'A ò lè lọ síbi iṣẹ́ mọ́ torí àwọn olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso,' àwọn olùkọ́ ṣèfẹ̀hónúhàn l'Oyo

Awon olukọni ni ipinlẹ Oyo ṣe iwọde alaafia lati pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn jigbe nile ẹkọ ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin bayii.
Ifehonuhan naa waye ni ilu Ibadan, Ogbomosho, Oyo ati ilu Iseyin.
Awọn olukọ naa bẹrẹ iwọde wọn lati agbegbe Iwo road niluu Ibadan ti wọn si gba Idi-ape, Gate titi de ọfiisi ijọba Ipinlẹ Oyo ni Agodi niluu ibadan.
Nigba ti o n sọrọ nibi ifẹhonuhan naa, Olusoaguntan Bunmi Thomas ṣalaye wi pe ifẹhonuhan ti ẹgbẹ olukọ n ṣe wa ni ibamu pẹlu ofin orile-ede Naijiria.
Ọjọ Ẹti ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun un yii lo pe ọṣẹ meji ti awọn agbebon ji awọn olukọ ati akẹkọọ to le logoji gbe niluu Yawota ati Ahoro Esinele ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ.
''A o le lọ sibi iṣe mọ, ẹru n ba wa''
Ọkan lara awọn to kopa ninu ifẹhonuhan naa, Odunayo Ajala, ṣalaye wi pe ọpọ olukọ ni ẹru n ba bayii lati lọ sibi iṣe nitori iṣẹlẹ ijinigbe to waye l'Ogbomoso.
Odunayo ni "nibi ti isẹlẹ buruku yìí ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti n ṣíṣe ijọba ibilẹ Orire, a jade lati jẹ ki ijọba ran wa lọwọ lati gba awọn akẹgbẹ wa atawọn akẹkọọ wa jade ni ahamo awọn agbebon.
A fẹ ki ijọba ran wa lọwọ, ọmọ ọdun kan aabọ wa ninu awọn ti wọn ko yii.
Awọn ti wọn ti pa bi ẹran wá nibẹ, a bẹ ijọba Ipinlẹ Oyo ki wọn jọọ nítorí Ọlọrun, abiamọ lawọn naa, ki wọn saanu wa.
A o le lọ sibi iṣe mọ, inu igbo lọpọlọpọ wa ti n ṣíṣe ẹru n ba wá, gbogbo ọgba ile ẹkọ wa ni ko ti si aabo.
''Ijọba Ipinlẹ Oyo n gbiyanju lati doola awọn ti wọn ji gbe, sugbọn gbogbo aṣọ ko ni a fi n sa loorun''
Ẹwẹ, agbenuso fun gomina Ipinlẹ Oyo to tun jẹ oludamoran si gomina Seyi Makinde lori eto aabo, Sunday Odukoya, ni Ijọba Ipinlẹ Oyo n ṣíṣe takuntakun lati ri wi pe awọn to wa ni ahamo awọn agbebon gba ominira.
Odukoya ni "mo n fi dayin loju wi pe gbogbo igbese ni gomina Seyi n gbe lati ri wi pe awọn to wa ni ahamo awọn agbebon gba ominira, sugbọn ki i ṣe gbogbo iroyin ati igbese ijọba la maa sọ sita nitori a o mo alami awọn agbebon naa to wa ni itosi.
Lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti n lọ si agbegbe naa, koda yoo ti to igba mọkanla ti mo ti nlọ si agbegbe Yawota ati Ahoro Esinele bayii, awọn olugbe agbegbe naa le jẹrii si i.''
O fi da awọn olukọ to n ṣe ifẹhonuhan naa loju wi pe ijọba Ipinlẹ Oyo ko ni le won kuro nisẹ nitori won kopa ninu ifẹhonuhan.


























