You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gbogbo kọ̀rọ̀kọ́ndú ìpinlẹ̀ Ekiti ni a ti fi ọlọ́pàá ṣọwọ́ sí fún ètò ìdìbò ọjọ́ Abamẹta - Ọlọ́pàá
Kọmiṣọna ọlọpaa fun eto idibo ipinlẹ Ekiti, Abayomi Shogunle, ti sọ fun wọn eeyan ipinlẹ naa pe ko ni si ewu kankan fun wọn lasiko eto idibo sipo gomina ti yoo waye lọjọ Abamẹta.
CP Abayomi Shogunle lo sọ ọrọ naa lasiko ti ileeṣẹ iroyin BBC bẹ ẹ wo ni ọọfisi rẹ to wa niluu Ado Ekiti.
O ni gbogbo kọrọkọndu ipinlẹ ọhun lawọn ti fi ọlọpaa ṣọwọ si ki awọn janduku ma ba a da idibo naa ru ati pe ko ni si ewu kankan fun awọn oludibo.
Ẹ jáde láti dìbò, kò s'éwu fún yín rárá, ọlọ́pàá képe aráàlú ṣaájú ètò ìdìbò gómìnà Ekiti
Ni igbaradi fun ti eto idibo iyansipo Gomina to fẹ waye nipinle Ekiti ni ọjọ Abamẹta ogunjọ osu kẹfa opin ọsẹ yii, ileeṣẹ ọlọpaa ti kepe araalu lati jade dibo.
Kọmiṣọna ọlọpaa fun eto idibo naa, CP Abayomi Shogunle, fi dawọn eeyan ipinlẹ Ekiti loju pe abo to peye wa fun wọn ti wọn ba jade lati dibo.
Ọga agba ajọ eleto idibo nipinlẹ Ekiti, Bunmi Omoseyindemi, naa sọ fun BBC News Yoruba pe awọn ohun elo fun idibo lorisiirisii ti wọle lati ile ifowopamọ apapọ Naijiria, CBN to wa niluu Ado Ekiti.
Bakanna lo tun mẹnuba igbaradi awọn oṣiṣẹ ajọ INEC fun sise agbekalẹ eto idibo naa lọna to muna doko.
Ninu ọrọ tiẹ, komisona ọlọpaa fun eto idibo gomina nipinle Ekiti, sọ nipa ọkan o jokan alakalẹ ti won ti ni lati pese eto aabo to peye fawọn oludibo.
CP Shogunle salaye pe wọn ti fi awọn oṣiṣẹ agbofinro ranṣẹ s'awọn ibi to yẹ káàkiri ipinle Ekiti lati ṣe aridaju eto aabo to peye.
Bakanna lo gb'awọn oludibo niyanju wi pe ki wọn jade lati wa dibo láì bẹru ohunkohun tori pe eto aabo to gbopọn ti wa nile fun wọn lọjọ ibo naa.