Báwo ni ayẹyẹ Ojude Oba 2026 ṣe rí láì sí Awujale Ijebu lórí oyè? Ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ rèé

Obinrin kan wọn aṣọ funfun pẹlu ilẹ lọrun, o si gbe akeregbe funfun sori, ọkunrin kan wọ aṣọ ofi ati fila pẹlu koko lẹnu, nigba ti arabinrin kan naa wọ aṣọ ofi to rẹwa pẹlu ilẹkẹ lọrun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bo tilẹ jẹ Awujale tuntun ko tii jẹ ni Ijebu-Ode titi di asiko yii, sibẹ, eto aṣa ibilẹ awọn Ijebu, Ojude Ọba ti wọn maa n ṣe lọdọọdun tun gbọna ara yọ lọdun yii.

Gẹgẹ bi ilana eto naa ṣe maa n lọ, kabiyesi, Ọba Awujalẹ ilẹ Ijebu ni gbogbo ọmọ ilu naa maa n lọ ọ ki, lati bu ọla ati ẹyẹ fun un ni gbogbo ọjọ ayẹyẹ naa.

Ṣaaju eto ayeye ọdun ọhun to waye lọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun-un ti a wa yii, ni oniruuru awuyewuye ti n waye lori boya eto naa ko ni si lọdun yii.

Ko sohun meji to fa a, bi ko ṣe ti Ọba ti ko si lori itẹ, leyi ti awọn kan nigbagbọ pe ko ni i si kabiyesi ti wọn yoo lọ foribalẹ fun nibi eto naa.

Amọ ṣa, awọn alakoso eto ayẹyẹ naa sọ pe ọba ko si lori itẹ, ko sọ pe ki awọn ma ṣe ayẹyẹ naa, ati pe Ọba Sikiru Adetọna tii ṣe Awujalẹ ana ti sọ pe eto naa ko gbọdọ dawọ duro, yala, oun wa lori aleefa, tabi oun tẹri gbaṣọ.

Ọtunba Fassy Yusuf to jẹ alaga igbimọ eto ayẹyẹ naa sọ pe awọn pinnu lati ṣe ayẹyẹ tọdun yii lara ọtọ, nitori pe awọn ni lati bu ọla ati ẹyẹ ikẹyin fun ọba to mu ọlaju wọnu ayẹyẹ Ojude Ọba.

Ojude Ọba gbọrọgẹjigẹ

Oniruuru aṣọ alarambara ati ẹṣọ aṣaraloge to jẹ olowo nla-nla lawọn ọmọ Ijẹbu wọ nibi akanṣe eto naa.

Oniruuru ẹgbẹ bii mẹtalaadọrun ni wọn kopa nibi eto ayẹyẹ Ojude Ọba ti ọdun 2026, nibi ti ẹsẹ ko ti gbero ninu gbagede Awujalẹ naa.

Bi a ṣe ri awọn rẹgbẹrẹgbẹ lọkunrin, naa la tun ri lobinrin, to si jẹ pe nipele-nipele to nii ṣe pẹlu ọjọ ori ni wọn fi da aṣọ ẹgbẹjọda.

Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ naa, to fi mọ awọn kọmiṣọna ati aṣoju ijọba ni wọn kọwọrin pẹlu rẹ nibi eto ọhun.

Awọn eeyan jankan jankan bii Sẹnetọ Gbenga Daniel to jẹ gomina tẹlẹ, Sẹnetọ Solomon Ọlamilekan Adeọla ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC fa kalẹ lati du ipo gomina lọdun 2027 naa ko gbẹyin nibi eto ọhun.

Nigba to n sọrọ, Gomina Abiodun sọ pe lotitọ ni eto naa ti gbọrọgẹjigẹ, pẹlu oniruuru eto ti wọn tun mu wọnu ayẹyẹ ọhun.

O ni apẹrẹ rere ni ayẹyẹ ọdun yii mu wa, nitori pe ọjọ naa lo pe ọdun meje toun gba ijọba, ti oun si tun n ṣayẹyẹ ọjọ ibi oun, pẹlu bi wọn tun ṣe n sajọyọ awọn ilana ti Awujalẹ ana, Ọba Adetọna fi lelẹ.

Idile Kuku ṣe ayajọ ọdun idile wọn

Ṣaaju l'Ọjọbọ to kọja ni awọn idile Kuku ti wọn bẹrẹ eto ayẹyẹ Ojude Ọba ṣe akanṣe eto adura fun awọn baba nla wọn, ati awọn akọni wọn, to fi mọ awọn to wa laye, to n gbe orukọ naa larugẹ.

Ayajọ ọjọ Kuku ni wọn pe eto naa, eyi ti wọn fi n ṣe iranti awọn akọni to ti filẹ ṣaṣọ bora.

Gbogbo ọjọ to ba ṣaaju ọjọ Ojude Ọba ni eto naa maa n waye ni agboole Kuku to wa niluu Ijẹbu-Ode.

Kaakiri agbaye ni awọn ọmọ idile naa ti maa n wa sile lati ṣayẹyẹ ọdun wọn naa, pẹlu awọn alejo to n tẹle wọn.

Gomina Abiodun kọ lati sọrọ nipa ipo Awujale

Bo tilẹ jẹ pe idunnu nla ni eto ayẹyẹ Ojude Ọba jẹ fun gbogbo ọmọ ilẹ Ijẹbu lapapọ, ti wọn si n ṣe ajọyọ, sibẹ, ẹdun ọkan lo jẹ fun ọpọ wọn, bi gomina ko ṣe mẹnuba ọrọ jijẹ ọba tuntun, eyi to ti n da awuyewuye silẹ lati oṣu Kinni, ọdun 2026.

Iyalẹnu nla lo jẹ fun awọn eeyan to wa nibẹ nigba ti Gomina sọrọ fun bi ogun iṣẹju, ti ko si sọ ohunkohun lati fọkan awọn araalu naa balẹ nipa bi eto naa yoo ṣe lọ.

Bi ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kinni ni ijọba gbẹsẹ le gbogbo eto yiyan ọba tuntun fun Akilẹ Ijẹbu, nitori awọn ẹsun ti wọn lawọn tọrọ kan fi kan awọn Afọbajẹ.