Wo àwọn owó àjẹmọ́nú òṣìṣẹ́ tí ìjọba àpapọ̀ ṣàfikún rẹ̀ àti ìdí tí NLC ṣe yínmú lórí àfikún náà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni ijọba apapọ Naijiria kede, pe oun ti ṣe afikun awọn owo ajẹmọnu kan fun awọn oṣiṣẹ ijọba lati ipele akọkọ de ikẹtadinlogun, (Grade Levels 01–17), pẹlu atunṣe si ilana owo ifẹyinti wọn .

Ẹka to n ri si owo tawọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria n gba, National Salaries, Incomes and Wages Commission, lo fi ikede yii lede ninu atẹjade wọn.

Ninu rẹ ni wọn ti ṣalaye pe ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ni afikun owo naa yoo gbera sọ.

Atunṣe to ba owo ifẹyinti ni wọn lo ti bẹrẹ lati ọjọ akọkọ ninu oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.

Ṣugbọn ajọ Nigeria Labour Congress (NLC) to n ri si igbayegbadun ati ẹtọ awọn oṣiṣẹ ti sọ pe awọn owo tijọba loun fi kun yii kan ran nnkan kan.

Wọn ni afikun to ju eyi ti wọn gbe de yii lo le tan iṣoro awọn oṣiṣẹ.

Awọn owo ajẹmọnu osisẹ wo nijọba ṣe afikun rẹ?

Duty Tour Allowance (DTA): Eyi ni owo ti ijọba maa n san fun awọn oṣiṣẹ ijọba lasiko ti won ba n rin irinajo to ni i ṣe pẹlu iṣẹ laarin Naijiria.

Owo naa wa fun ile itura ti wọn yoo de si, ounjẹ ti wọn yoo jẹ atawọn nnkan miran to ba yọju lati fi owo gbọ.

Estacode Allowance: Eyi ni owo tijọba maa n san fun awon oṣiṣẹ rẹ to ba n rin irin ajo iṣẹ lọ si orilẹede miran.

Owo ilẹ okeere ni wọn fi n san Estacode yii ni tiẹ, o yatọ si ti DTA to jẹ laaarin orilẹede Naijiria .

Oun naa wa fun otẹẹli, ounjẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Book allowance: Eyi jẹ owo kekere ti ijọba maa n san fun awon oṣiṣẹ to ba n ṣiṣẹ iwadii kan labala ẹkọ.

Won maa n sanwo naa lati ran wọn lọwọ ti wọn ba fẹ ra iwe atawọn nnkan ti yoo mu idagbasoke ba iṣẹ wọn.

Fun owo ajẹmọnu aarin Naijiria (DTA), ida ọgọrun-un afikun ni ijọba fi kun un fawọn oṣiṣẹ ijọba apapọ ti wọn ba n lọ fun irinajo lati fi kun imọ wọn (training programmes).

Koda ko jẹ laaarin ilu ti wọn n gbe naa ni ibi ti wọn ti n lọ fun idanilẹkọọ naa, wọn lẹtọ si DTA ti yoo kaju owo otẹẹli ati bẹẹ bẹẹ lọ bi ijọba ṣe sọ.

Elo ni wọn yoo maa gba bayii?

Bakan naa, nipa bi irinajo naa ba ṣe jinna si, ijọba apapọ ṣayẹwo eyi, won si kede pe awọn ọga agba lẹka ileeṣẹ ijọba (Permanent secretaries) yoo maa gba N664 fun irinajo onikilomita kan (per kilometre).

Awon to wa ni ipele akọkọ de ikẹrin, (GL 01–04 ) yoo maa gba N174 fun irinajo kilomita kan.

Fun irinajo lọ si ilẹ okeere, (Estacode allowances) awọn ọga agba lẹka ileeṣẹ ijọba apapọ yoo maa gba $1,040.

Awọn to wa ni ipele GL 15–17 yoo gba $737, nigba ti awon to wa ni ipele akọkọ si ikẹfa (GL 01-06) yoo maa gba $357.

Fun Irinajo abẹle (DTA), afikun tuntun yii kede pe yoo kan gbogbo ipele ẹka oṣiṣẹ ijọba.

Awọn ọga to wa nipele kẹrindinlogun si ikẹtadinlogun (GL 16–17) yoo maa gba N109,000 bayii, awọn ọjẹwẹwẹ oṣiṣẹ lati ipele akọkọ de ikẹrin (GL 01–04) yoo maa gba ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira (N30,000).

Fun awọn oṣiṣẹ ijọba to n lọ fun idanilẹkọọ ti yoo gba wọn ju ọdun kan lọ ki wọn too pari

Ninu afikun owo naa ni wọn ti mẹnuba awọn oṣiṣẹ ijọba to ba n lọ fun idanilẹkọọ ọdun kan tabi ti yoo ju bẹẹ lọ, ẹgbẹrun lọna aadọjọ (150,000) ni ijọba yoo maa fun wọn gẹgẹ bii owo iwe ati owo ohun ti wọn yoo kọ lẹyin ẹkọ naa.

Awọn to n lọ fun idanilẹkọọ ti ko pẹ to eyi yoo gba N125,000.

Awọn idanilẹkọọ abẹle naa ko gbẹyin, wọn ni awon ọga agba yoo maa gba nipele GL 16–17 yoo maa gba N33,877.5 lojumọ.

Awọn ọjẹwẹwẹ lati ipele akọkọ de ikẹrin yoo maa gba (GL 01–04) N9,034.1 lojumọ.

Afikun ajẹmọnu kan awọn tiṣa kan

Lẹka ẹkọ, wọn ya awon owo ajẹmọnu kan sọtọ fun awọ olukọ, paapaa awọn to n kọ imọ sayẹnsi atawọn to n kọ iṣiro, titi kan awon to maa n w ani yara ayẹwo (Laboratory attendants).

Awọn olukọ imọ sayẹnsi ti wọn w ani ipele kẹrinla (GL 14), yoo gba to N480,000 lọdun.

Awọn to wa ni yara ayẹwo yoo si gba N216,000 lọdun.

Awọn ajẹmọnu miran to tun w ani ni owo idaduro lẹnu iṣẹ, owo iṣipopada lọ si agbegbe mi-in ti I ṣe ida mẹwaa ninu owo oṣu oṣiṣẹ lọdun.

Eyi to si kasẹ rẹ nilẹ ni ti owo to wa fun awon dẹrẹba ti won ko b ani akosilẹ ijamba ọkọ ri. Won ni o

Won yoo maa fun wọn ni 150, 000 lọdun.

Lori atunṣe owo ifẹyinti, Olori awọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria, Didi Walson-Jack sọ pe wọn yoo maa gba ida ọgọrun owo oṣu wọn lọdun, pẹlu owo oloṣooṣu.

Ẹhonu NLC

Ajọ NLC to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ sọ pe gbogbo afikun yii ko to lati tan iṣoro ọwọngogo to n koju awon oṣiṣẹ Naijiria.

Adele Akọwe apọpọ fun NLC, Benson Upah, lo sọ eyi ninu ifọrọwerọ kan to ṣe l'Abuja lọjọ Aiku.

"Bo tilẹ jẹ pe a mọyi ohun ti won ṣe yii, o foju han kedere pe ko to lati tan iṣoro to wa fun awon oṣiṣẹ.

"A rọ awọn agbanisiṣẹ, paapaa ijọba ni gbogbo ẹka lati jẹ ki ọna iranwọ wọn kun ju bayii lọ."