You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Bí ọ̀wọ́ngógó epo bàálù ṣe gbòde, àti lọ sí Hajj lọ́dún yìí di ọwọ́ Ọlọ́run àti ìjọba"
Ọwọngogo epo baalu to gbode bayii tori ogun to n waye laarin Amẹrika ati Itran, ti jẹ kawọn ọkọ baalu akero ni Naijiria pinnu wi pe awọn yoo daṣẹ silẹ l'Ọjọbọ ọsẹ yii tii ṣe ọgbọnjọ oṣu Kẹrin yii.
Awọn olokowo ọkọ ofurufu akero ti sọ pe awọn ni lati daṣẹ silẹ tori ijiroro tawọn ni pẹlu ijọba apapọ atawọn ileeṣẹ to n ta epo baalu ko kẹsẹjari.
Wọn ni owo epo baalu ti wọn n pe ni Jet A1 ti lọ soke pẹlu ida ọọdunrun-un eyi to ti jẹ ki o nira lati tẹsiwaju pẹlu owo irinna ọkọ ofurufu.
Igbesẹ yii yoo ṣakoba fawọn ero ti wọn maa n wọ ọkọ ofurufu papaa julọ fun iṣẹ wọn, ti wọn ba le daṣẹ silẹ bi wọn ṣe sọ.
Loootọ ni minisita fun irinajo ọkọ ofurufu, Festus Keyamo (SAN), ṣepade pọ pẹlu awọn olokowo irinajo ọkọ ofurufu lọsẹ to kọja niluu Abuja, amọ, ipade naa foriṣanpọn.
Lẹyin ipade ọjọ meji ni minisita kede adinku owo ori lẹkun eto irinna ọkọ ofurufu pẹlu ida 30% lati mu irọrun ba okowo awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Naijiria.
Awọn olokowo mọ riri igbesẹ ijọba pẹlu adinku owo ori ti minisita kede, amọ, wọn ni ko tu irun kankan lara iṣoro ọwọngogo epo baalu tawọn n koju.
"Awọn olujọsin ti ijọba ba ṣeranwọ owo fun nikan ni owo ti wọn ti san tẹlẹ, le gbe lọ si Mecca bayii"
Ọwọngogo epo baalu naa si lawọn eeyan ti n para poro pe yoo se akoba fun eto Hajj tọdun yii.
Idi ree ti BBC News Yoruba se tọ onimọ nipa ẹsin Islam kan lọ, Alhaja Kafilat Ahmada Rufai, ti ọpọ eeyan mọ si Kaola, ẹni to tun maa n ko awọn alalaji lọ si Mecca fun isẹ Hajj, lati mọ ipa ti ọwọn epo baalu yii yoo ni lori isẹ hajj tọdun yii.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Alhaja Kafilat Kaola, ti sọ pe ọwọngogo epo baalu yoo ṣakoba fawọn alalhaji to fẹ rinrin ajo lọ si orilẹede Saudi Arabia yala fun Umrah tabi eto Hajj.
Alhaja Kaola ti wọn n pe ni Ummu-li-Muminat sọ pe awọn olujọsin ti ijọba ba ṣeranwọ owo fun nikan ni owo ti wọn ti san tẹlẹ le gbe lọ si Mecca bayii.
O ni ọpọ awọn olujọsin ni wọn ti san owo ọkọ baalu tẹlẹ ti yoo gbe wọn lọ si Hajj, amọ, owo naa ti le sii bayii pẹlu ọwọngogo epo baalu.
"Bi epo baalu ṣe wọn gogo bayii, ati le lọ fun Hajj di ọwọ Ọlọrun ati ọwọ ijọba"
Alhaja Kaola sọ pe ''gbogbo awọn olujọsin to fẹ rinrin ajo lọ si Mecca ni wọn ti gba fisa sọwọ.
Ṣugbọn bi epo baalu ṣe wọn gogo bayii, ati le lọ fun Hajj wọn di ọwọ Ọlọrun ati ọwọ ijọba.
Ijọba lo le ṣeranwọ fun wa nibi ti ọrọ de duro bayii.
Epo bẹntiroolu N200,000 ni mo lo fi gbe ọkọ lọ si Ilorin lati Ibadan funra a mi.
Ko yẹn ko le to bayii, bi ko ba ṣe ọwọngogo epo to gbode.''
Alahaja Kaola ko ṣai ṣalaye wi pe gbogbo eeyan naa kọ lo maa lanfaani lati lọ si Mecca lọdun yii.
''A ti kọ tikẹẹti baalu fawọn kan ni N2.2m tẹlẹ, bakan naa ni a tun ti kọ tikẹẹti fawọn mii ni N2.6m''
Alhaju Kaola ni olujọsin 95,000 ni ajọ alahaji Saudi kọkọ fun ni fisa lati Naijiria.
''Nigba to ya ni wọn ṣe adinku rẹ si 65,000, lati 65,000 yii ni wọn tun ti dinku si 40,250.
