.
Wayi o, ọpọlọpọ awọn ololufẹ Baba Ijesha lo ti bẹrẹ si n ki ku oriire oye tuntun ti Ooni Ile Ife sẹṣẹ fun.



























