Olùṣọ́ Àgùntàn ìjọ CCC ṣàlàyé ìdí tó fi ń ki orí àwọn ọmọ ìjọ sí ábẹ́ aṣọ

Oluṣọ Aguntan Oluwaseun fi agbada rẹ bo ọmọ ijọ lori

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọjọ mẹta sẹyin bayii ni fidio kan ti n fa awuyewuye lori ayelujara.

Ninu fidio naa ni pasitọ ijọ alaṣọ funfun kan ti n fi aṣọ rẹ bo awọn ọmọ ijọ rẹ kan ti wọn wa lori ikunlẹ lori, to si n gbadura fun wọn.

Fidio naa ti wa fa oniruuru ariwisi latọdọ awọn eeyan, tawọn eeyan si n kọminu lori bawọn pasito ṣe maa n ṣe nigba ti wọn ba n ṣiṣẹ iyanu.

Lara ohun tawon eeyan n sọ ni pe bi pasitọ naa ṣe n ki ori awọn eeyan paapaa wọ abẹ aṣọ jẹ ohun ti ko yẹ ki wọn maa ba ni awujọ ẹsin.

Awọn eeyan bu ẹnu atẹ lu iwa naa, ti wọn si n sọ pe niṣe ni iwa tabuku ijọ mimọ.

Amọ pasitọ naa ti wa jade bayii to si sọrọ nipa ohun to ṣẹlẹ ninu ijọ naa ati idi to fi n da aṣọ bo awọn eeyan lori lati gbadura fun wọn.

Oluṣọ Agutan Olatunji Oluwaseun ti ijọ Celestial Church of Christ ti Ọwọ Oluwa Wonder Parish to wa ni agbegbe CocaCola, Ilesha, ipinlẹ Osun to wa ninu fidio naa sọ pe oun ko hu iwa naa lati tabuku ijọ mimọ.

O sọ pe oun jade lati sọrọ nipa fidio naa nitori awọn awuyewuye to n waye lori ayelujara lori rẹ.

Oluṣọ Agutan Oluwaseun ṣalaye pe ni ọjọ Aiku to kọja ni oun ṣe iwuye fun awọn ọmọ ijọ oun ati pe ohun to waye ninu fidio naa kii ṣe ohun ti oun mọọmọ ṣe tabi gbiyanju lati tabuku ijọ.

'Mi o fi ori awọn eeyan sabẹ aṣọ nitori agbere'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ni kii ṣe pe oun mọọmọ ṣe igbesẹ naa tabi imọtẹlẹ ara oun bikoṣe irinajo ẹmi ti oun rin lasiko ti oun gbadura lẹyin iwuye naa.

O sọ pe ọmọ oun wa lara awọn eeyan ti wọn ṣe iwuye lọjọ naa, to si wa lara ti oun da agbada ti oun wọ lọjọ naa de lori.

O fi kun pe ẹmi lo dari oun lati gbadura fun ọmọ naa, to si tun dari oun lati da aṣọ bo o lori lati gbadura fun-un ti oun ko si le da gba adura fun ọmọ oun nigba ti awọn ti wọn jọ ṣe iwuye wa lori ikunlẹ.

"Kii ṣe pe mo ṣe bẹẹ ninu irinajo agbere tabi ninu irinajo lati tabuku si irinajo jọ mimọ tabi si irinajo baba wa Osofa.

"Mi o ṣe e si itabuku gbogbo awa iranṣẹ Oluṣọ Agutan kaakiri agbaye, mi o si ṣe e so itabuku ijọ mimọ.

"Mo fẹ ki fi asiko yii tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ọmọ ijọ mimọ kaakiri agbaye atawọn mii ti wọn ri fidio naa ti wọn wo o ni iwoye pe o jọ ohun irira, mi o ṣe e ni ohun irira.

"Mo fi akoko yii bẹ wa, ka fọwọ wọnu, mo rọ gbogbo ijọ mimọ lapapọ, irinajo yii irinajo ẹmi ni ko si rọrun lati fi ara ṣe dari ẹmi."

Oluṣọ Agutan naa tun sọ pe oun ko mọ pe wọn gbe fidio naa sori ayelujara nitori ọpọ iṣẹ itusilẹ ni awọn maa n ṣe ti awọn kii gbe sori ayelujara.

'Aṣọ mẹta lo wa labẹ agbada mi'

O tun tẹsiwaju pe aṣọ ti oun wọ lọjọ naa lo jẹ ipele mẹrin gẹgẹ bi awọn Oluṣọ Agutan ijọ mimọ ṣe maa n wọ ọ, ti ko si ẹni to le ri ara oun pẹlu aṣọ naa.

O ni agbada naa lo jẹ aṣọ kẹrin ninu aṣọ ti oun wọ lọ sile ijọsin lọjọ naa.

"Aṣọ isin kii ṣe ohun ti eeyan le wọ lati fi ṣe ohun irira fun ẹni to ba ni ibẹru ati ipaya Ọlọrun.

"Gbogbo ẹyin ojiṣẹ Ọlọrun ti ẹ n wo fọnran naa, mi o ṣe ohun irira, irinajo ti ẹmi dari ni, ti ara ko le dari rẹ, mo bẹ wa lorukọ Ọlọrun Olodumare.