You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèyàn 518 ló kú nínú rògbòdìyàn ètò ìdìbò Ààrẹ Tanzania – Ìwádìí
Apapọ eeyan 518 lo ku ni Tanzania lẹyin oniruru ifẹhonuhan to waye lẹyin esi ibo Aarẹ to waye lọdun to kọja.
Ọrọ yii lo jade lẹyin abajade iwadii igbimọ kan lẹyin eto idibo naa.
Igbimọ naa ti Mohamed Chande Othman dari rẹ ko sọ ni pato awọn gan to wa nidi iṣekupani ọgọrọ eeyan naa.
Awọn ọmọ ẹgbẹ alatako atawọn ọmọ ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan ti fẹsun kan ijọba orilẹede naa pe o lo awọn agbofinro lati fi iya jẹ awọn to fẹhonuhan tako ijọba.
Aarẹ Samia Suluhu Hassan lo bori eto idibo ọhun to si jawe olubori fun saa mii lẹyin to ko ida 98% gbogbo ibo ti awọn eeyan di.
Ẹgbẹ alatako ti juwe esi ibo naa gẹgẹ bii awada kẹrikẹri.
Amọ Aarẹ Samia Suluhu Hassan ti fesi pe ko si makaruru kankan ninu eto idibo naa, ati pe o lọ ni ilana to ba ofin mu.
Lẹyin naa lo di ẹbi idarudapọ to waye lẹyin eto idibo ọhun le awọn atọhunrinwa lori pẹlu ẹsun pe niṣe ni wọn gbiyanju lati yọ oun nipo.
Igba akọkọ ree ti awọn alaṣẹ yoo mẹnuba iye eeyan to ku ninu ifẹhonuhan to waye lẹyin eto idibo naa.
Othman ni 490 ninu awọn 518 eeyan to ba iṣẹlẹ naa lo jẹ ọkunrin.
Igbimọ oluwadii naa ni oniruru nnkan bi eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ, eto oṣelu, airiṣẹ ṣe awọn ọdọ atawọn nnkan mii lo ṣokunfa ifẹhonuhan ọhun.
O ni awọn ajafẹtọọmọniyan lo awọn iṣoro ti orilẹede naa n koju lati ru awọn eeyan soke lati kopa ninu ifẹhonuhan naa.
Amọ ṣa, awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ti bu ẹnu atẹ lu awọn ọmọ igbimọ ọhun pe Aarẹ ni wọn n ṣoju fun dipo ki wọn ṣe ti awọn araalu.