Iru Ekun nawọ́ gán afurasí ajínigbé méjì, dóòlà èèyàn méjì tí wọ́n jí gbé ní Osun

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ẹṣọ aabo Iru Ekun, Iru Ekun Security Network ti nawọ gan awọn afurasi ajinigbe meji, ti wọn si ri eeyan meji gba kalẹ lọwọ awọn ajinigbe naa ni agbegbe Ora-Igbomina, ipinlẹ Osun.
Ni ọjọru ni ẹṣọ aabo naa ni awọn ṣe iṣẹ naa lẹyin ti awọn gba iroyin pe awọn afurasi ajinigbe ji eeyan mẹta kang be ni ilu naa, ti wọn si ko wọn wọgbo lọ.
Olori ẹṣọ aabo Iru Ekun sọ pe awọn afurasi naa ti wọn jẹwọ pe ọmọ orilẹ ede Niger Republic ni wọn ti wa ṣiṣẹ ibi naa ni Naijiria.
O ni awọn ṣi n ẹnikẹta tawọn ajinigbe naa ji gbe, ti wọn si doola meji laaye lai ni ifarapa kankan.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, ẹni to n ja fun idasilẹ Yoruba Nation, Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho, to tun jẹ oludasilẹ Iru Ekun sọ pe awọn ti fa awon afurasi naa le awọn ọlọpaa Oke-Ila lọwọ fun iwadii to peye ati gbigbe igbesẹ ofin to yẹ lori awọn afurasi naa.
Igboho ni ojuṣe awọn ni lati da aabo bo awọn araalu, ki awọn si dena iṣẹ ibi awọn ajinigbe lai fa wahala rara.
O fi kun pe Iru Ekun jẹ idasilẹ lati ṣiṣẹ ni awọn ilu to wa ni ẹsẹ kuku toju awọn ọlọpaa ko le to, ki awọn si ṣe iṣẹ ni ilana ti ofin gbe kalẹ.
O rọ awọn ori ade ọrun ilẹkẹ atawọn araalu ni ipinlẹ Osun ati agbegbe rẹ lati w ani oju lalakan fi n ṣọri, ki wọn si mu alekun ba iṣamulo awọn fijilante ni agbegbe koowa wọn.
Bakan naa lo ni wọn gbọdọ maa fi iroyin, tabi ti wọn ba kẹfin ohun to ṣe ajoji ni agbegbe wọn to awọn ẹṣọ aabo leti ni kiakia.
Iṣẹlẹ ijinigbe ni Ora-Igbomina yii tun ṣafihan bawọn ajinigbe ati agbebọn ṣe n fi awọn igbo ọba to wa lawọn ipinlẹ Osun, Oyo, Kwara ati Ondo ṣe ibugbe, ti wọn si n ṣe awọn araalu lọṣẹ.
Iru Ekun tun fi kun pe iṣẹ ṣi n lọ lati ṣawari ẹnikan to ku ni aaye ati alaafia.

























