Èyí làwọn olóṣèlú tó fẹ́ dupò ààrẹ ní 2027 tórúkọ wọn gbilẹ̀ jù

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/Atiku Abubakar/Peter Obi/Goodluck Jonathan/X/Facebook
Lọwọlọwọ yii, o fẹrẹ jẹ pe gbogbo ẹgbẹ oṣelu pata ni wọn ti fẹnuko lori ẹni ti yoo dupo aarẹ fun ẹgbẹ wọn ninu idibo ọdun 2027 to n bọ lọna, lẹyin ti wọn ti dibo abẹnu tan.
Eto lori bi idibo ọhun yoo ṣe waye ti bẹrẹ, awọn ẹgbẹ ti orukọ wọn si gbilẹ ju gẹgẹ bii alatako fun APC ni ADC, NDC ati PDP, bo tilẹ jẹ pe awọn kan ti pin si igun ọtọọtọ ninu awọn ẹgbẹ yii.
Bi ajọ eleto idibo INEC ṣe n gbaradi, ti wọn n ṣe akọsilẹ awọn ẹgbẹ oṣelu, wọnyi ni diẹ ninu awọn to fẹ dupo aarẹ Naijiria ni 2026 ti ẹgbẹ wọn gbilẹ ju.
Bola Tinubu - APC
Bola Ahmed Tinubu ni aarẹ Naijiria lọwọlọwọ, o si jẹ olori ninu ẹgbẹ oṣelu Progressives Congress (APC).
Aarẹ Tinubu ti ṣe gomina ipinlẹ Eko fun ọdun mẹjọ ri, nigba ti wọn si dibo abẹnu APC fun ipo aarẹ nipari oṣu Karun-un ọdun 2026 yii, oun lo bori bii oludije ipo aarẹ ni 2027.
O fẹrẹ to ibo miliọnu mẹwaa ti iroyin sọ pe Aarẹ Tinubu ni ninu idibo abẹnu naa, lati fi ẹyin Stanley Osifo ti wọn jọ kopa janlẹ.
Ibo16,504 ni iroyin sọ pe Osifo ni ni tiẹ.
Nipa ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ, APC ati Tinubu funra rẹ ko ti I kede, ṣugbọn igbagbọ wa pe Sẹnetọ Kashim Shettima naa ni yoo maa tẹsiwaju pẹlu rẹ lọ.
Atiku Abubakar- ADC
Igbakeji aarẹ orilẹede yii tẹlẹ ni Atiku Abubakar, ni bayii, oun ni ẹgbẹ oṣelu ADC fun ni tikẹẹti lati dupo aarẹ ninu ẹgbẹ naa ni 2027.
Ninu idibo abẹnu ADC, Atiku ni ibo 1,846,370 lati fi ẹyin Rotimi Amaechi to gba 504,117 janlẹ, pẹlu Mohammed Hayatu-Deen to ṣe ipo kẹta.
Atiku ko ti I kede ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ, ṣugbọn afojusun wa pe o ṣee ṣe ko yan Rotimi Amaechi.
Peter Obi - NDC
Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ni Peter Obi, ọdun 2023 lo di gbajumọ nla, nigba to dije ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour.
Obi darapọ mọ ADC lati di aarẹ, o pada kuro nibẹ lọsan-an kan oru kan, o si di ọmọ ẹgbẹ NDC.
Awọn olori ẹgbẹ NDC gba a wọle, wọn si fẹnu ko o lati jẹ ko dupo aarẹ ninu ẹgbẹ naa ni 2027.
Lọjọ ti wọn fidi rẹ mulẹ pe Obi ni yoo dije, o kede gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Rabiu Musa Kwankwaso, bii ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ ti wọn yoo jọ dije.
Goodluck Jonathan – PDP
Aarẹ Naijiria laaarin ọdun 2010 si 2015 ni Goodluck Ebele Jonathan.
Lẹyin to fi awọn asiko kan sinmi ninu oṣelu, Jonathan fi erongba rẹ lati dupo aarẹ Naijiria han lẹẹkan si I ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Awijare rẹ ni pe awọn eeyan to gbagbọ ninu oun lo ni koun gbe igbesẹ naa.
O wọ igun Kabiru Turaki ninu PDP, bo tilẹ jẹ pe ija agba n fa rogbodiyan ninu PDP lọwọ.
Ta a lo ṣee ṣe ko ba APC fa a ju ninu awọn alatako yii?
Onimọ nipa eto oṣelu kan, Ọmọwe Kabiru Sufi, ṣalaye pe agbara ọtọọtọ ni awon alatako yii ni lati gbena woju APC.
O ṣalaye fun BBC pe iru eeyan ti kaluku wọn ba yan lati ṣe Igbakeji ati apa ibi ti Igbakeji gomina naa ba ti wa, ni ipa lori boya wọn yoo rọwọ mu tabi bẹẹ kọ.
"Bi awọn eeyan kan ko ṣe nifẹẹ si ijọba APC mọ tun jẹ ohun kan ti yoo sọ boya araalu yoo ṣi dibo fun wọn tabi bẹẹ kọ."
Kabiru Sufi lo ṣalaye bẹẹ.


























