Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé fítámì tó lè ṣe ara rẹ lóore wà nínú ọtí? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii kan tawọn onimọ ijinlẹ sayẹsni ṣẹṣẹ ṣe ti fi han pe eroja fitami kan to dara fun agọ ara wa ninu ọti.
Fitami ọhun ti wọn n pe ni B6 ni iwadii naa sọ pe o dara fun ọpọlọ ati ẹjẹ, o si tun maa n koju aisan to ba fẹ wọ inu agọ ara.
Bakan naa lawọn onimọ sayẹnsi ọhun tun sọ pe wọn le ri fitami naa ninu oniruuru ounjẹ pẹlu.
Awọn oluwadii naa ti fidi rẹ mulẹ pe ida 15% irufẹ fitami B6 yii lo wa ninu ọti ''beer'' ati ninu ọti ẹlẹrindodo ti kii pa eeyan naa.
Lara awọn eroja ti wọn fi n ṣe ọti ''beer'' ni ọka baba ''barley,'' ''wheat'' ati ''yeast.''
Fitami B6 yii si wa ninu rẹ eyi ti ko le kuro patapata bo ti wulẹ pẹ lori ina to.
A tun maa n ri fitami B6 ninu awọn ounjẹ kan bii ẹran ati ẹja, anamọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọpọ ounjẹ aarọ naa maa n ni eroja fitami ọhun ninu.
Fitami B6 maa n saba wa ninu agọ ara ọpọ eeyan, amọ, o le lọọlẹ nigba mii.
Nigba ti o ba lọọlẹ lo maa n rẹ eeyan tabi ki eeyan fẹ bi.
Awọn oluwadii ti wọn ṣe ayẹwo ọti ''beer'' oriṣii marundinlaadọrin ṣe awari nnkan wọnyi:
- Irufẹ ọti bia ti wọn n pe ni ''Bock'' lo ni eroja fitami B6 to pọ julọ ninu, lẹyin naa lo kan bia ''lagers,'' ''dark lagers'' ati bia ti wọn n fi ọka ''wheat'' ṣe.
- Ọti bia ti wọn fi irẹsi ṣe lo ni fitami B6 ti ko pọju.
- Awọn ọti bia ti kii pa eeyan lo maa n ni fitami B6 to pọ daadaa.
- Ọpọ ọti bia ti wọn ṣe iwadii lori rẹ lo ni ida 20% fitami B6 ninu.
- Amọ, ọkan lara ọti bia ti kii pa eeyan ti wọn ṣe iwadii le lori ni ida 59% fitami B6 ninu.
Ajọ ileeṣẹ eto ilera NHS sọ pe awọn ọkunrin nilo iwọn 1.4mg fitami B6 lojumọ, nigba ti awọn obinrin nilo 1.2mg.
Abọ iwadii ti wọn ṣe naa sọ pe lita bia kan maa n ni iwọn 0.3mg si 1mg fitami B6.
Bridget Benelam to n ṣiṣẹ pẹlu ajọ British Nutrition Foundation sọ pe ọpọ eeyan maa n saba ni anito fitami B6 lara tori o wa ninu awọn ounjẹ kan naa.
''A o ni sọ fawọn eeyan pe ninu ọti ni wọn ti le ri irufẹ fitami yii julọ.
Ko si bi eeyan ko ṣe ni maa jẹ awọn ounjẹ to ni fitami B6 ninu.
Ayafi ti eeyan ba ni awọn arun mii lara loku bii arun kindinrin ati ọti amupara ni eeyan le ni iṣoro,'' Benelam ṣalaye.
O wa rọ awọn eeyan lati maa jẹ ounjẹ to ba ni irufẹ fitami bii B12 ati B2 ninu to maa n wa ninu awọn ounjẹ kan tawọn eeyan maa n jẹ.




























