Ẹgbẹ́ àwọn gómìnà bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti máa san ₦100,000 gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ

Gbọgan ipade awọn gomina ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Nigeria Governors' Forum

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria ti kede pe awọn ti n jiroro lori igbesẹ lati maa san ₦100,000 gẹgẹ bii owo oṣu oṣisẹ to kere julọ ni Naijiria.

Wọn ni eyii jẹ ọkan lara awọn ọna lati mu aye dẹrun fun awọn oṣiṣẹ naa latari bi ọrọ aje Naijiria ṣe le koko lonii.

Alaga ẹgbẹ awọn gomina ọhun to tun jẹ gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju opo Facebook.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn gomina mọ pe nnkan ko rọgbọ fun awọn araalu latari ọwọngogo to gbode, awọn si n gbe igbesẹ lati wa ọna abayọ si iṣoro naa.

AbdulRazaq sọ pe awọn gomina ti n ba ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ jiroro lori bi igbesẹ naa yoo ṣe di ṣiṣẹ ti ko tun ni pa ojuṣe ijọba mii lara.

O ni "Awọn ijọba ipinlẹ ri pe o yẹ ka maye dẹrun fun awọn oṣiṣẹ ni kankan ni idahun si ọwọngogo to n koju awọn ọmọ Naijiria lasiko yii.

"A ti bẹrẹ ijiroro pẹlu ijọba apapọ atawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lati fẹnuko lori iye owo ti yoo yẹ awọn oṣiṣẹ ti ko si ni ṣakoba fun ojusẹ ijọba mii."

AbdulRazaq ṣalaye pe afojusun awọn ni bi awọn yoo ṣe le san owo to yẹ awọn oṣiṣẹ fun wọn ki awọn tun le lanfani lati maa ṣiṣẹ sin awọn aralu mii ti kii ṣe oṣiṣẹ ijọba.

Ọpọ awọn oṣisẹ ni Naijiria lo ti n kerora ọwọngogo to gbode bẹrẹ lati owo epo bẹntiro, si owo gaasi idana, atawọn nnkan mii.

Lọwọ yii, ₦70,000 ni owo oṣu oṣiṣẹ ijọba to kere julọ ni Naijiria bo tilẹ jẹ pe ọpọ oṣiṣẹ ileeṣẹ aladani mii ni ko le san to iye owo ọhun.

Amọ ṣa, awọn ipinlẹ kan bii Eko, Rivers ati Imo ni a gbọ pe wọn n san owo to pọ ju ₦70,000 to jẹ iye owo oṣu to kere julọ yii.

Wayi o, ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC, ko dake lati maa ke si ijọba loorekoore pe ko san owo to to fun awọn oṣiṣẹ ki aye le dẹrun fun wọn.