Àwọn ọmọ ilẹ̀ Afirika ní láti máa sọ ìtàn ilẹ̀ wọn fúnra wọn sí i - Ọ̀dọ́mọdé òǹkọ̀tàn àti ayàwòrán

Niyi Fagbemi ree, arinajo, ayaworan ati onkọtan to sọ fun BBC News Yoruba idi ti o fi yan rinrin ajo afẹ ati aworan yiya laayo.
Fagbemi gbagbọ wi pe awọn ọmọ ilẹ Afirika ni lati sọ itan wọn funra wọn si i.
Niyi ni oun maa n gbọ nipa ọpọ ibudo igbafẹ ti eeyan le rinrin ajo lọ, amọ, kii saba si aworan to le sọ nipa wọn.
O ni awọn ti kii ṣe ọmọ ilẹ Afirika lo maa n saba sọ nipa awọn ibudo igbafẹ yii to wa nilẹ Afirika.
Ọdọmọde ayaworan naa sọ pe awọn ọmọ ilẹ Afirika lo le sọ itan ilẹ wọn gẹgẹ bi o ṣe ri gan an.
Arinrinajo afẹ naa sọ pe lara awọn ipenija toun n koju ni ai ri owo to to lati rinrin ajo lọ sawọn ibi toun fẹ lọ.
Bakan naa ni o tun sọ pe irinajo nilẹ Afirika nira diẹ.
Niyi ṣalaye pe oun n ya aworan awọn ibi toun n rinrin ajo lọ kawọn ti ko lanfaani lati rinrin ajo afẹ bi toun le lanfaani lati wo awọn ibi toun n lọ ninu fọto.






