A máa tá tán ni pẹ̀lú Tani Olorun, nínú kó lọ sẹ́wọ̀n tí ọwọ́ òfin bá tẹ̀ ẹ́, tàbí ká fìdí rẹ̀mi - Agbejọ́rò Imam

Oríṣun àwòrán, Umar Imam - Tani olohun/Screenshot
Gbajumọ ori ayelujara to maa n tako ẹsin nni, Abdulazeez Adegbola Ifatimileyin, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Tani Olohun, ti sọ pe ko si ọrọ ninu ẹsun ti wọn fi kan oun niwaju ile-ẹjọ giga nilu Ilorin.
Tani Olohun sọ pe Emir ilu Ilorin, Ọmọwe Ibrahim Sulu-Gambari ti yowọ rẹ kuro ninu ẹjọ naa, ati pe ko ni ohunkohun lati ṣe ori ẹjọ ti wọn pe oun.
Ninu fọnran ti Tani Olohun gbe soju opo ayelujara ti Facebook rẹ, sọ pe agbẹjọro to n fi ẹwọn dunkooko mọ oun, ko mọ nnkan to n sọ, nitori pe ẹjọ ti ko lẹsẹ nilẹ lo n sọrọ le lori.
Tani Olorun ni "Mo maa n beere nnkan, ẹ ni awọn kan 'Ilorin Heritage Foundation' lo n pẹjọ.
Ki lo de ti awọn to n pe ẹjọ kii wa si kootu gan-an, to jẹ pe agbẹjọro lo n leri mọ ẹni ti wọn pe lẹjọ?" Tani Olorun sọ bẹẹ.
O sọ pe dajudaju, agbẹjọro lo da ẹjọ naa pe, "nitori pe baba ti wọn mu wa lọjọsi, to pe ara rẹ ni aṣoju Emir Ilorin, o ti pada jade sọrọ lonii, wi pe Emir Ilorin ko ni ki awọn ṣe ẹjọ kankan.
"O daju pe ọrọ ti a sọ gbẹyin ti de ọdọ wọn.
Baba naa sọ pe Emir Ilorin ko ran awọn niṣẹ, ati pe awọn da iṣẹ ara awọn jẹ ni.
O fi han pe Imam naa lo pẹjọ, oun naa si tun ni agbẹjọro, to tun n dunkooko mọ ẹni ti wọn pe lẹjọ."
Ki lo fa ọrọ yii?
Agbẹjọro kan, Umar Sa'ad Imam tọpọ mọ si O.S Imam lo jade lẹyin ti igbẹjọ waye lori ẹsun ti wọn fi kan Tani Olohun wi pe ki ẹnikẹni ma ṣe bẹ oun fun ọkunrin naa.
"Gbogbo aye lo ti mọ ohun to n lọ lori ẹjọ yii ati ti Tani Olohun, bo tilẹ jẹ pe nko fẹẹ darukọ rẹ," Agbẹjọrọ Imam sọ bẹẹ.
"Kaluku lo n wo o nisin yii, to ba di pe bi Ọlọrun ni ki ọwọ ofin tẹ ẹ, mo fẹẹ parọwa pe ki ẹnikankan ma wa ba mi.
"Eleyii ti a ko si yii, a maa ja a titi de opin ni. Yala ka padanu ẹjọ yii, tabi pe ko lọ sẹwọn, ikan ni yoo ṣẹlẹ nibẹ.
"Ẹni to ba fẹran rẹ, ki wọn ma wa ba mi pe ọrẹ mi ni, ẹbi mi ni, ololufẹ mi ni, mo n bẹ yin; ko si ẹni ti emi ko le woju o, ẹ ma jẹ ka woju ara wa.
Ìgbésẹ̀ ilé-ẹjọ́
Agbẹjọro Quadri Ajasa to jẹ ọkan lara awọn aṣoju Ilorin Emirates Foundation nile-ẹjọ nigba to n ṣalaye, sọ pe ohun ti awọn wa ṣe nile-ẹjọ ni ti aṣẹ ile ẹjọ ati gbigbọ ẹsun to atako.
