Tọkọtaya gbajúmọ̀ òṣèré, Lateef Adedimeji àti aya rẹ̀, Adebimpe bí ìbẹta

Oríṣun àwòrán, Adedimeji Adetola Lateef/InstagramLateef
Yoruba ni lẹyin onisuuru ni Ọlọrun wa tori bi ẹkun pẹ titi di alẹ, ayọ n bọ ni owurọ.
Bẹẹ ni ọrọ ri ni agboole tiata bayii bi gbajumọ osere meji se gbalejo ọmọ tuntun mẹta lanti-lanti.
Lateef Adedimeji ati aya rẹ, Adebimpe Oyebade Adedimeji si ni Ọlọrun fi ẹbun ọmọ mẹta kẹ ni ẹẹkan soso.
Baba ati iya ibẹta naa si ni ọpọ awọn ololufẹ wọn ti n ki ku oriire naa.
Bawo ni ikede ayọ naa se de ori ayelujara?
Baba ibẹta, Lateef Adedimeji lo fi ikede naa sori ayelujara ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ ni owurọ oni, ọjọ kini osu karun ọdun 2026.
Ninu fidio naa la ti ri Lateef ti aya rẹ fi ọwọ kọ lọrun, ti wọn si dijọ de fila ti wọn kọ akọle Baba ati Mama si lori.
Iya ibẹta, to so ọwọ mejeeji mọ ọkọ rẹ lọrun, lo mu ayẹwo ọmọ mẹta lọwọ, pẹlu aworan fila mẹta, ibọsẹ mẹta ati ibọwọ mẹta.
Koda, orin awa ti bimọ, dandan ni ka yọ fun Ọlọmọ ni wọn kọ sori fidio naa.
Lara ohun ti Lateef kọ sinu fidio naa niyi:
"Awọn ọmọ Adedimeji, a ti n fi nnkan pamọ fun yin.
Lọdun 2026 yii, Ọlọrun fun wa ju ohun ti a beere lọwọ Ọlọrun.
Obinrin yii ti fun mi ni ọmọ mẹta ti maa pe ni awọn ọmọ mi, ọba mẹta ti wọn jẹ ojuse mi"
Ọpọ eeyan si lo ti n ki baba ati iya mẹta naa ku oriire.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Awọn eeyan ti bu ẹnu atẹ lu Mo Bimpe, ti wọn ti pe e ni agan tẹlẹ, ti wọn to ki ku ayọ ọmọ mẹta bayii
Ọkan lara awọn oṣere tiata ti awọn eeyan fẹran pupọ bii lọkọlaya ni Lateef Adedimeji ati Mo Bimpe.
Latigba ti wọn ti ṣegbeyawo lọdun 2021 ni wọn ti di ẹni ti ọpọ eeyan n fẹran lori ayelujara fun bi wọn ṣe jọ maa n ṣiṣẹ pọ.
Bi iroyin ayọ si ṣe bẹrẹ si i ti idile Adedimeji jade wa bayii, niṣe ni gbogbo aye n ki wọn ku oriire aladipele to wọle tọ wọn wa.
Awọn eeyan ti wọn si ti bu ẹnu atẹ lu Mo Bimpe, ti wọn ti pe e ni agan tẹlẹ ti n ki I ku ayọ ọmọ mẹta bayii.
Bẹẹ ni wọn n pe Lateef naa ni Baba Ibẹta lẹẹkan ṣoṣo

Oríṣun àwòrán, Lateef Adedimeji/Facebook
Ta a ni Lateef Adedimeji?
Lateef Adetola Adedimeji jẹ ọmọ bibi ilu Abeokuta, ọjọ Kin-in-ni oṣu Keji ọdun 1986 ni wọn bi i.
Ọdọ langba lo wa to ti bẹrẹ si I kopa ninu ere ori itage. Ọpọ ami ẹyẹ lo si pada gba, bo tilẹ jẹ pe o ti figba kan jẹ ẹni ti aye ko mọ ri.
Lateef kẹkọọ gboye ninu iṣẹ iroyin.
Oṣere tiata to mọ bi wọn ṣe n gbe ipa ọlọkan-o-jọkan kalẹ ni, paapaa to ba di abala ki eeyan sunkun bii pe ohun to n ṣẹlẹ ninu fiimu naa n ṣẹlẹ si I loju aye ni.
Adedimeji ti kopa ninu ọpọ ere Yoruba, odu ni nibẹ ko too di pe oun ati iyawo rẹ, Mo Bimpe fi ifẹ wọn han saye.
Nibẹrẹ ajọṣepọ Lateef ati Bimpe, wọn fi ifẹ naa pamọ.
Bi ọpọ akọroyin to n ri wọn pọ si ṣẹ n beere pe ṣe ifẹ wa laaarin wọn ni, niṣe ni awọn mejeeji maa n sọ pe iṣẹ lo da awọn pọ, ifẹ kọ.
Ṣugbọn nigba ti 2021 n lọ sopin, Lateef ati Mo Bimpe kede pe awọn fẹ ṣegbeyawo, wọn si pada ṣe e loṣu Kejila ọdun 2021.
Latigba naa ni awọn eeyan ti n foju sọna pe ki wọn di ọlọmọ laye, amọ ko ri bẹẹ.
Ko too di ọjọ kin-in-ni oṣu Karun-un ọdun 2026 yii, ti Lateef kede pe oun ati Mo Bimpe ti di Baba ati Iya Ibẹta!

Oríṣun àwòrán, ADEBIMPE OYEBADE her/Instagram
Ta a ni Mo Bimpe?
Adebimpe Oyebade gan-an ni orukọ rẹ, ọmọ bibi Ijero Ekiti, nipinlẹ Ekiti ni.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta ọdun 1997 ni wọn bi i.
Adebimpe kẹkọọ gboye ninu ede oyinbo nile ẹkọ Fasiti ipinlẹ Ekiti.
Oṣere tiata ni Bimpe Oyebade tawọn eeyan mọ si Mo Bimpe, bẹẹ lo si tun mọ nipa irin oge (Modelling).
Oniṣowo ni pẹlu.
Ọdun 2016 lo di gbajumọ oṣere lagbo tiata Yoruba, ti wọn n lo o ninu awọn sinima ọlọkan -o-jọkan kiri.
Oun ati Lateef Adedimeji ti wọn jọ maa n wa papọ, ti aarin wọn si gun rege ni wọn pada jọ fẹra wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji maa n sọ pe ko si nnkan kan laarin awon ju iṣẹ tiata lọ ni.
Wọn ṣegbeyawo loṣu Kejila ọdun 2021, amọ ko si ọmọ ninu ajọṣepọ naa fun ọdun marun-un gbako.
Ọpọ igba ni awon eeyan ti sọrọ kobakungbe si Mo Bimpe lori ayelujara pẹlu aitete bimọ rẹ.
Bawọn kan ṣe sọ pe o ti lo ile ọmọ rẹ fun okiki ni ẹnikan sọ fun un ri pe ko ni itiju ati irori rara.
Ẹni naa sọ pe Bimpe ko mọ ju aṣọ lọ.
Ṣaaju Ibẹta to bi yii, iroyin ti jade ri pe oṣere naa loyun, awọn mi-in si ṣo pe o ti bimọ.
Ṣugbọn Lateef ati iyawo rẹ ko fidi iru rẹ mulẹ ri, afi ni bayii ti ọkọ gbe fidio jade, to n kede ibẹta lantilanti.



























