Ó pé oṣù kan táwọn ajínigbé jí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé ní Ogbomoso; wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti wáyé látìgbà náà

Oríṣun àwòrán, Others
Oni, ọjọ Aje, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Kẹfa lo pe oṣu kan geerege tawọn agbebọn kọlu ile ẹkọ LA School ati Community High School, Ahoro-Esinele, niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.
Nibi ikọlu naa ni awọn agbebọn yii pa olukọ kan, ji olukọ pẹlu awọn akẹkọọ ti apapọ iye wọn jẹ mẹrindinlaaadọta (46).
Gẹgẹ bi atẹjade ti Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ayanlade Olayinka, fi sita lọjọ Ẹti, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Karun-un ti wọn ji awọn eeyan naa gbe lọ, o ni nnkan bii aago mẹjọ si mẹsan-an aarọ ni awọn ajinigbe yawọ ile ẹkọ naa lati ṣọṣẹ.
Awọn akẹkọọ n ṣeto orin kikọ ti won maa n ṣe lori ila lasiko ti awọn agbebọn naa de ti wọn ṣina ibọn bolẹ, wọn gbe ọga agba ile ẹkọ naa, Abilekọ Rachael Alamu pẹlu awon akẹkọọ ti ẹnikẹni ko mọ iye wọn lọ.
Olùkọ́ àgbà gbé fídíò síta láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ìtúsílẹ̀ wọn
Lẹyin ọjọ meji ti ikọlu naa waye ni awọn ajinigbe naa gbe fidio kan jade nibi ti olukọ agba ile ẹkọ naa Esinele, Rachael Alamu ti n rawọ ẹbẹ sijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Oyo lati ma jẹ ẹ kawọn ku sakata awọn ajinigbe naa.
Arabinrin Alamu sọ ninu fidio naa pe oun ṣe fidio yii lati beere fun iranwọ lọwọ gbogbo eeyan, bẹrẹ lati ọdọ ijọba apapọ Naijiria, Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo, ajọ awọn ọmọlẹyin Kristi, CAN ati gbogbo eeyan lati tete wa bi awọn ṣe maa kuro ni ahamọ awọn ajinigbe naa.
"Mo fẹ ki ẹ bawa yanju ọrọ yii ni itubi inubi ki a maa baa ku sibi.''
Nigba to tun di ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun un yii, to jẹ ayajọ ọjọ awọn ọmọde lagbaye
ni Arabinrin Alamu ti bẹbẹ lorukọ awọn eeyan ti wọn wa ni igbekun naa.
O ni "Ẹ jọwọ, a n bẹbẹ. Oni lo pe ọjọ kẹtala ti wọn ti ko wa, a ṣi wa ninu igbo titi di akoko yii.
"A n bẹ yin, Aarẹ Tinubu, gomina Seyi atawọn ọmọ Naijiria mii ki wọn dide fun iranlọwọ wa.
"Mo ke pe ajọ NUT, ANCOPSS, ki wọn ran wa lọwọ lati ba wọn sọrọ.
"A ko fẹ ki wọn fi agidi ṣe e, ohun ti a bere ni pe ki wọn ba wọn dunadura ki wọn le fi wa silẹ.
"A wa ninu otutu, a wa ninu ojo ati ninu oorun, awa atawọn ọmọ kekere ni a wa nibi. Ẹ jọwọ, a n bẹ yin, ẹ ma jẹ ki wọn fi aye wa ṣofo."
''A o le lọ sibi iṣe mọ, ẹru n ba wa'' – Awọn olukọ ṣewọde
Awon olukọni ni ipinlẹ Oyo ṣe iwọde alaafia lati pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn jigbe nile ẹkọ ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso.
Ifehonuhan naa waye ni ilu Ibadan, Ogbomosho, Oyo ati ilu Iseyin.
Ọkan lara awọn to kopa ninu ifẹhonuhan naa, Odunayo Ajala, ṣalaye wi pe ọpọ olukọ ni ẹru n ba bayii lati lọ sibi iṣe nitori iṣẹlẹ ijinigbe to waye l'Ogbomoso.
Odunayo ni "nibi ti isẹlẹ buruku yìí ti ṣẹlẹ̀ ni mo ti n ṣíṣe ijọba ibilẹ Orire, a jade lati jẹ ki ijọba ran wa lọwọ lati gba awọn akẹgbẹ wa atawọn akẹkọọ wa jade ni ahamo awọn agbebon.
A fẹ ki ijọba ran wa lọwọ, ọmọ ọdun kan aabọ wa ninu awọn ti wọn ko yii.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Iroyin nipa ohun tawọn ajinigbe n beere fun lati gba itusilẹ awọn akẹkọọ naa da awuyewuye silẹ
Lẹyin ọsẹ kan si iṣẹlẹ naa ni Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo tako aba lati bawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe l'Ogbomoso dunaadura.
Adari ile, Họnarebu Adebo Ogundoyin, ninu fidio kan to ṣafihan ijokoo ile igbimọ aṣofin Oyo sọ pe ijọba ko ni sanwo fawọn agbeṣumọmi lati fawọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe lominira.
Ogundoyin sọ ninu fidio naa wi pe ''ṣe to ba jẹ pe ẹyin ni gomina ipinlẹ Oyo, ṣe ẹ maa gba lati fun awọn agbesunmọmi ni owo gobọi, nnkan ijagun, ati agbekalẹ ofin ti ko ni tako wọn lọjọ iwaju?