Koda, kii ṣe gbogbo awọn 40,250 yii gan an lo pada ri fisa gba.
Gbogbo nnkan yii n ṣẹlẹ nitori ogun to n lọ laarin Iran ati Amẹrika pẹlu Israel.''
Alhaja Kaola ni awọn ti kọ tikẹẹti baalu fawọn kan ni N2.2m, bakan naa lawọn tun ti kọ tikẹẹti fawọn kan ni N2.6m.
O ni bi owo epo baalu ba ti lọ soke sii ni owo tikẹẹti tawọn olujọsin naa yoo san ṣe maa pọ si.
Onimọ ẹsin Islam naa sọ pe awọn alahaji yoo bẹrẹ si ni gbera lati ipinlẹ Oyo titi ipari oṣu yii.
Alhaja naa ṣalaye pe lati ọjọ kẹsan an oṣu Karun un lawọn olujọsin yoo bẹrẹ si ni gbera lọ si Mecca kaakiri agbaaye.
O ni ọjọ kẹrindinlọgbọn ni wọn yoo gun oke Arafa ti ọdun Ileya si jẹ ọjọ keji tii ṣe ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Karun un.
Ipa tí ọ̀wọ́ngógó epo bàálù ti ní lórí ìrìnàjò ọkọ̀ òfurufú ní Naijiria
Allen Onyema to jẹ igbakeji awọn olokowo ọkọ ofurufu akero ni Naijiria sọ pe ''ijọba ti ṣeranwọ fun okowo eto irinna ọkọ ofurufu, ṣugbọn nnkan to wa nibẹ ni pe ijọba gbọdọ wa ojutuu si awọn alagbata epo to n ta epo baalu lọwọn gogo.
Iyanu lo jẹ fun Dangote gan an wi pe awọn alagbata epo n ta epo baalu pẹlu afikun ida 300%.
Epo ti Dangote si n ta fun wa ni owo rẹ kere julọ ti a n ra.''
Idi niyi ti a ṣe fun ijọba ni gbedeke ọjọ meje lati wa nnkan ṣe si iṣoro yii, bi bẹẹ kọọ, a o daṣẹ silẹ l'Ọjọbọ ọsẹ yii.
Lati igba ti ogun Iran pẹlu Amẹrika ati Israel ti bẹrẹ ni epo baalu ti di ọwọngogo ni Naijiria, eyi tawa olokowo ọkọ baalu akero si mọ pe ko wọn to bẹẹ lawọn orilẹede agbaaye mii.
A n fẹ ki ijọba wa nnkan ṣe si ọrọ yii, bi bẹẹ kọọ, baalu kankan ko ni fo fun ọjọ meje bi ijọba ko ba wa nnkan ṣe si ọrọ naa.''
Onyema ni epo baalu tawọn n ra ni N900 tẹlẹ ti di N2,700 si N2,900 bayii.
Koda, o ni awọn alagbata epo kan n ta jala epo baalu kan ni N3,500 bayii.
Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Turkish Airlines fagile irinajo baalu lọ si agbegbe mejidinlogun
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọkọ ofurufu Turkish Airlines ti kede wi pe baalu ileeṣẹ naa ko ni lọ sawọn agbegbe mejidinlogun kan mọ bayii.
Ileeṣẹ naa ṣalaye ninu atẹjade to fi sita wi pe awọn baalu awọn ko ni fo lọ sawọn ẹkun kan kaakiri ilẹ Afirika, ẹkun Middle East, Aaringbungbun Asia ati nilẹ Yuroopu laarin oṣu Karun un to n bọ si oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Awọn ibomiran ti Turkish Airlines ko ni kero lọ mọ bayii ni Aqaba, Billund, Bissau, Freetown, ati Havana.
Awọn ilu ti ileeṣẹ baalu Turkey ko ni i lọ mọ lọwọ yii nilẹ Afirika ni Kinshasa, Luanda, Libreville, ati Lusaka.
Bakan naa ni Tukish Airlines ko ni lọ sawọn agbegbe bii Hurghada, Najaf, Kirkuk, Turkistan, ati Leipzig mọ bayii.
Awọn ibikan wa ti baalu ileeṣẹ Turkish Airlines ko ni fo lọ titi oṣu Kẹwaa ọdun yii, nigba tawọn mii di oṣu Kẹta ọdun 2027 ki ileeṣẹ naa to maa fo lọ sibẹ.
Awọn agbegbe bii Billund ati Leipzig ni Turkish Airlines ko ni tete bẹrẹ si ni maa fo lọ sibẹ, to fi mọ Ferghana ni aaringbungbun Asia.
Amọ, Turkish Airlines yoo si maa fo lati Istanbul lọ si Dar es Salaam, Lusaka ati lati Libreville si Pointe Noire laarin oṣu Karun un si oṣu Kẹfa ọdun yii.