Ohun tí o kò mọ̀ nípa àgbà òṣèré tíátà Yoruba, Elegbeje Ado tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Afrimek Media
Iroyin ibanujẹ lo tun ti sọ lagboole tiata bayii ni Naijiria lẹyin ikede iku agba oṣere nni, Pasitọ Adeshina 'Elegbeje Ado' Taiwo to jade laye.
Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 ni agba oṣere naa ki aye pe o digboṣe lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo da a dubulẹ.
Ẹgbẹ awọn oṣere, Afrimek, ni wọn kede iku oloogbe naa loju opo ayelujara wọn laarọ oni.
Ikede naa sọ pe "Pẹlu ibanujẹ ọkan la fi n kede ipapoda Pasitọ Taiwo Adeshina (Elegbeje Ado), agba oṣere ti a nifẹ si, ẹni to jade laye lẹyin aisan rampẹ lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2026."
"Ipa manigbagbe ti agba oṣere naa ko lagboole tiata, ati awọn ti ẹ ti ko ipa to jọju laye wọn ni a ko le gbagbe.
"Ki Ọlọrun fun yin ni isinmi titi ayeraye, ko si tu awọn mọlẹbi, ọrẹ ati ololufẹ yin ninu lasiko ipenija yii."
Odun bii mẹwaa sẹyin ni oloogbe naa yago fun iṣẹ tiata, to si lọ bẹrẹ iṣẹ ajihinrere, ko to tun bẹrẹ iṣẹ tiata awọn onigbagbọ, to si gbe ere agbelewo Ẹgbẹrun Ọdun jade.
Tani Elegbeje Ado?
Ọmọ bibi ilu Ẹgbado to wa nijọba ibilẹ Ariwa Yewa, ni ipinlẹ Ogun ni Pasitọ Adeshina Taiwo.
Lẹyin ti baba rẹ ku, lo kuro niluu Ẹgbado lati tẹdo si Ibeṣe, ko to lọ siluu Ifọ, titi de Iju Iṣaga, nibi to ti bẹrẹ iṣẹ tiata.
Bo tilẹ jẹ pe Elegbeje Ado ti n ṣiṣẹ tiata diẹdiẹ, ọdun 1979 lo wọ inu rẹ yanyan, to si bẹrẹ si n di gbajumọ kaakiri orilẹ Naijiria.
Oloogbe naa ṣiṣẹ pẹlu awọn ọrẹ rẹ bii Dele Odesola, Musibau Olabulo, Taiwo Owoeye, ati Sina Atanda.
Eremọde lasan ni Elegbeje Ado fi n ṣiṣẹ tiata, ṣugbọn ni kete to de ilu Iju Ishaga, lo pade ẹnikan to n jẹ Oguntade, oludasilẹ ẹgbẹ 'Ọmọdemẹṣọ Theater Group', to si darapọ mọ wọn lẹkunrẹrẹ.
Ọpọ ipa ni oloogbe naa ti kopa ninu ere agbelewo, to si ti jẹ awọn orukọ bii Fadiran, Baba Sefu ati awọn miran, ko to di pe o wa gba orukọ Elegbeje Ado loju pali.
Ere agbelewo Oyindọlapo lo gbe agba oṣere naa jade sita fun araye.
Yatọ si pe Pasitọ Adeshina Taiwo n ṣe iṣẹ tiata, o tun maa n kọrin, paapaa sinu awọn sinima to ba n jade, ẹbun to jogun lara awọn obi rẹ ree.
Lara awọn sinima to ti korin sinu rẹ ni Eegun Eleegun ti oloogbe Jimoh Aliu ṣe lọpọ ọdun sẹyin.




























