You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Sanwo-Olu fẹ́ kúrò nípò gómìnà torí àìlera, ló ṣe fa ọwọ́ igbákejì rẹ̀ sókè bíi awọ tó kájú ìlù?
Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Obafemi Hamzat, ti gboriyin fun gomina Babajide Sanwo-Olu bo ṣe fa ọwọ rẹ soke fun ipo gomina ipinlẹ ọhun.
Ṣaaju ni Babajide Sanwo-Olu ti kọkọ fa ọwọ Hamzat soke, to si kede rẹ gẹgẹ bii ẹni ti oun fọwọ si ko dije du ipo gomina ipinlẹ Eko ninu ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ijọba oun.
Ikede Hamzat naa lo waye lẹyin ti wọn ti kọkọ ṣe ipade bọnkẹlẹ kan nile ijọba to wa lagegbe Marina nibi ti Hamzat ti kede niwaju awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC pe oun nifẹ si ati dije fun ipo gomina.
Ninu atẹjade kan loju opo X rẹ ni Hamzat ti fi ẹmi imoore han si bi gomina Sanwo-Olu ṣe fọnte lu erongba rẹ lati dije.
O ni inu oun dun pe Sanwo-Olu ni igbagbọ ninu oun lẹyin ti awọn mejeji ti jọ ṣiṣẹ papọ papọ lati sin ipinlẹ Eko fun ọpọ ọdun.
Hamzat ni afojusun oun ni lati tẹsiwaju iṣẹ rere ti wọn ti n ba bọ latẹyinwa.
A gbọ pe awọn mii to nifẹ si ipo gomina ọhun yatọ si Hamzat ni Abdul-Azeez Adediran, ti ọpọ mọ si Jandor, ati Samuel Ajose, ti inagijẹ rẹ n jẹ SMA Gold.
Bi Sanwo-Olu ṣe fa ọwọ Hamzat soke yii n ṣafihan pe ẹgbẹ oṣelu APC ti n murasilẹ fun eto idibo gomina ipinlẹ Eko lọdun 2027.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade naa, Sanwo-Olu juwe fifa ọwọ Hamzat soke gẹgẹ bii ohun ti gbogbo awọn agbagba ẹgbẹ fọwọ si.
Lẹyin naa lo juwe Hamzat gẹgẹ bii awọ to kaju ilu lati tukọ ipinlẹ Eko.
"Sanwo-Olu ko ṣaisan, bẹẹ ni ko kọwe fi ipo silẹ"
Ẹwẹ, ọọfisi Sanwo-Olu ti sọ pe irọ ni iroyin ti awọn kan n gbe kiri pe gomina ọhun n kọwe fi ipo silẹ latari ilera rẹ ti ko ṣe dede.
Agbẹnusọ Sanwo-Olu, Gboyega Akosile, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.
Gboyega Akosile sọ pe kokoko lara Sanwo-Olu le, o si n ba iṣẹ rẹ lọ lai si wahala kankan.
O ni "Kii ṣe pe irọ ni iroyin naa nikan, amọ awọn to n gbe kiri mọọmọ n ṣe bẹẹ lati ṣi awọn araalu lọna ni.
"Ko si ẹni to n gbogun ti gomina Sanwo-Olu lati kọwe fi ipo silẹ, bẹẹ ni ẹnikẹnikẹ ko sọ pe ko fi ipo silẹ.
"Alaafia ni gomina wa, ilera rẹ ji pepe, o si n ṣi ṣiṣẹ rẹ bii iṣẹ lai yẹsẹ."
Ọrọ yii lo jade lẹyin ti iroyin kan sọ pe awọn alagbara kan ti ke si Sanwo-Olu ko kọwe fi ipo silẹ nitori ilera rẹ, ko si fi igabkeji rẹ, Obafemi Hamzat rọpo.