Àjọ NEMA kéde agbègbè 37 tó wà nínú ewu ẹ̀kún omi, 15 l'Eko, 19 l’Ogun, 3 ní Nassarawa

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

O n bọ o n bọ, amojuto ati igbaradi ti yoo dena rẹ ni aye n dẹ de e bayii.

Eyi wa ni ibamu pẹlu bi ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, National Emergency Management Agency (NEMA), ṣe n kilọ pe isẹlẹ ẹkun omi yoo ṣọṣẹ ni awọn agbegbe ijọba ibilẹ kan nipinlẹ Eko ati Ogun.

NEMA ninu ikilọ tuntun naa sọ pe bi ojo ba ṣe n rọ, to si n pọ ni awọn agbegbe wọnyi wa ninu ewu omiyale.

Agbegbe mẹẹẹdogun (15) ni NEMA kilọ nipa rẹ l'Eko, mọkandinlogun (19), ni wọn kilọ pe ki wọn ṣọra nipinlẹ Ogun, eyi to mu apapọ wọn jẹ mẹrinlọgbọn (34).

Awọn ikilọ ewu ẹkun omi to seese ko waye ni ipinlẹ mẹta nilẹ Naijiria ni ajọ NEMA fi si oju opo X rẹ, @nemanigeria lọjọ Iṣẹgun.

Wọnyi ni awọn agbegbe ijọba ibilẹ ti ọrọ naa kan l'Eko

Agege

Alimosho

Ikeja

Kosofe

Ikorodu

Lagos Island

Eti-Osa

Amuwo-Odofin

Apapa

Badagry

Epe

Ibeju-Lekki

Ajeromi-Ifelodun

Ifako-Ijaiye ati

Lagos Mainland.

Awọn ijọba ibilẹ to wa ninu ewu ẹkun omi l'Ogun

Abeokuta North

Abeokuta South

Ado-Odo/Ota

Ifo

Sagamu

Ijebu Ode

Obafemi Owode

Ewekoro

Odogbolu

Yewa North

Yewa South

Imeko Afon

Ipokia

Awọn yoku l'Ogun ni:

Odeda

Ikenne

Remo North

Ijebu East

Ijebu North ati

Ijebu North East.

Ijọba ibilẹ mẹta lo wa ninu ewu ẹkun omi ni ipinlẹ Nassarawa

Ijọba ibilẹ Nassarawa

Ijọba ibilẹ Doma

Ijọba ibilẹ Toto

Wo ohun ti ajọ NEMA ni ki o se lati dena ẹkun omi to n bọ

NEMA ni kawọn to ba n gbe ni bebe okun lagbegbe naa tete fi ibẹ silẹ, awọn to si n gbe lori ilẹ gbigbẹ naa gbọdọ tete ko awọn koto idaminu wọn daadaa pẹlu bi wọn ṣe sọ.

Wọn fi kun un pe ikilọ yii n waye lẹyin ti ajọ to n ri si oju ọjọ ti kede pe o ṣee ṣe ki ojo ti yoo maa rọ bayii maa pọ si I ju ti tẹlẹ lọ.

Eyi ni wọn lo le fa omiyale lawọn agbegbe ti anfaani idominu geere ko ba si fun wọn, ti wọn ko si tete mojuto o.