"Agbekoya ní agbára ìbílẹ̀ láti lé àwọn jàndùkú afẹ̀míṣòfò kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Yoruba láàrin oṣù kan péré, àmọ́..."

Oríṣun àwòrán, Agbekoya solidarity movement kogberegbe ifo Ogun state/Facebook
Aarẹ ẹgbẹ Agbekoya Solidarity Movement of Nigeria, Bankole Ahmed, ti sọ pe ẹgbẹ naa lagbara lati le awọn janduku agbebọn to n ṣọṣẹ kuro ni gbogbo ipinlẹ Yoruba laarin oṣu kan pere.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu iwe iroyin Punch, Ọgbẹni Ahmed sọ pe awọn ọdẹ atawọn fijilante le jọ ṣiṣẹ pọ lati le awọn janduku agbebọn afẹmiṣofo to n ji awọn eeyan gbe pa owo lọ.
Aarẹ Agbẹkoya ni lọpọ igba lawọn ti kọ lẹta si ijọba lori eto aabo to mẹhẹ wi pe awọn ṣetan lati ṣeranwọ lori a ti wa ojutuu si iṣoro naa, amọ, ijọba ko tii pe awọn lati ṣe nnkankan lori ọrọ naa.
''Nnkan ti wọn ba pe wa si ni a maa n dasi, ni bayii, a ko le ṣeranwọ fawọn ọlọpaa tori ijọba ko tii fun wa laṣẹ lati ṣe bẹẹ.
Ibanujẹ ọkan ni nnkan to n ṣẹlẹ nilẹ Yoruba lori eto aabo jẹ fun mi, tori pe agbara wa fun wa lati wa ojutuu si ọrọ naa ṣugbọn ijọba ko tii pe wa.
Ko din ni ẹgbẹrun un marundinlogoji ọmọ ẹgbẹ Agbekoya to wa ni ipinlẹ mẹwaa.
Gbogbo wọn lo si lagbara lati ja fun ilẹ wa nibi ti ogun ti le gan an.
Ogun ibilẹ ni a n lo, a ni awọn ọdẹ, awọn ẹgbẹ Agbekoya atawọn OPC kaakiri ilu Ibadan ati ni gbogbo ipinlẹ Oyo.
A ṣetan lati ṣiṣẹ ti ijọba ba le kepe wa, nitori gbogbo ipinlẹ Yoruba lawọn agbesunmọmi ti wa bayii,'' aarẹ Agbekoya lo sọ bẹẹ.
Ọgbẹni Ahmed ni ọ rọrun fawọn lati koju awọn janduku agbebọn yii tori agbara ogun ibilẹ lawọn n lo.
Amọ, aarẹ Agbekoya ni ohun kan tawọn nilo lati ọdọ ijọba naa ni atilẹyin.
''Awọn agbesunmọmi yii kii ṣe ẹmi airi, eeyan bi tiwa bayii naa ni wọn''
''Ẹ jẹ ki ijọba ko gbogbo awọn ọdẹ jọ ki a si wọ inu igbo lọ, ko le pẹ ti a fi maa le gbogbo ọdaran ti wọn wa ninu igbo wa kuro.
Ọmọ Yoruba ni wa, a ṣi mọ nnkan to yẹ ki a ṣe bi a ba ti wọ inu igbo lọ.
Awọn nnkan kan wa ti a le ṣe ninu igbo ti ko ṣee ṣe laarin ilu, a si ti ṣe iru rẹ tẹlẹ ni Idi-Ayunre niluu Ibadan nibi ti a ti wọ inu igbo ti a si le gbogbo ọdaran kuro.
A nilo nnkan ijagun, nnkan irinsẹ ati ounjẹ, ti a ba le ri awọn nnkan yii laarin oṣu kan, iṣẹ yoo di ṣiṣe.
Awọn agbesunmọmi yii kii ṣe ẹmi airi, eeyan bi tiwa bayii naa ni wọn, ẹ jẹ ka jọ waako ninu igbo ki a si wo ẹni ti yoo ṣẹgun,'' Ọgbẹni Ahmed lo sọ bẹẹ.
O fikun ọrọ rẹ pe awọn ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹṣọ Amotekun, ọlọpaa atawọn ẹṣọ eleto aabo mii.
Ọgbẹni Ahmed sọ pe Agbekoya ti ja oniruuru ija bayii sẹyin ti wọn si ṣẹgun.
Aarẹ Agbekoya ni agbara tawọn lo laye igba naa si tun wa di oni.
Adari ẹgbẹ ajigbara naa sọ pe kii ṣe wi pe oun kan janu lasan an, amọ, nnkan to da oun loju loun n sọ nipa rẹ.
O ni ko si nnkan tawọn le ṣe ti ijọba ko ba kepe awọn lati dasi ọrọ naa.
Ọgbẹni Ahmed ni awọn o le wọ inu igbo lọ lai gbaṣẹ lati ọdọ ijọba




























