''Èyi ni ipa tí Bàba-bàbá mi kó nínú ogun abẹ́lé Biafra''-Meji Alabi, gbajúmọ̀ adarí orin

 Meji Alabi, o ṣe irun dada sori, o ni irungbọn, bẹẹ lo n wo oju kamẹra ninu aworn yii.

Oríṣun àwòrán, Meji Alabi

Àkọlé àwòrán, Meji Alabi, gbajumọ nipa awon ara ọtọ fidio to maa n gbe jade. O fẹ lati maa gbe awon itan idaamu to koju awon Naijiria laye ọjọsi, koda, kọja iroyin ogun ti baba-baba rẹ sọ fun un ri.
    • Author, Tamasin Ford
    • Role, BBC Africa Eye
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10
Àkọlé fídíò, ''Èyi ni ipa tí Bàba-bàbá mi kó nínú ogun abẹ́lé Biafra''- Meji Alabi, gbajúmọ̀ adarí orin

Gbajugbaja adari orin ni Meji Alabi, o ti dari awọn awọ orin awọn elere nla to lorukọ lagbaaye daadaa: Awọn bii : Beyoncé, Burna Boy, Davido ati Stormzy. Ṣugbọn ko to igbaradi ti Meji Alabi to ti gba ami ẹyẹ nla Grammy gbe kalẹ lori itan Ogun abẹle Naijiria.

Ikilọ: Awọn ohun to le daamu ọkan wa ninu àyọkà yii.

Líla Biafra ja: Awọn ohùn lati ibi ogun abẹle Naijiria, eti ti BBC Africa Eye gbe jade, tun ṣafihan awọn fidio ti ẹnikẹni ko ri ri, ti wọn ya loju ogun lile to waye lati 1967 titi di1970 naa, lasiko ti ogun ẹlẹyamẹya fẹju toto, to si fẹ pin apa Ila Oorun Africa to ṣẹṣẹ n dide nigba naa ka.

"Ilaniloye lo jẹ fun mi. Mo kan dagba lai mọ nnkan pupọ nipa ogun naa rara, tabi pe awon wo lo tiẹ ja a."

Bẹẹ ni Meji Labi, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ( 37) ti wọn bi si London sọ. Ọmọ Naijiria ni awọn obi rẹ ko too lọ si Texas, ni US lati kawe.

Gongo ẹka iṣẹ rẹ waye ni nnkan bii ọdun marun-un sẹyin, nigba to gba ami ẹyẹ fun bo ṣe ba wọn kopa ninu idari fidio orin Beyoncé ti a mọ si Brown Skin Girl.

Nigba to sowopọ pẹlu ẹgbọn rẹ, Leke Alabi-Isama, toun naa jẹ ẹni to n ṣe fiimu, ti wọn si jọ da ileeṣẹ fiimu ati aworan silẹ l'Eko, iyẹn PriorGold Pictures, lati ṣe akojọpọ awọn iṣẹ bẹẹ ti wọn jọ bẹrẹ, ni wọn too mọ bi ogun abẹle to koju Naijiria naa ṣe le to.

Iwọnba diẹ ti wọn mọ naa wa lati ọdọ Baba Leke ati baba to bi Baba Meji; Godwin Alabi-Isama, olori ogun nigba kan to ja fun ijọba apapọ Naijiria, tako awọn ẹya Igbo to n pe fun iyapa ni Guusu Ila-Oorun orilẹede yii, ti wọn ni awọn fẹ kuro lara Naijiria lati da ilu ti a o maa pe ni Biafra silẹ.

Ṣọja Naijiria kan fi ara ti ọkọ ologun ti wọn gbe kalẹ si ẹba ọna- igbo kijikiji wa lẹyin wọn.Awọn ologun miran naa wa nibẹ, aworan aye ọjọun to maa n gbe funfu n ati dudu jade ni fọto naa, ki i ṣe ti awọ arambara bii ti asiko yii.

Oríṣun àwòrán, Godwin Alabi-Isama

Àkọlé àwòrán, Godwin Alabi-Isama, Baba to bi Leke ati Baba to bi Baba Meji, ree ninu aworan yii ti wọn ya lasiko ogun abẹle, o n lo irinṣẹ ibaraẹnisọrọ igba naa ti a mọ si "two-way radio"
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Oju ti awọn ologun Naijiria (ologun apapọ) fi wo o nikan ni mo fi ri i tẹlẹ, mi o mọ nipa oró to mu wa, mi o mọ nipa inira ati ijiya to waye lapa keji."

