Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ 20 ni mo kọ̀wé fún, ṣùgbọ́n mẹ́rin péré ni mo rí gbà - Akẹ́kọ̀ọ́ tó gba First Class
Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ 20 ni mo kọ̀wé fún, ṣùgbọ́n mẹ́rin péré ni mo rí gbà - Akẹ́kọ̀ọ́ tó gba First Class
Published
Laipẹ yii ni fasiti ilu Ilọrin nipinlẹ Kwara ṣeto ayẹyẹ ikẹkọọgboye, ti wọn si ṣafihan awọn akẹkọọgboye ti wọn peregede julọ lẹnu ẹkọ wọn.
Bilesanmi Tobiloba naa wa lara awọn akẹkọọgboye tuntunt o ṣe daadaa ni fasiti naa.
Nigba to n ba BBC sọrọ, ọmọbinrin naa ṣalaye irin ajo rẹ, ati bo ṣe tiraka lati de ipo naa, pẹlu afojusun rẹ lẹyin ọdun marun-un si asiko yii.
Bilesanmi sọ pe oun ko wa lati inu idile olowo, ṣugbọn to sọ pe awọn obi oun tiraka lati ran oun atawọn yooku oun nile ẹkọ, lati ṣe aṣeyọri.



