Ọlọ́pàá dóòlà ọmọdé méjì lọ́wọ́ ajínigbé l'Oyo, mú ọ̀daràn mẹ́rin pẹ̀lú oríṣiríṣi nǹkan ìjà olóró

Awọn afurasi merin tiu ọlọpaa mu duro, oniruuru ibọn ati ọta ibọn wa lori tabili

Oríṣun àwòrán, Oyo Police Command/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti doola ọmọde meji lọwọ awọn ajinigbe ni ijọba ibilẹ Ibarapa East.

Bakan naa ni awọn agbofinro tun fọwọ ofin mu afurasi ajinigbe mẹrin pẹlu oniruuru ibọn ati nnkan ija olori mii lọwọ wọn.

Lasiko ti wọn koju awọn awọn afurasi adigunjale kan ti wọn ni wọn n ṣọṣẹ nipinlẹ Eko ni wọn fọwọ ofin mawọn ọdaran naa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe aṣeyọri naa n tọka si ipinnu ileeṣẹ ọlọpaa lati dẹkun iwa ọdaran kaakiri ipinlẹ Oyo.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe ṣalaye, lọjọ Ẹti ọsẹ to kọja lawọn janduku agbebọn ya wọ ilu Ebinpejo lagbegbe Lanlate nibi ti wọn ti ji awọn ọmọde gbe lọ.

''Ni kete ti awọn araalu fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti wi pe awọn janduku ajinigbe kan ti gbe ọmọde meji lọ ni Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CP Abimbola Olugbenga, paṣẹ pe ki DPO Lanlate da awọn agbofinro pẹlu awọn ẹṣo Amotekun, awọn fijilante atawọn ọdẹ sinu igbo ki wọn si doola awọn ọmọ ti wọn ji gbe lọ naa.

Awọn agbofinro pẹlu awọn Amotekun, fijilante atawọn ọlọdẹ pada ṣawari ibuba awọn ajinigbe naa ninu igbo.

Bawọn janduku naa ṣe ri awọn ẹṣọ eleto aabo ni wọn ṣina ibọn bolẹ tawọn ẹṣọ eleto aabo naa si da a pada eyi to mu ki ọpọ ninu wọn salọ,'' DSP Olayinka lo sọ bẹẹ.

''Awọn afurasi mẹrẹẹrin ti n ran ọlọpaa lọwọ bayii papaa julọ lati mawọn yooku ti wọn salọ''

''Ikọ eleto aabo fọwọ ofin mu ọkan lara awọn janduku naa, Umaru Usman, to fara gbọta.

Awọn agbofinro tun gba foonu mẹta lọwọ awọn ajinigbe ọhun.

Ọwọ tun tẹ afurasi ọdaran mii, Abdullahi Ahmed, lọjọ Abamẹta ọsẹ to kọja.

Awọn ọlọpaa kọkọ gbe e lọ si ile iwosan ki wọn to ju si ahamọ,'' DSP Olayinka ṣalaye ninu atẹjade to fi sita..

Ileeṣẹ ọlọpaa tun mu Sunday Idowu, afurasi mii eyi to ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajinigbe naa.

Awọn ọlọpaa tun mu Muhammed Ibrahim Shina bakan naa, ẹni to rinrin ajo lati ilu Ilorin lati kopa ninu ijinigbe to waye ni Ibarapa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn afurasi mẹrẹẹrin ti n ran ọlọpaa lọwọ bayii papaa julọ lati mawọn yooku ti wọn salọ.

Ẹwẹ, awọn ọlọpaa ti gbe awọn ọmọ meji ti wọn doola lọwọ awọn ajinigbe naa lọ si ile iwosan fun itọju.

Ileeṣẹ ọlọpaa si n tẹsiwaju iṣẹ iwadii wọn lori iṣẹlẹ naa.