Wo ohun tí ìjọba fẹ́ fi $1.5bn tí wọ́n fẹ́ yá ní ilé ìfowópamọ́ àgbáyé ṣe

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook
Ijọba apapọ tun ti n beere ẹyawo biliọnu kan abọ dọla ($1.5bn) latọwọ ile ifowopamọ agbaye iyẹn World Bank.
Igbesẹ yii lo n waye leyin ti gbogbo gbesẹ to wa lọrun Nigeria ti wọ N166.79tn ni ipari oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Gẹgẹ bi iwe ẹyawo ti ijọba apapọ fi ranṣẹ si ile ifowopamọ agbaye naa ṣe fi han, ọna mẹta ni owo ti ijọba naa fẹ ya pin si, ti wọn si ni awọn fẹ lo owo naa lati fi mu alekun ba igbayegbadun awọn eeyan, awọn ọmọde ati imugbooro ayipada oju ọjọ.
Laaarin ọdun mẹta bayii, gbese Naijiria ti lekun ni ilọpo meji. N87.38trn ni gbese Naijiria ni oṣu Kẹfa ọdun 2023 ṣugbọn to ti fo wọ N166.79trnni ipari oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Ki ni ijọba fẹ fi owo tuntun ti wọn fẹ ya yii ṣe?
- $500m fun imugbooro awọn akanṣe iṣẹ lori ayipada oju ọjọ
Ninu owo tuntun ti ijọba apapọ fẹ ya lọwọ ile ifowopamọ agbaye naa ni $500m ti wọn ni awọn fẹ lo fun eto imugbooro akanṣe iṣẹ lori awọn ayipada ti oju ọjọ n fa lori eto ọgbin iyẹn the Agro-Climatic Resilience in Semi-Arid Landscapes, ACReSAL.
Ile ifowopamọ agbaye sọ pe ijọba apapọ n beere fun owo naa lati mu alekun ba awọn aṣeyọri ti wọn ti ṣe lori eto naa.
Ṣaaju ni World Bank ti sọ pe awọn maa ṣagbeyẹwo mimu alekun bao wo ti wọn ya ajọ naa lati $700m di $1.2bn ki ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika to n mojuto akanṣe iṣẹ naa le ri iṣẹ wọn ṣe bo ṣe tọ.
Ipinlẹ mọkandinlogun, to fi mọ olu ilu Naijiria, Abuja ni ACReSAL ti n ṣiṣẹ pẹlu afojusun ipese omi to ṣe e bumu buwẹ, atunṣe awọn ọna, ṣamojuto awọn ohun ti ayipada oju ọjọ le ṣakoba fun ati pipọkun eto ọgbin.
Ninu $500m tuntun ti wọn fẹ ya yii, wọn ni $310m ni wọn maa lo fun amojuto awọn ilẹ gbigbẹ, $165m maa lọ lori eto mimu ayipada oju ọjọ duro ṣinṣin, ti $25m to ku yoo si lọ lori amojuto akanṣe iṣẹ naa.
Lara awọn ti wọn ni wọn maa ṣe ni amojuto omiyale agbara ya ṣọọbu, awọn ojuṣan agbara, koto idaminu lawọn ibi to yẹ, gbigbin igi sawọn igbo ọba ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- $500m fun ironilagbara
Fun $500m keji, ijọba apapọ ni awọn maa lo owo naa lati fi ṣe eto ironilagbara lati mu ki awọn idile le ri igbega ti wọn pe ni HOPE-SP.
Akanṣe iṣẹ naa gẹgẹ bi agbekalẹ rẹ ni lati fi pese iranlọwọ fawọn idile to wa ninu iṣẹ ati oṣi, mimu alekun bao wo to n lọ si ipinlẹ kọọkan, ti wọn yoo si ri daju pe wọn pese awọn iranlọwọ yii latara awọn ijọba ibilẹ.
Eto yii yoo pese fifun awọn eeyan ni owo, ounjẹ, eto ẹkọ ati eto ilera eyi ti wọn lo n waye latari akọọlẹ lori bi iṣẹ ati oṣi ṣe n peleke si ni Naijiria.
Gẹgẹ bi iwadii World Bank ṣe sọ, awọn eeyan to n gbe ninu iṣẹ ati oṣi ni Naijiria lo ṣeeṣe ko wọ ida mejilelọgọta apapọ gbogbo eeyan to n gbe ni Naijiria ni ọdun 2026, bi wọn ṣe ni yiyọ iranwọ ori epo atawọn eto mii ti ijọba tig be kalẹ ti mu ki igbe aye le si fawọn araalu.
- $500m fun idagbasoke awọn ọmọde
Ẹyawo $500m to kẹyin ti ijọba Naijiria n beere lọwọ ile ifowopamọ agbaye ni wọn ni awọn fẹ lo lati mu idagbasoke bae to to niṣe pẹlu awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn wa lati ọmọ oojọ wọ awọn ọmọ ọdun marun-un.
Lara awọn eto ti wọn n gba lero fawọn ọmọde yii ni ipese eto ilera, ounjẹ, omi ati eto aabo fun wọn.
Ile ifowopamọ agbaye sọ pe ida ogoji ninu awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko i tii pe ọdun marun-un ni wọn kmo dagba bo ṣe yẹ, ati pe ida mẹrindinlogoji ni wọn n lọ sile ẹkọ bo ṣe tọ.
di ti wọn fi pin awọn ẹyawo yii ni ọtọọto gẹgẹ bi ijọba apapọ ṣe sọ ni pe akanṣe iṣẹ ọtọọtọ ni wọn fẹ lo wọn fun, ti iṣẹ ti wọn yoo si ṣe jẹ ọtọọtọ.
Pẹlu ẹyawo tuntun yii, apapọ gbese ti Naijiria jẹ ile ifowopamọ agbaye bayii jẹ $20.73bn.
Ni oṣu Kẹfa ọdun 2026 ni gbese naa lekun pẹlu ẹyawo $907.09m to kun $19.82bn to wa tẹlẹ ninu oṣu Kẹta ọdun yii.
Gbese $20.73bn ti ijọba Naijiria jẹ World Bank yii ni ida mejidinlogoji gbese ti Naijiria jẹ nilẹ okeere ni opin oṣu Kẹfa odun 2026.
Atiku bu ẹnu atẹ lu Tinubu lori ẹyawo tuntun yii
Ṣaaju ni oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu ADC, Atiku Abubakar ti ni o yẹ ki aarẹ Naijiria Bola Tinubu tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria lori awọn gbese ti wọn n gba yii.
Atiku ni o yẹ ki ijọba ṣafihan gbogbo gbese Naijiria si oju kan pẹlu bi gbese Naijiria tun ti ṣe lekun bayii.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ eto ipolongo idibo fun ẹgbe oṣelu ADC, Phrank Shaibu fi lede sọ pe nnkan ti ijọba n ya owo fun ko ye awọn pẹlu bi ijọba se sọ pe owo to n wọle ti pọ si lati igba ti wọn ti yọ iranwọ ori epo bentiroolu.
Awọn onimọ lẹka eto ọrọ aje ni ohun to yẹ ko jẹ iwoye fawọn araalu ni pe ṣe ijọba n lo awọn owo ti wọn n ya yii sawọn nnkan ti wọn ni awọn fẹ lo o fun nitori yiya owo kii ṣe ohun to buru, aina sibi to yẹ gan-an ni ko dara.




























