Omoyele Sowore tún fojú balé ẹjọ́ lónìí lórí ẹ̀sùn pé ó pe Ààrẹ Tinubu ní ọ̀daràn, ohun tó bá bọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Ajafẹtọọmọniyan, Omoyele Sowore ti rọ adajọ to n gbọ ẹjọ ẹsun ti ajọ ọtẹlẹmuye DSS fi kan an, Mohammed Garba Umar, pe ko yọ ara rẹ kuro ninu igbẹjọ ọhun.
Sowore lo gbe igbesẹ yii lẹyin to ni oun ko gbagbọ pe oun yoo ri idajọ ododo gba niwaju adajọ naa.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti adajọ naa kọ ẹbẹ Sowore pe ko da ẹsun ti DSS fi kan oun nu.

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Ti ẹ ko ba gbagbe, adajọ yii lo ni ki agbẹjọro Sowore kunlẹ nile ẹjọ loṣu to kọja.
Ṣaaju ni DSS ti pe Sowore lẹjọ lori ẹsun pe o pe Aarẹ Bola Tinubu ni "ọdaran" loju opo X rẹ.
Adajọ sọ pe Sowore gbọdọ wa wi tẹnu rẹ niwaju oun lori awọn ẹsun ti DSS fi kan an.
Ile ẹjọ ọhun tun sọ pe olujẹjọ kọ nnkankan soju opo ibadọre ayelujara rẹ, gẹgẹ bii ẹlẹri kan ṣe fidi rẹ mulẹ.
Nigba to n fi erongba rẹ lede lẹyin ti adajọ kọ ẹbẹ rẹ tan, ajafẹtọọmọniyan ọhun bẹ ile ẹjọ naa, lati ẹnu agbẹjọro rẹ, pe oun fẹ ni gbolohun pẹlu adajọ, ti adajọ si gba si lẹnu.
Ninu ọrọ rẹ, Sowore sọ fun adajọ naa pe oun ko ni igbagbọ kankan pe oun yoo ri idajọ ododo gba niwaju rẹ lẹyin to ti kọkọ paṣẹ pe ki agbẹjọro oun kunlẹ niwaju ile ẹjọ.
Lẹyin naa lo rọ adajọ ọhun ko yọ ara rẹ kuro ninu igbẹjọ naa ki adajọ miran si gba igbẹjọ ọhun lọwọ rẹ.
Agbẹjọro Sowore sọ fun ile ẹjọ naa pe awọn yoo kọ iwe sile ẹjọ naa lori igbesẹ yii.
Ẹwẹ, adajọ ọhun ti sun ogbẹjọ naa si ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2026 ti a wa yii bo tilẹ jẹ pe agbẹjọro Sowore ni ọjọ naa ko rọrun fun oun.



























