Agbébọn darandaran pá ọlọ́pàá méjì, ṣe ọ̀gá ọlọ́pàá léṣe ní Benue

Olatunji Disu, ọga ọlọpaa patapata nilẹ Naijiria ree lasiko to n sọrọ pẹlu ẹron gbohungbohun to mu dani

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue ti fidi rẹ mulẹ pe otitọ ni iroyin to n kaakiri nipa wi pe awọn agbebọn kan ṣe ikọlu si ọga ọlọpaa ẹkun Ayilamo nipinlẹ naa, ati ikọ akọwọrin rẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Peter Aondongu lo fidi iroyin naa mulẹ fawọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.

Aondongu ọ pe ọga ọlọpaa ẹkun ọhun lọ gba nnkan niluu Makurdi , ati pe asiko toun pẹlu ikọ akọwọrin rẹ n pada lọ si ibudo wọn, ni awọn agbebọn naa da wọn lọna.

"Ọga ọlọpaa yii wa siluu Makurdi lati gba nnkan ni, to si jẹ pe asiko lo n pada si Ayilamo ni wọn ṣe ikọlu si i, meji ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ ni wọn pa lasiko ikọlu ọhun," Aondongu ṣalaye fawọn akọroyin.

Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?

Ijọba ibilẹ Logo ni ẹkun Ayilamo ti awọn ọlọpaa ọhun ti n ṣiṣẹ wa, to si gbajumọ daadaa nibẹ.

Ọjọ Aje, ọsẹ yii ni a gbọ pe ikọlu ọhun waye, ni nnkan bi ọjọ mẹrin ti awọn darandaran ṣeku pa ọlọpaa mẹrin ati awọn araalu meje lagbegbe naa.

Lara awọn to fi iroyin ọhun to wa leti jẹ ko di mimọ pe ko tii pẹ ti wọn ṣẹṣẹ gbe awọn ọlọpaa naa de ẹkun Ayilamo, ki wọn too pade iku ojiji yii.

Wọn ni nnkan bi agogo mẹfa irọlẹ ọjọ Aje naa, iyẹn ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni awọn darandaran naa ṣe ikọlu si wọn.

Ọkan lara awọn to sọrọ, ti ko fẹẹ darukọ ara rẹ, ṣalaye pe "Ni nnkan bi agogo mẹfa, irọlẹ ọjọ Aje, awọn ọlọpaa tuntun ti MOPOL ti wọn ṣẹṣẹ gbe wa si Ayilamo ni wọn ṣe ikọlu si, ti wọn si pa wọn.

"Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lasiko ti awọn ọlọpaa naa n bọ wa si Ayilamo, nibi ti wọn ti kọwọrin pẹlu ọga wọn, to n bọ lati ilu Makurdi."

Njẹ́ irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti wáyé rí?

Awọn ara agbegbe naa sọ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn janduku agbebọn yoo maa ṣe ikọlu si agbegbe naa.

Wọn ni yatọ si awọn araalu ti awọn agbebọn ti igbagbọ wa pe wọn jẹ darandaran n ṣ ikọlu si, bẹẹ ni wọn tun n koju awọn ọlọpaa.

Lara awọn eeyan to fidi rẹ mulẹ sọ pe ko ju bi ọjọ mẹrin sẹyin ti awọn darandaran agbebọ ṣe ikọlu si Ayilamo, nibi ti wọn ti pa ọlọpaa mẹrin ati araalu meje, ni wọn tun ṣeku pa awọn ọlọpaa meji yii.