A ò gba èsì ìbò tó gbé Oyebanji wọlé fún sáà kejì, ètò ìdìbò náà kún fún èrú - AAC

Oríṣun àwòrán, AAC/Biodun Oyebanji
Ẹgbẹ oṣelu Africa Action Congress, AAC tẹka ipinlẹ Ekiti ti kọ esi ibo to gbe Gomina Biodun Oyebanji fun saa keji.
Atẹjade ti alaga ẹgbẹ oṣelu AAC tẹka ipinle Ekiti, Makinde Folorunso fi lede lalẹ ọjọ Abamẹta, Ogunjọ, oṣu Kẹfa lẹyin ti eto idibo naa pari fẹsun kan pe awọn iwa ko tọ to waye nibi eto idbo naa ko kere.
Folorunso ni awọn iwa bii rira ati tita, didẹruba awọn ẹgbe alatako atawọn iwa ko tọ mii.
O ni awọn maa pe esi ibo naa nija nile ẹjọ nitori eto idibo naa ko lọ bo ṣe yẹ ati pe o jẹ abuku si eto ijọba awaarawa.
Alaga naa fẹsun kan gomina ipinlẹ Ekiti, Biodun Oyebanji sọ eto idibo di ohun abuku ati ẹtẹ pẹlu bi wọn ṣe fi owo ra ibo lọwọ awọn araalu.
"Gbogbo ibudo idibo ni a ti gbọ nipa rira ati tita ibo ni ipinlẹ Ekiti bi wọn ṣe n fun awọn eeyan lowo lati ra ibo wọn. Eyi kii ṣe abuku eto idibo nikan, o jẹ itabuku awọn araalu funra wọn."
Bakan naa lo tun fẹsun kan pe egbẹ oṣelu APC, to n ṣejọba ko faaye gba awọn ẹgbẹ oṣelu yooku, ti wọn si n lo gbogbo ọna lati tẹ wọn ri nibi eto idibo naa.
Folorunso ni ọpọ ọmọ egbẹ oṣelu awọn ni wọn ko jẹ ki wọn kopa lati dibo fun ẹni to wu wọn, to si ni eyi lodi si bo ṣe yẹ ki ijọba awaarawa siṣẹ tabi ki eto idibo waye ni orilẹ ede to ba fẹ mu iduroire ba idajọ ododo ati iṣe dọgbandọgba laaarin ilu.
O fi kun pe ohun to jẹ ki ẹgbẹ awọn tọwọbọ adehun alaafia ṣaaju eto idibo naa ni ifarajin awọn lati mu igbega bae to idibo to duro ire amọ ti awọn ba gba esi ibo yii tumọ si pe awọn ko tẹle adehun naa.
"A ko ni gba esi ibo to tẹ ẹtọ awọn eeyan wa lati yan ẹni to wu wọn loju mọlẹ.
"Ohun ti ẹgbẹ oṣelu AAC duro fun ni iṣejọ awaarawa tootọ ati ayipada rere to tọna fawọn ọmọ Naijiria.
"A ni igbagbọ ninu Naijiria ti esi ibo maa jẹ ohun tawọn eeyan dibo fun tootọ, ti ifẹ awọn araalu si wa si imuṣẹ."
Alaga naa bu ẹnu atẹ lu esi ibo ti ajọ eleto idibo Naijiria, INEC kede pe o gbe Oyebanji wọle fun saa keji, to si pe fun iwadii lori eto idibo ọhun paapaa lori awọn iwa ibajẹ ti wọn fẹsun kan pe o waye nibi eto idibo naa.
Bẹẹ naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa da aabo bo ijọba awaarawa ati lati maa ri daju pe wọn n tẹle ilana eto idibo ti ko lẹja n bakan ninu.
Ni oru mọju ọjọ Aiku ni ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC kede Gomina Oyebanji gẹgẹ bii olubori ibo gomina to waye lọjọ Abamẹta.
Ajọ naa kede pe Oyebanji la awon oludije yooku mọlẹ lati gba iṣakoso ipinlẹ Ekiti fun saa miran.
Alakoso eto idibo naa, Ọjọgbọn Adenikẹ Temidayọ Oladiji salaye pe Oyebanji to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ni ibo 319,224 lati gba ipo kiini bi Oluwole Oluyede ti PDP gba ipo keji pẹlu ibo 40,543 ti Oluwadare Bejide ti ADC si mu ibo 12,872 lati gba ipo kẹta

























