You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn onímọ̀ ṣàwárí obìnrin tó bí ìbejì táwọn ọmọ náà sì ní bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
- Author, Santiago Vanegas
- Role, BBC Mundo
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ní ọdún 2018, obìnrin kan lọ sí ẹ̀ka tí wọ́n ti máa ń ṣàyẹ̀wò ìyẹn Laboratory of Population Genetics Identification ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì National University of Colombia láti fìdí ẹni tó jẹ́ bàbá àwọn ìbejì náà múlẹ̀.
Ilé iṣẹ́ náà ṣàyẹ̀wò ní ìgbà púpọ̀ nítorí wọ́n fẹ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn kò ṣe àsìṣe kankan lórí àyẹ̀wò náà nítorí èsí tí wọ́n ń rí yani lẹ́nu púpọ̀.
Àwọn ìbejì náà ní ìyá kan náà àmọ́ kìí ṣe bàbá kan náà ló bí wọn.
Èyí jẹ́ ohun tí kìí sábà wáyé, òhun sí ni àwọn olóyìnbó ń pè ní heteropaternal superfecundation.
Iwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì sọ pe iru rẹ to wa kaakiri agbaye ko ju ogun lọ.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn to ṣe ayẹwo naa ti gbọ ri pe o ṣeeṣe ki irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ waye, igba akọkọ niyi ti iwadii wọn n fidi rẹ mulẹ. Eyi jẹ ki wọn ni ifẹ lati ṣe ayẹwo naa siwaju sii.
Bi wọn ṣe ṣawari rẹ
Lati ṣe ayẹwo mimọ baba ọmọ, awọn onimọ sayẹnsi ni ẹka ekọ nipa ẹya ara, Institute of Genetics ni ile ẹkọ giga fasiti Colombia lo imọ ẹrọ microsatellite markers lati fi ṣe ayewo naa.
Ni ede kukuru, eyi tumọ si pe ṣiṣe ayẹwo awọn nnkan to kere latara ọmọ, iya ati baba, ti wọn si maa ṣe agbeyẹwo wọn papọ.
"A mu nnkan lara gbogbo wọn, a ṣe ayẹwo laaarin pọinti mẹẹdọgbọn si mejilelogun, a sig be wọn yẹwo sira lẹyọ kọọkan," Ọjọgbọn William Usaquén, adarí iléeṣe ayẹwo naa sọ fun BBC Mundo.
Amọ iwadii yii kọja ṣiṣe ayẹwo DNA labẹ ẹrọ aṣewadii ohun to ba kere nikan.
Lẹyin ti wọn gba ẹjẹ lara awọn eeyan naa, awọn onimọ sayẹnsi lo awọn kẹmika lati fi pin awọn ohun DNA kuro lara awọn ẹya mii.
Lẹyin naa ni wọn gbe awọn eyi to niiṣe pẹlu DNA sabẹ akanṣe imọ ẹrọ lati fi ṣe igbelewọn rẹ daadaa.
Lẹyin eyi ni wọn tun gbe sabẹ maṣiini mii eyi to n ka microsatellites ninu ayẹwo kọọkan ki wọn si sọ wọn di oni nọmba ohun ti wọn n pe ni electrophoresis.
Nipari, lilo awọn nọmba naa, awọn oluwadii maa ti bẹ mọ lati mọ eni to jẹ baba ọmọ gan-an.
Nigba ti ilaji awọn ohun ti wọn ba ṣe DNA ba ba iya mu, ti ilaji rẹ si ba ti baba mu, bẹẹ ni wọn ṣe maa n mọ ẹni to jẹ baba ọmọ.
Esi ayẹwo to yani lẹnu
Ni ti awọn ibeji Colombia, awọn onimọ sayẹnsi sayẹwo microsatellites mẹtadinlogun ninu DNA ti iya, awọn ọmọ mejeeji ati baba to lọ fun ayẹwo naa.
