"Igede Ekiti ni ilé Osun, omi rẹ̀ sàn dé Osogbo ni, ohun tó mú u yíra padà kò di odò ńlá rèé"

Àkọlé fídíò, OSUN
"Igede Ekiti ni ilé Osun, omi rẹ̀ sàn dé Osogbo ni, ohun tó mú u yíra padà kò di odò ńlá rèé"

Ọkan lara awọn odo to gbajumọ nilẹ Yoruba ni Odo Osun Osogbo, eyi ti wọn maa n bọ ni ọdọọdun.

Ni oṣu Kẹjọ ọdọọdun ni wọn maa n ṣọdun Osun Osogbo tawọn ọmọ ipinlẹ naa kaakiri nile ati lẹyin to fi mọ awọn ajoji maa n ba wọn kopa ninu rẹ.

Amọ a gbọ pe ilu Igede Ekiti ni ipinlẹ Ekiti ni odo Osun ti ṣan lọ si ilu Osogbo eyi lo si mu BBC News Yoruba ṣe abẹwo si ilu naa lati tọpinpin rẹ.

Kabiyesi ilu Igede Ekiti, Oba James Adelusi Aladesuru Keji ṣalaye fun BBC News Yoruba pe, baba kan ti orukọ rẹ n jẹ Akẹ ni oun ati iyawo rẹ lo ṣe irinajo wọ ilu Igede Ekiti laye ọjọun.

Ere Osun

"Ede aiyede waye laarin awọn ọmọ lori ẹni to maa gba ipo baba wọn, wọn n binu yira pada si nnkan to wu wọn, ti Osun si yira pada di odo nla"

Oba Aladesuru ni ibi kan to wa ni ẹba ilu Igede Ekiti ni baba naa ti kọkọ duro to fẹ tẹdo sibẹ amọ nigba ti wọn da ifa, ifa sọ pe ibẹ kii ṣe ibẹ ni wọn maa tẹdo si.

"Ifa wọn sọ pe ki wọn tẹsiwaju pe ki wọn ma i tii duro nibẹ."

Ọba alaye naa fi kun pe baba naa ati iyawo rẹ tẹsiwaju ninu irinajo wọn titi ti wọn fi de ibi kan to wa ni ki eeyan to de Iyin Ekiti.

O ni bi wọn ṣe debẹ ni wọn tun gbe ifa janlẹ ti Ifa si sọ fun wọn pe ki wọn gun ori oke to wa ni agbegbe naa lati tẹdo ti wọn si ṣe bẹẹ.

O fi kun pe ibẹ ni baba naa ati iyawo rẹ, Erindo gbe titi ti wọn fi bi ọmọ mẹrindinlogun eyi ti Osun wa lara wọn.

Kabiyesi ṣalaye pe lẹyin ti baba naa jade laye ni ede aiyede waye laaarin awọn ọmọ lori ẹni to maa gba ipo baba wọn.

O ni eyi lo mu ki onikaluku wọn binu, ti wọn si n yira pada si nnkan to wu wọn, ti Osun naa si yira pada di odo nla.

Oju omi Osun ni Ijede Ekiti

Nitori itọju ti Osun ṣe fun awọn eeyan ilu Osogbo ni wọn ko ṣe jẹ ko kuro nibẹ mọ - Iya Osun Igede

Nigba to n kin ọrọ Kabiyesi lẹyin, Iya Osun ilu Igede Ekiti, Ayodele Osunlayo sọ pe Osun lo binu parada di omi to si ṣan lọ si ilu Osogbo ibi ti wọn ti n bọ ọ titi di oni.

Iya Osun naa ṣafihan awọn aga eyi to ni apere ti Osun fi maa n jokoo nigba to wa laye toun atawọn irunmọlẹ mii bii Ogun, Obanifọn ti jọ maa n ṣepade.

"Osun ko kan ṣadede de ilu Osogbo, o rinrinajo de ilu Osogbo ni, ti wọn si gba a ni alejo nibẹ."

Iya Osun tun sọ pe ile Ataoja ilu Osogbo ni Osun kọkọ de si nigba to wọ ilu Osogbo, to si jẹ pe ile Ataoja ni ojubọ Osun tẹlẹ ki wọn to yipada.

O ni nitori bi Osun ṣe n tọju awọn eeyan ilu Osogbo ni wọn ko ṣe jẹ ko kuro nibẹ mọ.

Ilu Igede Ekiti