Leke lo sọ bẹẹ.

Ni gbogbo igba ti Africa Eye fi n ko akọjọpọ iroyin jọ, awọn to ye ogun naa ti wọn ti pe ẹni aadọrin si ọgọrin ọdun bayii (70- 80), ṣalaye ohun ti oju wọn ri to si nipa lori bi wọn ṣe gbele aye nigba naa, koda, to ṣi n ba igba mu titi di asiko yii.

Rogbodiyan naa, ti a tun mọ si ogun Biafra, bẹrẹ lẹyin awọn iditẹgbajọba kan ati lẹyin oṣu diẹ ti wọn pa ọpọ ọmọ ẹya Igbo to n gbe ni Ariwa Naijiria.

O to miliọnu kan awọn ẹya Igbo to pada si ilu abinibi wọn ni Guusu Ila -Oorun orilẹede yii, nibi ti ipinlẹ mẹta ti ya kuro lara ilẹ Olominira Biafra.

Ijọba Naijiria kede ogun- ọkan lara awọn ogun to mu itajẹsilẹ to lagbara wa, ti si tun mu ẹlẹyamẹya dani pẹlu, ti iru rẹ fẹrẹ ma ṣẹlẹ ri nilẹ Adulawọ.

Akọsilẹ sọ pe laaarin eeyan ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ( 500,000 si miliọnu mẹta eeyan lo ku).

Pupọ awọn eeyan wọnyi ni wọn jẹ ọmọde, iṣẹlẹ yii si di akọkọ iru ẹ to buru ju lawujọ eeyan, ti wọn gbe jade lori amohunmaworan.

Awọn ẹṣọ obinrin ikọ Aabo ara ẹni laabo ilu (Civil Defence) n gbaradi niluu Enugu, nibi ti wọn pe ni olu ilu Biafra. Wọn ya aworan yii loṣu Kẹjọ ọdun 1967.
Wọn wọ aṣọ funfun ati alawọ dudu.

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ẹṣọ obinrin ikọ Aabo ara ẹni laabo ilu (Civil Defence) n gbaradi niluu Enugu, nibi ti wọn pe ni olu ilu Biafra. Wọn ya aworan yii loṣu Kẹjọ ọdun 1967.

Awọn fidio ati aworan to buru lati wo to jade nigba naa ṣafihan awon ọmọde ti ebi gidi n pa lori amohunmaworan, awọn eeyan ri i wo kaakiri fun igba akọkọ nilee wọn. Eyi si jẹ lẹyin ọgbọn oṣu (30 months) ti wọn ti n jagun ki Biafra too pari.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo jẹ pe nipa itan atẹnudẹnu ni wọn fi gbọ nipa ohun to ṣẹlẹ ninu ogun yii.

O ju ọdun mẹwaa lọ ti ko fi si ẹkọ nipa itan ninu iṣẹ tawọn akẹkọọ n ṣe ni Naijiria mọ, ko too di oṣu Kẹsan-an ọdun 2025 .

Ni ti Leke, ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44), ti wọn bi si ilu Abeokuta, ipinlẹ Ogun ni Guusu Iwọ Oorun Naijiria to si dagba sibẹ, ninu iwe lo ti ri awọn nnkan kan tabi meji mu nipa ogun yii.

"Wọn ko yanna-na ẹ kun to, ṣe ẹ mọ, bawọn eeyan ṣe jiya to. Emi si ro pe ẹru n ba Naijiria lati koju otitọ rẹ ni."

Bẹẹ ni Leke wi.

Leke ati awọn aburo rẹ mẹtalelogun (23) gbọ awọn itan yii lati ọdọ baba wọn, Godwin Alabi-Isama, bi wọn ṣe n dagba.

Baba wọn ni olori awọn oṣiṣẹ fun Ọgagun Benjamin Adekunle, ti ikọ ologun 3 Marine Commando, lasiko ogun naa.

