Oru àmújù ṣekúpa èèyàn ogójì nilẹ̀ France

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ogoji eeyan ni wọn ti padanu ẹmi wọn ni France latari ooru amuju to n mu nibẹ.
Olootu ijọba orilẹede naa, Sébastien Lecornu sọ pe oru naa mu kọja iriri ti wọn ti ni latẹyinwa nibẹ ati lawọn orilẹeede to wa nilẹ Europe.
Minisita fun ere idaraya, Marina Ferrari sọ pe "A ko gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ki eeyan lọ maa luwẹ ninu adagun odo lai si ẹni ti yoo maa ṣakoso rẹ nibẹ.
Lara awọn orilẹede ti oru amuju naa n ba finra bayii ni France, Spain ati Italy.
Ni France, ajọ Météo France sọ pe ọjọ Aje ni oru naa mu julọ, wọn si ti fi ikilọ sita fun idaji orilẹede naa bayii.
Ajọ adoola ẹmi German Lifesaving Association (DLRG) sọ pe eeyan marun un lo ku lasiko ti wọn lọ wẹ ninu odo laarin ọjọ Ẹti si ọjọ Aiku bo tilẹ jẹ pe wọn ko le luwẹ
Minisita ere idaraya orilẹede naa sọ pe ọpọ eeyan lo n gbiyanju lati lọ seti odo lati lọ wẹ lai ro ewu to wa ninu ṣiṣẹ bẹẹ.
Lara awọn to ti ku bayii ni ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹtala kan to lọ wẹ pẹlu awọn ẹbi rẹ ninu odo Seine to wa lagbegbe Fontaine-La Port lalẹ ọjọ Aiku.
Iroyin ni ọmọ naa ko mọ bi wọn ṣe n luwẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
Ẹwẹ, ọdọkunrin agbabọọlu kan ti wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun bayii lẹyin ti wọn wọ oun naa jade kuro ninu omi Rhône lẹba ilu Lyon.
Wọn ri lasiko ti awọn adoola ẹmi fẹ lọ yọ awọn ọdọkunrin mẹrin mii ninu odo ti awọn alaṣẹ sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ wẹ ninu rẹ mọ.
Ni France yii kan naa, wọn ri oku awọn ọmọde meji ninu ọkọ ayọkẹlẹ awọn obi wọn ni Carpentras lẹyin ti oru mu wọn pa sinu rẹ.
Ajọ German Lifesaving Association (DLRG) sọ pe eeyan marun un lo ku lasiko ti wọn lọ wẹ ninu odo laarin ọjọ Ẹti si ọjọ Aiku bo tilẹ jẹ pe wọn ko le luwẹ.
Ni Spin, ajọ to n ri si ọrọ ọjọ sọ pe oru naa le pọ ju bo ṣe wa yii lọ.
Nigba ti ijọba Italy ni oun ti bẹrẹ eto idaabo fun awọn oṣiṣẹ ti wọn maa n ṣiṣẹ ninu oorun fun ọpọ wakati.
























