Kí ni pàtàkì Òkúta Dúdú táwọn olùjọsìn máa ń fọwọ́ kan tàbí fẹnu kò ní Kaaba lásìkò Hajj?

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn musulumi to ba n ṣiṣẹ Hajj maa n fọwọ kan Okuta dudu to wa ni Kaaba ninu iṣẹ Hajj eyi ti wọn maa n pe ni Tawaf.

Awọn Alalaaji maa n jija du lati fọwọ kan OKuta naa lasiko iṣẹ Hajj ni Mecca.

Rinrin yika Kaaba nigba meje ni wọn maa n pe ni Tawaf, lasiko yii lawọn olujọsin maa n gbiyanju lati fọwọ kan okuta dudu naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Hajar al-Aswad.

Lọdọọdun ni ọpọ eeyan maa n ti ara wọn, koda wọn maa n tẹ awọn mii mọlẹ nibẹ lati ri pe awọn lanfaani lati fọwọ kan okuta naa.

Awọn mii tiẹ maa n ri pe awọn fẹnu ko okuta ọhun.

Amọ, ṣe o pan dandan fawọn olujọsin lati fọwọ kan okuta yii ninu iṣẹ Hajj, ati pe kini itumọ rẹ gan an?

Onimọ nipa ẹsin Islam Ustadh Aminu Zubairu ṣalaye pe Anabi Muhammad (PBUH) gan an fọwọ kan okuta yii.

O ni awọn musulumi to ba n gbiyanju lati fọwọ kan okuta naa n tẹle apẹẹrẹ Anabi lati gba ibukun to wa nibẹ ni.

N jẹ o pọn dandan fawọn olujọsin ni Hajj lati fọwọ kan Okuta dudu ni Kaaba?

Ustadh Aminu Zubairu Ustaz Aminu ṣalaye pe fifi ẹnu ko okuta naa ko pọn danadan, amọ, o ṣe pataki tori Anabi fọwọ kan okuta naa nigba ti o lọ fun Umrah ati Hajj.

Onimọ nipa ẹsin Islam naa sọ pe gbogbo awọn ọmọlẹyin Anabi lo fẹnu ko okuta naa.

''Amọ, ẹni ti ko ba lanfaani lati fẹnu ko okuta naa le fi igi kan okuta ọhun ki o si fẹnu ko igi naa.

Olujọsin ti ko ba raye lati fọwọ kan oku naa le sẹ bi ẹni pe o fẹnu ko okuta, eyi yoo si jẹ itẹwọgba.

Niwọn igba ti Anabi gan an ti fẹnu ko okuta yii, ti o si maa n nawọ si i nigba mii tori awọn eeyan, awọn olujọsin naa le nawọ si okuta ọhun.

Ki lo maa ṣẹlẹ si iṣẹ isin ẹni ti ko ba lanfaani lati fọwọ kan okuta dudu to wa ni Kaaba?

Ustadh Aminu sọ pe ko ba iṣẹ Hajj jẹ ti eeyan ko ba lanfaani lati fẹnu ko tabi fọwọ kan okuta dudu to wa ni Kaaba.

''Ohun ti a mọ ni pe Anabi fẹnu ko okuta naa, ti eeyan ba maa gba ibukun latari pe o fọwọ kan okuta naa, iru ẹni bẹ gbọdọ ṣe iṣẹ ti Anabi ṣe.

Iru iṣẹ yii lo ni laada tabi ibukun to pọ, eyi tumọ si pe fifi ọwọ kan okuta yii ko pan dandan.

Sunnah lo jẹ tori Anabi n ṣe bẹẹ, iru sunnah yii ko si ba iṣẹ Hajj jẹ,'' Ustadh lo sọ bẹẹ.

Onimọ nipa ẹsin Islam naa sọ pe bi ọpọ olujọsin ṣe maa n gbiyanju lati fẹnu ko okuta naa tabi awọn kan ti wọn maa n fi gbogbo ara wọn kan okuta ọhun ko dara to.

Orisun ati itan to rọ mọ Okuta Dudu to wa ni Kaaba

Onimọ nipa ẹsin Islam ni orisun okuta dudu to wa ni Kaaba wa lara awọn nnkan tawọn onimọ ṣalaye pe o wa ninu Hadiths.

''O wa ninu Hadiths wi pe ojiṣẹ Allah ni orisun okuta yii wa lati Paradise lasiko Sayydina Ibrahim (AS) ati Ismail (AS) nigba ti wọn n lọ kọ Kaaba.''

Ustadh fikun ọrọ rẹ pe okuta funfun kan gan an ni orisun okuta yii.

Amọ, o ni ẹṣẹ awọn eeyan atawọn nnkan to ti ṣẹlẹ si iran ẹda eeyan lo jẹ ki okuta naa di dudu.

Ustadh Aminu sọ pe ipa to pọ ni okuta dudu naa (Al-Hajar al-Aswad) ni ninu iṣẹ Hajj ati Umrah tori o wa ninu Hadiths wi pe Anabi fẹnu ko okuta naa.