"Niṣe lo fi han pe baba mi gbajumọ fun iranlọwọ to ṣe lati fun awọn ilu ati abule ni ominira. Mo ri i bii akọni loju ogun."

Leke lo ṣalaye bẹẹ.

Leke Alabi-Isama
BBC
The first time I saw those clips of people, children starved… it was horrific. And I think that was a moment of truth for me"
Filmmaker Leke Alabi-Isama

Nigba ti Leke pe ẹni ọgbọn ọdun o le diẹ lo bẹrẹ si i ṣe iwadii ohun to ṣẹlẹ lasiko ogun naa.

Nigba naa lo mọ nipa ebi ọpapanla to pa awon eeyan lasiko ogun Biafra, ipa to mu ariyanjiyan dani ti baba rẹ ko ninu ogun naa, ati ijiya tootọ ti ogun naa mu dani.

Ikọ ologun ijọba apapọ, titi kan 3 Marine Commando, koju ẹsun ogun ti wọn fi kan wọn fun Biafra, wọn tun fẹsun kan wọn pe wọn n pe awọn araalu paapaa.

"Ni igba akọkọ ti mo ri fidio awon eeyan yẹn, awọn ọmọde ti ebi ti pa… o buru jai.

Fun emi o, akoko otitọ farahan ni. " Leke lo sọ bẹẹ.

"Iyẹn ni asiko ti idaamu ogun yẹn ti han kedere lododo. To fi han gedegbe pe loootọ, ohun ti buru jai n ṣẹlẹ ni igun keji.

"Nigba to ba han si ọ pe otitọ tiwọ n ri nikan kọ ni otitọ, akoko ti eeyan yoo rẹ ara rẹ nilẹ ni."

Leke ati Meji sọ pe ko ye awọn bi ko ṣe si ọpọ fiimu to n sọ nipa ogun Biafra ni Naijiria, wọn ni eyi n jẹ ko ṣoro lati ri idi otitọ ohun to ṣẹlẹ gan-an.

Eyi jẹ ọkan lara awọn idi ti awọn mejeeji ti wọn maa n ba awọn gbajumọ olorin ilẹ okeere ṣe, ṣe fẹẹ gbe itan yii kalẹ.

Meji Alabi, o de fila pupa, o wọ aṣọ funfun, ṣokoto kekere dudu, ibọsẹ ati bata funfun. O gbe kamẹra dani, na ọwọ rẹ siwaju bo ṣe n dari iṣẹ, awọn obinrin kan jokoo, bẹẹ ni awon eeyan kan naa duro ninu aworan yii.

Oríṣun àwòrán, Meji Alabi

Àkọlé àwòrán, Meji Alabi lo nawọ rẹ siwaju yii, nibi to ti n dari iṣẹ kan.

"Wọn n sọ ọrọ naa labẹlẹ ni".

Meji sọ pe awọn fidio orin oun maa n ko ipa pataki ninu mimu atẹ orin Naijiria wọ ọja agbaye, pẹlu awon ilana orin ati eto ti Naijiria n ṣamulo, to maa n jọ ọpọ awon ti ko mọ nipa rẹ laye loju.

"O n mu ori ya, ẹ mọ, to tun jẹ awọn ọdọ to maa n fẹ mọ si i lo n gbe e kalẹ."

Meji lo ṣalaye bẹẹ.

Agbekalẹ ti wọn bẹrẹ yii ko ọpọ awọn to ni ẹbun oriṣiriṣi kaakiri ẹkun jọ- Bi Meji ṣe n sọ fun olorin ilẹ Ghana nni, Ray Michael Djan Jr, to ṣiṣẹ lori orin Black Panther: Wakanda Forever, lati ṣe orin.

Bakan naa lo tun fọkan si ọdọ awọn ẹya BBC Igbo, awọn to mọ itan ilẹ Igbo lati gbe akojọpọ yii kalẹ, pẹlu afikun lati ẹnu awọn o ṣoju mi koro atawọn ti ko ba ogun Biafra lọ ti won le royin rẹ lasiko yii, nitori awon mi-in wa ninu wọn ti wọn ko ti i lanu sọ ohun toju wọn ri jade ri.

"Iran yii ti n ṣe bẹẹ wọ ookun lọ, bi a ko ba si da aabo bo awon ohun ti won ba sọ bayiii, bi a ṣe maa sọ ọpọlọpọ itan nu niyẹn.

