Àwọn orílẹ̀èdè Áfríkà wo ló jẹ àjọ IMF lówó jùlọ ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Obitibiti gbese ti awọn orilẹede Afirika jẹ ajọ iṣuna IMF atawọn orilẹede miran to ti goke lagbaye kii ṣeohun to ṣokunkun si ọpọ, amọṣa ṣe eyi ko maa ṣe akoba ati ọpọ ewu fun awọn orilẹede ilẹ Afirika bayii? Eyi ṣe pataki lati mọ paapaa julọ bi o ba jẹ pe ẹyawo lawọn ọrọ aje bẹẹ n gbara le lati fi ṣe aayan iṣuna wọn ati lati ṣe atilẹyin fun idokoowo to yẹ gẹgẹbi iwe iroyin Business Insider Africa ṣe sọ.
Bi o tilẹ jẹ pe awọn orilẹede maa n lo owooya lati ajọ IMF lati fi ṣe eto ọrọ aje wọn, ẹru wiwo gbese ọlọjọ gbọọrọ lee bẹgidina idagbasoke, ko dina idurodeede agbara owo ati awọn nnkan miran lati agbaye bii bi owo epo ṣe n gbowo lori sii, ọwọngogo lagbaye tabi adinku bi owo ṣe n wọle labẹnu.
Awọn nnkan to n ṣẹlẹ lorilẹede Mozambique lẹnu lọwọlọwọ yii, gẹgẹbi ileeṣẹ iroyin Reuters, ati eyi to n ṣẹlẹ ni Angola ti tọka si awọn ewu wọnyii.
Awọn eeyan ti tana wo ọrọ Mozambique nitori ọrọ gbese ọrun rẹ ati bi o ṣe le rọrun fun un lati san an pẹlu bi ọkan gbogbo awọn onwoye ṣe n wa loke nitori pe gbese naa ti n kọja eyi ti wọn le mojuto, pẹlu ibẹru pe afaimọ ki o ma di eyi ti wọn yoo fi tipatikuuku dunadura lori awọn gbese naa.
Awọn nnkan bayii le mu ifasẹyin ba ifẹ awọn oludokoowo lati fẹ ko owo si inu ọrọ aje wọn.
Eyi lawọn orilẹede Afirika ti gbese ti wọn jẹ ajọ IMF pọ julọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eyi lawọn orilẹede Afirika ti gbese ti wọn jẹ ajọ IMF pọ julọ.
Iṣiro Owo dọla ilẹ Amẹrika ni wọn fi ṣi gbese naa.
- Egypt $7,245,182,524 (in USD)
- Ivory Coast $3,603,438,776 (in USD)
- Kenya $2,873,418,234 (in USD)
- Ghana $2,728,468,500 (in USD)
- Angola $2,437,716,676 (in USD)
- DRC $2,196,550,004 (in USD)
- Ethiopia $1,764,502,000 (in USD)
- Tanzania. $1,335,730,000 (in USD)
- Zambia $1,271,660,000 (in USD)
- Cameroon. $1,152,990,000 (in USD)
Awọn orilẹede Afirika mẹwaa ti gbese ti wọn jẹ ajọ IMF kere julọ
- Namibia
- Lesotho
- Comoros
- Djibouti
- Sao Tome and Principe
- Equatorial Guinea
- Guinea-Bissau
- Cape Verde
- Burundi


