Ajasa sọ pe ile-ẹjọ ti da ẹjọ ti awọn olufẹsunkan pe tẹlẹ nu, nitori pe wọn gbe igbesẹ pe ki ile-ẹjọ yọ ẹjọ naa kuro ninu awọn eyi ti wọn n ṣe tẹlẹ, nitori ẹjọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ pe.
"Awọn olufẹsunkan lo fẹẹ yọ iwe ẹsun atako (affidavit) ti wọn ko ṣe daadaa tẹlẹ kuro. Awa tako o nigba naa wi pe wọn ko le yọ ọ kuro, nitori pe wọn ti da gbogbo rẹ papọ.
"Ṣugbọn nigba ti ile-ẹjọ n paṣẹ, wọn ni lawọn eeyan naa ni ẹtọ lati yọ iwe naa kuro, ile-ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn yọ ọ.
"Lẹyin eyi ni awa naa gbe atako dide lori eyi ti wọn tun ṣẹṣẹ gbe wa, gbogbo wa fẹnuko lori ọjọ igbẹjọ miran lor iwi pe ṣe ile-ẹjọ ni agbara lati gbọ ẹjọ Benylee tabi pe ile-ẹjọ naa ko ni agbara."
Báwo ni ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀?
Abdulazeez Adegbola, ti awọn eeyan mọ si Tani Olohun, to jẹ gbajugbaja oniṣẹṣe lori ayelujara, ni awọn ọlọpaa mu nilu Ibadan, ti wọn si gbe lọ si ilu Ilorin labẹ idari kọmiṣọna fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara.
Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Tani Olorun, ti wọn si fi ẹsun ibanilorukọjẹ ati sisọ ọrọ abuku si Emir ilu Ilorin, Alhaji Ibrahim Sulu-Gambari atawọn aafaa mii ni ipinlẹ naa, pẹlu awọn ẹsun miran.
Gbogbo awọn ẹsun yii, gẹgẹ bii Ademola Banks to jẹ agbẹjọro olujẹjọ naa ṣe wi, ni wọn lee gba oniduro fun nile-ẹjọ amọ inu galo ni Tani Olohun wa lati ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹjọ.
Kí ló lè mú ọmọ Mùsùlùmí di oníṣẹ̀ṣe?
Lọdun 2024, Adegbola Ifatimilẹyin Tani Olorun, sọ fun BBC pe oun ko ja mọ nnkankan ṣaaju ki oun to o di ẹlẹsin abalaye.
O ni nigba ti oun wọ inu iṣẹẹṣe ni ọrọ aye oun ni itumọ, ti gbogbo aye mọ oun, ti awọn kan si tun n fẹ mọ oun si.
O ni ọjọkọjọ ti oun ba pinnu pe oun ko ṣe ẹbọ mọ, ni ki ẹmi oun bọ.
Bakan naa lo ṣalaye pe iya oun , ati iyawo oun ṣi n ṣe ẹsin Islam.
"Emi ni mo pinnu pe, ẹsin awọn baba wa ni ma a pada si.
"Mo si l'agbara lati sọ pe ki iyawo mi naa pada sinu iṣẹẹṣe, amọ mi o l'agbara lori awọn obi mi pe ki wọn ma ṣe ẹsin Islam mọ."
O ni jibiti ati aṣilo agbara lo mu ki ọpọ̀ eeyan ma a fi ẹnu tẹnbẹlu Iṣẹẹṣe.
Yatọ si eyi, o ni fifi ẹnu ba ẹsin ẹlomiran jẹ, lo n fa ija ẹsin.
Arakunrin Ifatimilẹyin sọ pe ọjọkọjọ ti oun ba kirun, ni ki awọn iraunmọlẹ gba ẹmi oun.


