Ṣugbọn a ni lati wa ọna ti a maa fi ṣe akojọpọ rẹ si oju kan, lọna to maa jẹ ki ohun to ṣẹlẹ ye awon eeyan, ti yoo si tu ọkan wọn lara."

Bẹẹ ni Leke wi.

Meji ninu awon eeyan to maa kopa gboogi ninu agbekalẹ yii jẹ sọja tẹle, obinrin ni won, wọn ja fun igun keji.

O tun wa awọn ifọrọwanilẹnuwo si i pẹlu, pẹlu iranlọwọ akọroyin BBC tẹlẹ; Martin Bell, ẹni ti wọn jọ ka ẹhonu wọn nipa idahun ti awọn ilẹ okeere fọ si rogbodiyan to ṣẹlẹ.

Bi Leke ati Meji ṣe ti gbọ ọpọ itan lati ọdọ Godwin Alabi-Isama tẹlẹ, wọn ko ti i ni anfaani lati beere awọn ibeere to le kan.

Ikọ iroyin BBC ṣaaju ifọrọwerọ naa lati ri i pe olori ogun tẹlẹ naa sọrọ lori ẹsun ti won fi kan an tako ikọ ologun 3 Marine Commando.

Lasiko rogbodiyan naa, ijọba Naijiria tun di ọna ti ounjẹ n gba wọle fawọn Biafra - wọn ko jẹ ki wọn ri nnkan kan gba lati papa ọkọ oju omi, ti oke ati ti ilẹ ibomi-in.

Bi wọn ṣe di wọn pa lati ma ri ounjẹ gba yii lo fa ìyàn to mu, ero ọkan ọpọ eeyan si ni pe ebi lo pa ẹgbẹẹbẹrun awọn to di oloogbe ti won fi ku.

Leke ṣapejuwe asiko naa, o ṣafihan baba rẹ ninu aworan dudu ati funfun aye ọjọun, nibi ti ebi ti sọ ọpọlọmọ ọmọde di ọpẹlẹngẹ tan.

O ni lati ọdun kẹtalelogoji ti oun ti dele aye yii, oun ko gbọ ki ohùn ẹnu baba oun gbọ̀n ri, afi ti igba ogun to le gidi naa.

"Koda, ni gbogbo igba ti mo ba n wo o pada, ti mo ba wo o de apa ibẹ yẹn, ara mi maa n bu maṣọ ni."

Bẹẹ ni Leke tẹsiwaju ninu ohun ti ogun naa maa n ṣe si iranti rẹ.

Lasiko ifọrọwerọ naa, baba rẹ sọ bo ṣe jẹ pe oun ko mọ pe oun ti jẹ ẹran eeyan.

Asiko ti wọn n jẹ ara eeyan ni, o ni awon ara abule to wa ni agbegbe Biafra gbe ounjẹ foun lati jẹ.

Nipa akojọpọ iṣẹlẹ to n bọ yii ( Documentary) ijọba Naijiria sọ pe Nigeria ireti awon ni pe yoo jẹ iranti nipa ohun ti oju ilu yii ti ri lati ọdun mọkandinlọgọta (59) sẹyin.

"Ati bi ibaraẹni sọrọ ṣe ṣe pataki to, ti ajoṣe pada ati nini ero ire kan naa fun idagbasoke si ṣe jẹ koko to fun irandiran to n bọ."

Leke ati Meji fẹran eyi ati ọpọ iru rẹ.

"Ireti mi ni pe fiimu yii yoo mu kawọn ọmọ Naijiria le koju awọn apa ibi to ṣokunkun ninu itan ilẹ wa pẹlu otitọ, irori ati aanu." Leke lo sọ bẹẹ.

Meji paapaa gba bẹẹ, o ni:

"Ireti wa ni pe akojọpọ ti a fẹ gbe kalẹ yii yoo jẹ ki ọpọ awọn to ye ogun yii jade lati sọ itan wọn, ka si ṣe akọsilẹ itan wa si i. Ọwọ wa lo ku si lati ṣe e."

Afikun iroyin lati ọwọ Charlie Northcott, Izzy Fleming ati Adline Okere.

A map showing di territory of Biafra from 1967 to 1970