A ò tíì wẹ̀ láti ọjọ́ mẹ́ta, kò sí ìná, kò sí omi – Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ibadan figbe ta

Awọn akẹkọ ile ẹkọ giga to wa niluu Ibadan, UI, ṣe ifẹhonuhan ninu ile iwe naa lonii lori awọn iya to n jẹ wọn lẹyin ti ẹka kan ninu awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa da iṣẹ silẹ.
Awọn alakoso awọn akẹkọọ naa ba wọn sọrọ amọ awọn olufẹhonuhan ọhun kọti ikun si ibawi wọn lati fẹhonuhan.
Lẹyin eyii ni wọn bọ si oju ọna to wọ ile ẹkọ naa ti wọn si n da awọn ọkọ to n lọ ati eyi to n bọ duro latari.
Eredi ifọhẹhonuhan naa ko ṣẹyin inira wọn lẹyin iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ti kii ṣe olukọni, NASU, ninu ile ẹkọ ọhun to n lọ lọwọ.

Awọn to n yanṣẹlodi ọhun lawọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ mii yatọ si iṣẹ olukọ nibẹ.
Nigba ti BBC Yoruba de ibẹ awọn akẹkọọ ọhun sọ pe bi awọn ọmọ ẹgbẹ NASU ṣe da iṣẹ silẹ ti mu ọpọlọpọ inira ba awọn.
Wọn ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ naa ni wọn n tan ina mọnamọna ati omi fun awọn to fi mọ gbogbo ohun to n mu igbe aye idẹrun fun awọn akẹkọ ninu ile ikọ naa.
O tun tẹ si waju pe lati ijẹta ni awọn ko ti ri omi wẹ lọsi yara ikawe mọ ti kò sì sí ina ijọba lati ka iwe fún idanwo wọn to n bọ lọna laipẹ.
Ninu ọrọ tirẹ Nice Linus, to tun jẹ akẹkọọ sọ pe awọn akẹkọọ naa ko le fi ara da inira mọ nitori ile-iwosan kan ṣoṣo ti o wa ninu ile ọgba ile ẹkọ naa lo ti di titipa latari iyanṣẹlodi NASU.
O fi kun pe ti ohunkohun ba ṣe akẹkọọ kankan bayii ki wọn to gbe de ile- wosan UCH o ṣeeṣe ki irufẹ ẹni bẹẹ papoda.
Goodluck Akinlawon ati awọn akẹkọ miran naa sọ ẹdun ọkan wọn, ti gbogbo wọn si rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati daa awọn oṣiṣẹ ti ki n ṣe olukọni naa lọhun ohun ti wọn bere fun ki gbogbo nnkan le pada bọ sipo fun wọn.



























