Ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé dúkìá afurasí mẹ́tàlá tó ń ṣagbátẹrù ìgbésùnmọ̀mí

Awọn agbesunmọmi wọ aṣọ ologun pẹlu ibọn lọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ajọ SEC to n ri si katakara ọja lawọn ileeṣẹ ti gbẹsẹ le dukia afurasi mẹtala to n ṣegbatẹru fun igbesunmọmi lorilẹede Naijiria.

Ajọ SEC sọ pe awọn ṣe ikede yii lẹyin ti ajọ NSC to n fiya jẹ ọdaran kede orukọ awọn afurasi naa gẹgẹ bi afurasi to n ṣagbatẹru igbesunmọmi ni Naijiria.

Igbesẹ yii gẹgẹ bi ajọ SEC ṣe ṣalaye da lori ofin ọdun 2022 to tako igbesunmọmi eyi to sọ pe ijọba gbọdọ gbẹsẹ le owo, dukia ati nnkan ọrọ aje ẹnikẹni to ba n ṣagbatẹru fun igbesunmọmi lai sọ fun wọn tẹlẹ.

Ajọ naa sọ pe awọn ti jẹ ko di mimọ fun awọn akọṣẹmọsẹ ọja katakara awọn ileeṣẹ lati gbe igbesẹ lori gbigbẹsẹ le dukia awọn eeyan naa.

Wọn ni eyi wa ni ibamu pẹlu ofin to tako igbesunmọmi abala 49 lati gbẹsẹ le dukia iru awọn eeyan bẹẹ.

Atẹjade ti SEC fi sita sọ pe agbara lati ṣi akaunti ati gbẹsẹ le akaunti wa lọwọ awọn akọṣẹmọṣẹ to n ṣakoso ọja okowo katakara awọn ileeṣẹ.

Atẹjade naa tun sọ pe awọn akọṣẹmọṣẹ naa tun lagbara lati gbẹsẹ le dukia awọn eeyan to ba n ṣagbatẹru fun igbesunmọmi.

Awọn akọṣẹmọṣẹ ọja katakara tun ni lati sọ fun ijọba nipa dukia awọn eeyan ti wọn ba gbẹsẹ le.

Loṣu Kẹrin ọdun 2019 ni Ileẹjọ kotẹmilọrun Abu Dhabi dajọ wi pe awọn eeyan naa jẹbi ẹsun siṣe agbatẹru fun ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram ni Naijiria.

Ileẹjọ naa sọ pe awọn afurasi ọhun n fowo ranṣẹ si ẹgbẹ agbesunmọmi ni Naijiria lati Dubai.

Ijiya ti ileẹjọ sọ pe awọn eeyan naa le lọ sẹwọn ọdun mẹwaa tabi ẹwọn gbere.

Ajọ SEC sọ pe gbigbẹsẹ le dukia awọn to n ṣagbatẹru ẹgbẹ agbesunmọmi wa lati le ge ọwọja awọn ẹgbẹ igbesunmọmi lati maa rowo fi ṣe iṣẹ laabi wọn mọ kuru.

Ajọ SEC sọ pe igbesẹ yii tun wa fun igbogun ti kiko owo ilu lọ si oke lọna ti ko tọ ati lati tako igbesunmọmi

Laipẹ yii ni ẹka to n ri si ọrọ aabo lorilẹede America gba awọn ọmọ ilu wọn niyanju lati ma ṣe wa si Naijiria lasiko yii, nitori ijinigbe, igbesunmọmi ati aisi aabo gbilẹ nibẹ kankan.

Ìjọba Nàìjíríà kéde orúkọ àwọn afurasí tó ń ran ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́

Awọn ṣọja naa ṣafihan asia kan ninu igbo ti wọn wa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ṣọja Naijiria lẹyin ija kan pẹlu ikọ agbesunmọmi Boko Haram, ni Borno. Eyi jẹ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2016.

Ko din ni orukọ eeyan mejidinlogoji (48), ati ẹgbẹ mejila ti ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti fi sita bayii gẹgẹ bi awọn ti wọn fura si pe wọn n ran awọn agbebọn lọwọ ni lorilẹede yii.

