Kí ló mú Davido ṣẹ́wélé orin kíkọ fún oṣù méjì báyìí? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Davido/Facebook
Gbajugbaja akọrin takasufee, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido, ti kede wi pe oun yoo ṣe gaaya fun orin kikọ bayii.
Davido ṣalaye pe oun gbe igbesẹ yii lati ṣe ipolongo ibo fun Gomina Ademola Adeleke to fẹ dupo gomina ipinlẹ fun saa keji.
Laarin ọsẹ yii ni Davido sọrọ naa niluu Ede lasiko ti ifilọlẹ igbimọ ọdọ ti yoo ṣe ipolongo ibo ti wọn pe orukọ rẹ ni Imole Youth Campaign Mobilisation Team waye.
Akọrin takasufee naa sọ pe oun ṣẹwele orin kikọ fun igba diẹ lati le raye ṣe ipolongo ibo kaakiri ẹsẹ kuuku nipinlẹ Osun ṣaaju eto idibo gomina to n bọ.
Nigba ti o n bawọn ọmọ igbimọ naa sọrọ, Davido ni oun ṣetan lati sapa oun lati ri pe Adeleke jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Osun.
''Mo ti ṣẹwele orin kikọ fun oṣu meji bayii lati le ṣiṣẹ fun aburo baba mi.
Mi o gbe igbesẹ yii nitori pe Gomina Adeleke jẹ aburo baba mi, ṣugbọn nitori pe o n ṣiṣẹ daadaa nipinlẹ Osun.
O si ṣe pataki ki o wọle ẹẹkeji ki o le pari iṣẹ to n ṣe nipinlẹ Osun, iṣẹ si ku lati ṣe fun Gomina Adeleke.
A maa lo gbogbo agbara wa, a si maa ṣe atilẹyin fun gomina lati wọle fun saa keji.
Ẹgbẹ ọdọ yii ṣe pataki tori wọn lagbara lati ṣe ipolongo ibo daadaa,'' Davido lo sọ bẹẹ.
''A o ṣe ipolongo ibo lati ojule de ojule ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Osun''
Akọrin takasufee naa wa rọ gbogbo ọdọ to wa ninu ẹgbẹ ọhun lati kara mọ ipolongo ibo ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Osun.
''Ẹ jẹ ka ṣe ipolongo ibo lati ojule de ojule ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Osun.
Ẹ jẹ ki a sọ fawọn araalu nipa awọn nnkan ti ijọba Ademola Adeleke ti ṣe ati awọn nnkan to n si n gbero lati ṣe.
Gbogbo awọn eeyan to wa ni ayika wa ni ẹ jẹ ka ba sọrọ nipa iṣẹ ti gomina n ṣe,'' Davido lo sọ bẹẹ.
Davido ni alaga igbimọ naa, nigba ti Adeshina Kayode Olododo jẹ igbakeji rẹ; Họnọrebu Gbenga Idowu ni akọwe ẹgbẹ.
Awọn ọmọ ẹgbẹ mii ni Mutiu Oladimeji, Họnarebu Tomiwa Babalola; Họnarebu Mayowa Oloso ati Họnarebu Olatunji Awodiran.
Otunba Tunde Badmus; Họnarebu Dapo Okunola; Họnarebu Majeed Salami; Oloye Owodunni Abiodun Ramon; ati Deji Bello naa wa lara awọn ọmo ẹgbẹ ọhun.




























