Ìyà tí ọ̀rẹ́ ìyá mi tí mo gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú ìyá mi fi jẹ mí ló sọ mí di ìlúmọ̀ọ́ká alásè – Ilesanmi Mayowa, , Alásè 'Immigrant'

Àkọlé fídíò, 'Ìyà tí ọ̀rẹ́ ìyá mi tí mo gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú ìyà mi fi jẹ mí ló sọ mí di ìlúmọ̀ọ́ká alásè'
Ìyà tí ọ̀rẹ́ ìyá mi tí mo gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú ìyá mi fi jẹ mí ló sọ mí di ìlúmọ̀ọ́ká alásè – Ilesanmi Mayowa, , Alásè 'Immigrant'
Published

Ilesanmi Mayowa jẹ gbajumọ alase ti o gbajumọ pẹlu ase rẹ loju opo Instagram ti wọn ti mọ ọ̀ si 'Cookwithmayor'.

Lọpọ igba awọn eekan oṣere tiata lo maa n tọ ounjẹ rẹ wo lorilẹede Gẹẹsi to fi ṣe ibujoko.

Ninu ifọrọwerọ yii pẹlu BBC News Yoruba, Mayowa ṣalaye itan igbesi aye rẹ fun wa ati bi iya to jẹ lọdọ ọrẹ iya rẹ lẹyin ti iya rẹ dagbere fun aye sọ ọ di ẹni to mọ ounjẹ se, ti o si ti ipasẹ bẹẹ di gbajumọ alase ni ilu London.

Ọgbẹni Mayọwa ni o dara ki atọkun atobinrin mọ ounjẹ n se nitori eyi le tubọ mu ki opo idile o fidi mulẹ daadaa sii.

Alaye lẹkunrẹrẹ ree ninu fidio yii.