Iwe orukọ ti wọn fi lede lọjọ Ẹti, ọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii, wulẹ sọ diẹ nipa awọn ti wọn fẹsun kan naa ni.

Igbimọ 'Nigeria Sanctions Committee' (NSC) to gbe awọn orukọ naa jade ko sọ ọmọ orilẹede ti wọn jẹ, bẹẹ ni ko ṣalaye bi ipa ti wọn ti ko ninu igbesunmọmi ṣe pọ to.

Bakan naa ni wọn ko ṣalaye kikun nipa iru ẹgbẹ gan-an ti wọn wa, wọn ko si fi fọto wọn lede lati fi oju wọn han, tabi sọ boya ọkunrin tabi obinrin ni wọn.

Iwe orukọ ti wọn fi lede yii, jade bi igbẹjọ awọn afurasi ẹẹdẹgbẹta (500) ṣe fẹ bẹrẹ lọsẹ yii.

Eeyan to din ni aadọrin (386) ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe wọn jẹbi igbesunmọmi ninu igbẹjọ .

Awọn wo ni wọn darukọ?

Ṣọja kan n bọ lẹyin pẹlu ibọn, agbesunmọmi ti wọn mu wa laaarin, ṣọja kan naa wa niwaju rẹ, o n tọka ọna ti yoo gba fun un. Ọkọ ologun wa ninu aginju ọhun pẹlu, ṣoja kan jokoo lorii rẹ, o n wo agbesunmọmi ti wọn n mu lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ṣọja Naijria mu agbesunmọmi kan lẹyin ti wọn koju ikọ Boko Haram ni Borno, lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2016
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iwe ti Nigeria Sanctions Committee (NSC) fi lede naa ko fi alaye pupọ han.

Ọkan lara awọn afurasi naa ni olori ogun (Quaid), fun ẹgbẹ Islamic State of West Africa Province (ISWAP) Okene.

Oun ni afurasi ti wọn lo ṣọṣẹ nibi ikọlu ile ijọsin St. Francis Catholic Church, Owo, nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti pa ọpọ eeyan lọjọ karun-un oṣu Kẹfa ọdun 2022.

Afurasi yii naa ni wọn lo tun mọ nipa bawọn agbebọn ṣe yabo ọgba ẹwọn Kuje, l'Abuja, lọjọ karun-un, oṣu Keje ọdun 2022.

Afurasi miran ni wọn pe ni ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Ansarul Muslimina Fi Biladissudam (ANSARU).

Ẹgbẹ yii ni wọn lo rọ mọ Al-Qaeda for di Islamic Maghreb (AQIM).

NSC ṣalaye pe afurasi yii ti gba ẹkọ ija pupọ, o si ṣiṣẹ labẹ Muktar Belmokhtar tawọn eeyan mọ si One Eyed.

"Koko iṣẹ rẹ ni ko maa ṣeto ibaraẹnisọrọ labẹnu fawọn agbesunmọmi, o si tun jẹ ọga ninu ado oloro ṣiṣe.

Oun tun ni aṣọna fun olori ẹgbẹ ANSARU, Mohammed Usman (Khalid Al-Bamawi).

Bakan naa lo tun jẹ iranṣẹ ati atọna fun AQIM Katibat, ninu aṣalẹ̀ Algeria ati Mali".

Bẹẹ ni igbimọ NSC wi.

Afurasi ISWAP

Afurasi mi-in ti wọn tun tọka si jẹ olori ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP.

NSC ṣalaye pe ọkan lara awọn olori ẹgbẹ naa ni Guusu-Iwọ oorun ni.

Oun ni wọn lo n wa owo fun wọn nilana ori ayelujara ti a mọ si Crypto currency.

Lara awọn afurasi yii jẹ ọmọ ẹgbẹ Boko Haram bi wọn ṣe wi, wọn ṣe ikọlu, wọn n gba owo itusilẹ, wọn si tun n kọ ẹkọ igbesunmọmi.

Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ẹka to n ri si ọrọ aabo nilẹ America, gba awọn ọmọ ilu wọn niyanju lati ma ṣe wa si Naijiria lasiko yii, nitori ijinigbe, igbesunmọmi ati aisi aabo gbilẹ nibẹ kankan.