Ọlọ́pàá méjì kú ní ìpínlẹ̀ Osun lẹ́yìn tí ọkọ̀ gbá wọn lójú pópó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti bẹrẹ si n wa awakọ kan to juba ehoro lẹyin to fi ọkọ rẹ ṣekupa ọlọpaa nipinlẹ naa.
Wọn ni oju ọna marosẹ Osogbo si Gbogan, niluu Oogi ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodun Ojelabi lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin.
O fi orukọ awọn ọlọpaa meji ti ọrọ naa kan lede gẹgẹ bii Kehinde ati Tobi lai mẹnuba orukọ wọn keji.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ori alupupu lawọn ọlọpaa meji ọhun wa ki ọkọ ayọkẹlẹ Lexus kan to kọlu wọn loju popo niluu Oogi.
O fi kun pe kete lẹyin iṣẹlẹ naa ni awakọ ọhun na papa bora to si fi ọkọ naa silẹ nibẹ.
Ojelabi sọ pe "Awọn ọlọpaa meji ọhun wa lori alupupu ki ọkọ naa to gba wọn.
Alukoro ọlọpaa ọhun ṣalaye pe "Ọkọ Lexus kan lo gba wọn. Orukọ awọn ọlọpaa naa ni Kehinde ati Tobi."
Ojelabi fi kun pe awọn ti gbe ọkọ Lexus ọhun, to fi mọ alupupu naa lọ si agọ awọn bayii.
Lẹyin naa lo ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, awọn ti si n wa awakọ ọhun ki wọn le tẹ ẹ.
O ni "A ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa."
O pari ọrọ rẹ pe wọn ti sin oku ọkan lara awọn oloogbe ọhun ni ilana ẹsin Musulumi.



