Ṣe ẹyin maa fawọn agbesunmọmi lawọn nnkan yii ti wọn maa fi gbilẹ si i lagbegbe igberiko ti wọn ti n ṣọṣẹ?''
Adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo sọ pe ọpọ eeyan ni ko mọ ẹkunrẹrẹ nnkan tawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe nijọba ibilẹ Oriire n beere fun.
Họnarebu Ogundoyin ṣalaye pe idi niyi tawọn eeyan fi ni lati ṣe suuru lori ọrọ yii.
O ni ijọba yoo fawọn agbesunmọmi ni igboya lati tubọ maa ṣọṣẹ si i ti wọn ba le fun wọn lawọn nnkan ti wọn n beere fun.
Amọ lẹyin naa ni fidio mii tun jade sori ayelujara nibi ti Arabinrin Alamu ti rọ awọn akọroyin, atawọn to n gbe iroyin nipa ijinigbe naa lati ṣe pẹlẹ, ki wọn ye gbe ohun ti kii ṣe ootọ.
O ni awọn ajinigbe naa ṣafihan awọn nnkan fun awọn pe awọn eeyan n sọ pe awọn n beere fun ofin Sharia ni ipinlẹ Oyo ati owo lati gba itusilẹ awọn, obinrin naa ni ọrọ ko ri bẹẹ.
O ni niṣe ni awọn eeyan n mu nnkan nira sii fawọn nitori awọn ajinigbe naa ni ohun ti awọn n fẹ ko ju lati gba awọn eeyan wọn to wa ni ahamọ silẹ lọ.
Alamu ni "oni lo pe ọjọ mẹrinlelogun ti a ti wa nibi yii, o dabi pe awọn kan n mu ki iṣoro wa peleke sii.
"Wọn fi awọn iwe iroyin kan han wa nibi ti wọn ti kọ sibẹ pe awọn to ji wa gbe n beere fun itusilẹ awọn eeyan kan, wọn beere fun ọkọ, wọn beere fun biliọnu kan naira ati imulo ofin Sharia.
"Awọn nnkan yii kii ṣe ootọ, wọn kan n da iṣoro kalẹ fun wa ni, ko si ẹni to fi tipa mu wa lati maa ṣẹsin Islam, wọn fi wa silẹ laaye wa.
"Wọn o beere fun owo tabi ofin Sharia, wọn o beere fun nnkan ija ogun nnkan ẹyọkan ti wọn n beere ni itusilẹ awọn eeyan wọn.
"A n bẹ awọn eeyan lati ma fi ẹmi wa ṣe oṣelu, a lero pe ijọba maa jiroro pẹlu wọn lati mọ awọn ti wọn fẹ itusilẹ wọn ki awọn naa le gba itusilẹ."
Fidio yii mu kawọn eeyan kan faraya paapaa awọn Musulumi ṣugbọn ijọba ipinlẹ Oyo ni awọn ko ni sọ ohunkohun nipa rẹ.
"Ijọba ti pinnu lati maṣe sọ nnkankan sita lori ọrọ iṣẹlẹ ijinigbe Ogbomoso"
Kọmiṣanna fun eto iroyin ni ipinlẹ Oyo, Ọmọba Dotun Oyelade sọ fun BBC News Yoruba wi pe lati ọjọ ti wọn ti ji awọn akẹkọọ ati olukọ lọ ni Esinele ati Yawota l'Ogbomoso ni ijọba ti pinnu pe oun ko ni maa ṣe arohunbọhun pẹlu ẹnikankan lori iṣẹlẹ naa.
Kọmiṣanna fun eto iroyin ni ijọba ko ni da ẹnikẹni to ba n kọ nnkankan lori iṣẹlẹ naa lohun.
Ọmọba Oyelade ṣo pe nnkan ẹyọ kan to jẹ ijọba Gomina Seyi Makinde logun ni bi awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso yoo ṣe pada wale ni alaafia.
''Ijọba ti pinnu lati ma sọ nnkankan sita lori ọrọ yii, amọ, iṣẹ n lọ lọwọ lori ati doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn wa lakata awọn ajinigbe.
Mo fi n da araalu loju wi pe awọn eeyan ipinlẹ Oyo yoo pada rẹrin-in lori iṣẹlẹ ijinigbe yii.
Ipinlẹ Oyo yoo sí jẹ ipinlẹ akọkọ nibi ti ọrọ awọn ajinigbe yoo ti lojutuu ni gbogbo Naijiria.''
A ti mọ ibi táwọn agbébọn kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso pamọ́ sí - Makinde
Ni ọjọ Aje, ọjọ Kejila oṣu Kẹfa to jẹ ọsẹ mẹrin geerege tawọn eeyan naa ti w ani ahamọ awọn ajinigbe ni Gomina Seyi Makinde gbe atẹjade kan sita pe awọn ti mọ ibi tawọn agbebọn ko awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ni Ahoro-Esinele ati Yawota l'Ogbomoso pamọ si.
O ni ninu igbo ijọba Old Oyo National Park lawọn ajinigbe naa wa pẹlu awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire l'Ogbomoso.
O sọ pe bi igbo ọba naa ṣe tobi to lo jẹ ko nira fawọn ẹṣọ eleto aabo lati le tete doola awọn ti wọn ji gbe ati pe ọrọ naa gba suuru ati ifarabalẹ ki wọn baa le ri awọn eeyan to wa lakata awọn ajinigbe yii doola ni aaye ati alaafia.

