Wọn ṣawari rẹ pe DNA baba naa ba ọkan ninu awọn ọmọ naa mu ṣugbọn ko ba ti ọmọ ikeji – esi ayẹwo to yatọ.
"Lati ọdun mẹrindinlọgbọn sẹyin ni mo ti wa gẹgẹ bi adari ileeṣẹ ayẹwo yii, igba akọkọ niyi ti a maa ṣe awari iru eyi," Usaquén sọ.
"A ti maa n gbọ pe awọn iṣẹlẹ bayii maa n waye ṣugbọn o kere jọjọ," Andrea Casas, onimọ nipa ẹya ara ati oluwadii ni ni ile ẹkọ Institute of Genetics ni National University of Colombia, sọ.
Wọn tun ayẹwo naa ṣe lati ibẹrẹ lati fidi rẹ mulẹ pe wọn o ṣe aṣiṣe amọ esi kan naa ni wọn ri.
Idi ti ko fi wọpọ
Iwe kan ti awọn onimọ sayẹnsi ni ileeṣẹ ayẹwo kan ni Baltimore ni Amẹrika kọ lọdun 2014 sọ pe ninu iwadii lati mọ baba ọmọ 39,000 ti wọn ṣe, mẹta ninu rẹ ni wọn ti ri irufẹ ti heteropaternal superfecundation.
Usaquén ṣalaye idi ti eyi kii saba wọpọ.
O ni eyi tumọ si pe obinrin naa ni ọkunrin meji to n b ani ajọṣepọ ati pe o ni ibalopọ pẹlu awọn mejeeji nigba ti ko pẹ sira wọn rara.
O fi kun pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ẹyin meji ni o wa lara obinrin naa ṣaaju ko to ni ibalopọ eyi tawọn oloyinbo n pe ni polyovulation, to si jẹ pe ẹyin mejeeji ni atọ awọn ọkunrin sọ di ọmọ ni ọtọọtọ.
O ṣe pataki lati sọ pe awọn ibeji bayii ko le jọ ara wọn nitori atọ kan ati ibeji to ba jade ninu ẹyin kan naa lo le ṣokunfa ki ibeji jọ ara wọn.
Igbe aye ọlọdanni
Ni ọpọlọpọ igba, ti ẹyin to ba wa lara obinrin ba ju ẹyọkan lọ, to ba jẹ ẹyọkan ni o kọkọ di ọmọ, ikeji maa n tete ku danu.
Eyi wa lara ohun to jẹ ki iṣẹlẹ heteropaternal superfecundation ma fi bẹẹ wọpọ, o tumọ si pe ibalopọ gbọdọ tete waye ki ẹyin keji to ku.
Gẹgẹ bi iwadii US National Library of Medicine, ẹyin ko le lo ju ọjọ kan lọ lara obinrin ko to ku.
Amọ Andrea Casas ṣalaye pe o ṣeeṣe ki awọn ẹyin naa ma jade si asiko kan naa.
O sọ pe o maa n ṣẹlẹ nigba mii ti ẹyin maa jade lara obinrin ni ọjọ meji tabi mẹta sira wọn.
O ni eyi le mu kawọn ẹyin naa di ọmọ lasiko ọtọọtọ ti obinrin yoo si maa gbe ibeji ti baba wọn yatọ sira.
Ohun mii ti awọn ibeji bayii ko fi wọpọ ni pe ọpọlọpọ ni kii ṣe ayɛeo DNA.
Awọn onimọ nileeṣẹ ayẹwo naa woye pe o ṣeeṣe ki irufẹ nnkan bayii ma wọpọ lọjọ iwaju nitori awọn ohun ayẹwo to ti wa ati bi awọn eeyan ṣe ti n ṣe ayẹwo DNA bayii.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn onimọ sayensi n gbiyanju lati mọ bi wọn ṣe sun oorun awọn ọmọ yii, amọ ofin ati ilana iṣẹ ko faye gba wọn lati tọpinpin igbe aye awọn ti o n ṣe iwadii yii.