Ọlọ́pàá ká aṣọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbọn, ọta ìbọn, àti ọkọ̀ lákàtà afurasí adigunjalè, Surii Ilupeju ní Ibadan

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ayanlade Olayinka

Oríṣun àwòrán, Ayanlade Olayinka

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe oniruru ohun ija oloro, alupupu, ọkọ akero ati aṣọ ẹgbẹ oṣelu Accord loun ba lakata afurasi adigunjale, Surajudeen Babatunde Adio, ti inagijẹ rẹ n jẹ "Surii Ilupeju".

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Ayanlade Olayinka lo fidi ọrọ ọhun mulẹ ninu atẹjade kan.

Ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii ni ọlọpaa sọ pe oun mu Surii Ilupeju pẹlu afurasi mẹrin mii lori ẹsun idigunjale ati nini ohun ija oloro ni ikawọ wọn.

Ayanlade sọ pe asiko iwadii awọn lawọn ṣawari oniruru ohun ija oloro ni akata afurasi ọhun.

Awọn ohun ti ọlọpaa ri lakata Suri Ilupeju

Ibọn

  • Ibọn Pump-Action kan
  • Ibọn Single-Barrel kan
  • Ibọn Single-Barrel Cut-to-Size kan
  • Ibọ ilewọ ti wọn gbelẹrọ meji
  • Ibọn ilewọ Double-Barrel ti wọn gbelẹrọ kan
  • Ọta ibọn mẹtalelogun
  • Ọta ibọn AK-47 mẹjọ

Yatọ si awọn ibọn yii, ọlọpaa ni ohun tun ri awọn ọkọ lakata rẹ bii

  • Ọkọ akero Mazda to ni nọmba iforukọsilẹ FFE 08 XB;
  • Ọkọ akero Hummer kan to ni nọmba MUS 246 CK;
  • Ọkọ akero BAW kan to ni nọmba iforukọsilẹ KTU 688 YG;
  • Ọkọ akero Toyota kan
  • Ọkọ akero Toyota kan to ni nọmba idanimọ BDG 117 YK;
  • Ọkọ akero Toyota kan to ni nọmba idanimọ BRS 842 TW;
  • Ọkọ Sienna kan to ni nọmba idanimọ LSD 68 CJ;
  • Ọkọ Ford Sharon kan to ni nọmba idanimọ FKJ 39 EW;
  • Ọkọ Sienna kan to ni nọmba idanimọ BDG 986 SA;
  • Ọkọ Toyota Previa kan

Yatọ si awọn ọkọ yii,ọlọpaa ni oun tun ri awọn alupu nibẹ bii alupupu Suzuki Inazuma Power Bike kan, to fi mọ awọn alupupu Honda ti ko ṣiṣẹ.

Awọn nnkan mii ti wọn tun ri lakata rẹ gẹgẹ bii ọrọ ọlọpaa ni ọpọlọpọ aṣọ ati fila ipolongo ibo fun ẹgbẹ oṣelu Accord.

Ti ẹ ko ba gbagbe, inu ẹgbẹ oṣelu Accord yii ni Oriyomi Hamzat ti fẹ dije du ipo gomina ipinlẹ Oyo.

Amọ ṣa, Oriyomi ti sọ ni gbangba pe oun ko ni ibaṣepọ kankan pẹlu afurasi adigunle naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ awọn to ni awọn dukia naa ati ibaṣẹpọ wọn pẹlu awọn adigunjale to wọn mu.