Ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́, ẹ̀wọ̀n lẹ́sẹ̀, ọwọ́ òfin tẹ pásítọ̀ àti ìyàwó rẹ̀ tó ń so àwọn èèyàn mọ́lẹ̀ ní ìjọ wọn

Oríṣun àwòrán, Department of social development
Ọwọ awọn eleto aabo ti tẹ pasitọ kana ti iyawo rẹ, lori ẹsun wi pe wọn de awọn eeyan mọlẹ pẹlu ṣẹkẹṣẹkẹ lẹkun Ariwa-Ila-Oorun orileede South Africa.
Awọn eeyan ti ko din ni igba la gbọ pe wọn de ni ṣẹkẹṣẹkẹ mọle, nigba ti awọn miran wa nibi ti wọn pe ni ọgba imularada.
Ọgba naa to wa labẹ akoso ile ijọsin agbegbe Mpumalanga, la gbọ pe awọn agbofinro ṣawari rẹ l'Ọjọbọ, ọsẹ to kọja yii.
Awọn alakoso sọ pe wọn ri "awọn ri ipo igbe aye ti ko ni aanu" ti awọn eeyan wa, nigba ti wọn ṣe abẹwo sibẹ, pẹlu bi wọn ṣe ri ọgbẹ lara ọpọ awọn eeyan, ti awọn miran si wa labẹ ide.
Loju ẹsẹ ti ọwọ ti tẹ tọkọtaya naa, la gbọ pe awọn ọlọpaa ti fi ẹsun to nii ṣe pẹlu ijinigbe kan wọn nile-ẹjọ , to si ṣee ṣe ki wọn tun fi kun ẹsun naa.
Lati bi ọdun diẹ sẹyin la gbọ pe ọgba imularada ti n pọ kaakiri South Africa, pẹlu bi awọn eeyan ṣe n lo egboogi oloro lọna ti ko tọna.
Ni ọdun to kọja, ẹka idagbasoke awujọ sọ pe awọn ti ṣawari ileeṣẹ to le ni ọgọrun-un kan ti wọn n ṣiṣẹ lai ni iwe aṣẹ lorileede naa, to si jẹ pe ẹkun Gauteng, nibi ti ilu to tobi julọ, Johannesburg wa.
Ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ati ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mọkanla ni wọn ri ninu yarak an naa gẹgẹ bi agbalagba ni ọgba ileeṣẹ kan ni Mpumalanga.

Oríṣun àwòrán, South Africa Police Service
Tọkọtaya naa sọ fawọn alakoso wi pe eeyan ti ko din ni ọgọta ni awọn n tọju ninu ọgba ileeṣẹ wọn, ṣugbọn nigba ti wọn de bẹ, o jẹ iyalẹnu wi pe awọn to le ni idamẹta iye ti wọn sọ, ni wọn ba nibẹ.
Bẹẹ si lo jẹ pe obinrin to le ni ọgbọn ni wọn wa nibẹ pẹlu.
Awọn ti wọn ba nibẹ, ti igbagbọ wa wi pe wọn ko le ṣe ki wọn ma fa egboogi oloro ni wọn kun inu awọn yara ti wọn ko ni anfaani si baluwẹ ati omi.
"Pupọ ninu wọn lo ti wa nibẹ fun igba pipẹ," awọn alakoso sọ bẹẹ di mimọ.
Gift Skhosana, ọkan lara awọn ti wọn mu nigbekun sọ fawọn akọroyin pe kii ṣe nnkan tuntun bi wọn ṣe n de awọn eeyan ni ṣẹkẹṣẹkẹ.
"Wọn n de wa ni ṣẹkẹṣẹkẹ lati jẹ niya, ni kete ti a ba debẹ," o ṣalaye.
Ṣugbọn pẹlu eyi, Skhosana to ti figba kan ri jẹ ẹni to n mu egboogi oloro lamupara sọ pe ileeṣẹ naa ran oun lọwọ lati wa ni imọtoto, toun si bori ipenija mimu egboogi oloro.
Ẹlomiran ti ko darukọ ara rẹ, sọ pe iriri oun latigba toun ti debẹ, ti sọ oun di ẹni to n nilo iranlọwọ ọpọlọpọ.
Tọkọtaya naa ni wọn n gba ẹgbẹrun mẹta owo ilẹ South Africa, eyi to jẹ ojilelọgọsan owo dọla ati ọtadinlogoje pọun ($182; £137), lati maa fi ran awọn ti wọn n tọju lọwọ.
Idaji owo yii la gbọ pe inu ile ijọsin wọn lo n lọ.
Mẹrinla ninu awọn ti wọn gba itusilẹ yii ni awọn alakoso ti ko lọ sile iwosan fun itọju to pe ye, gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ.
Bẹẹ ni wọn sọ pe awọn mejilelaadoje ni wọn ti pada sọdọ mọlẹbi wọn.
Ju gbogbo rẹ lọ, oni ọjọ Aje, ni awọn tọkọtaya naa foju ba ile-ẹjọ.


























