Ìtàn ìgbésí ayé 'Bàbá', ìjàpá tó bá Aláàfin Oyo márùn-ún lògbà kó tóó jáde láyé
Gẹgẹ bi itan ṣe wi, ijapa kan lasan kọ ni Bàbá, ijapa to lo to okoolenirinwo ọdun (420) loke eepẹ ni.
Aafin ọba Oyo lo n gbe titi to fi dagbere faye lọsẹ to kọja.
Bo tilẹ jẹ pe ko seni to le sọ pato igba ti ijapa ti wọn n pe ni Baba yii de siluu Oyo, BBC News Yoruba kan si awọn eeyan laaafin Oyo lati gbọ nipa rẹ.
Wọn fidi ẹ mulẹ pe Oyo atijọ ti a mọ si Oyo ilé ni wọn ti gbe Baba wa, ki i ṣe Oyo ode oni ti a mọ si Oyo Atiba.
Bẹẹ, Oyo Atiba naa ti n sunmọ igba ọdun to ti wa.
Wọn fi ye wa pe Alaafin to ba Baba logba ko kere, pupọ wọn ṣipo pada nigba ti ọjọ pe, amọ Ijapa Baba wa nibẹ to n ṣọla laaafin.
"O maa n gbọ ohun ti a n sọ, o si maa n fi ori juba, ko kan le sọrọ bii eeyan ni"
Ọkan lara awọn to ba BBC News Yoruba sọrọ nipa Baba, ṣalaye pe ẹranko lasan kọ ni Ijapa naa.
O ni o maa n gbọ ọrọ ẹnu awọn, o si maa n ṣe ohun tawọn ba sọ fun un, ko wulẹ le fọhun bii eeyan ni.
Gẹgẹ bo ṣe wi:
:Baba maa n juba, yoo lọ siwaju ọfiisi Iku Baba Yeye, yoo gbe ori soke bii igba ti eeyan n juba, yoo si pada wọle rẹ lọ.
"O n gbọ ohun ti a ba sọ, ta a ba si ni ko wọle pada, yoo wọle. Iku rẹ dun wa pupọ, koda, emi bii ẹnikan n sunkun bii ọmọde ni."
Wọn ṣe oku Ijapa naa gẹgẹ bi obinrin oyinbo kan laaafin naa ṣe ṣalaye fun BBC.
O ni awọn ra ọti ẹlẹrindodo, awọn pin in kiri aafin fawọn eeyan lati daroo Baba, ijapa to gbe aafin ọba jaye ori rẹ fun ọdun ti onka rẹ ṣoro lati mọ.



