Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Emmanuel Uduaghan, gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Delta tó jade láyé lẹni ọdún 71

Gomina tleẹri naa
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn mọlẹbi gomina tẹlẹ nipinlẹ Delta, Emmanuel Eweta Uduaghan, ti kede ipapoda rẹ lẹni ọdun mọkanlelaadọrin (71).

Ọjọ Aje, oni ni, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni Uduaghan jade laye, gẹgẹ bi awọn mọlẹbi ṣe kede.

Ninu atẹjade ti ọkan lara awọn mọlẹbi gomina tẹlẹ naa, Toju Anire Uduaghan fi sita lorukọ mọlẹbi, o sọ pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fun awọn.

Aarin ọdun 2007 si 2015 ni Emmanuel Uduaghan fi jẹ gomina nipinlẹ Delta.

Awọn mọlẹbi naa ṣapejuwe iku Uduaghan gẹgẹ bi ẹyi to mu ọkan wọn gbọgbẹ wọn, nitori pe ohun ti wọn ko tẹlẹ ni.

"Nipa ọkan to gbọgbẹ ati ibanujẹ nla la fi n kede iku baba wa, arakunrin wa, ẹgbọn wa, aṣiwaju wa, ọlọlajulọ, Ọmọwe Oloye Emmanuel Eweta Uduaghan, gomina tẹlẹ nipinlẹ Delta, ẹni to jade laye laarọ oni, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Awọn mọlẹbi naa ti sọ pe iku Uduaghan ti ṣi alafo nla silẹ ninu mọlẹbi awọn, ti wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi orison okun ati agba ti wọn n bọwọ fun, ẹni ti ipa rẹ kọja inu ẹbi nikan.

"Iku rẹ ti fi wa sinu ibanujẹ ọkan nla. Ọrọ ko le ṣakawe iru ibanujẹ to wọnu ọkan wa, nipa pipadanu ẹni to jẹ ohun gbogbo fun wa, ẹni ti igbe aye rẹ ti ko ipa to jọju nigbesi aye ọpọ awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Delta, ati ilẹ Naijiria lapapọ," atẹjade naa fi kun un.

Ṣaaju, ko too di gomina, Uduaghan ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii kọmiṣanna feto ilera ipinlẹ naa laarin ọdun 1999 si 2003.

Bakan naa lo tun ṣe akọwe ijọba ipinlẹ Delta laarin ọdun 2003 si 2007, lẹyin eyi lo ṣẹṣẹ di gomina lọdun 2007.

Saa meji ni Uduaghan ṣe gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Delta, ko too gbe ipo naa silẹ lọdun 2015.

Taani Emmanuel Uduaghan?

Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 1954 ni wọn bi Uduaghan nijọba ibilẹ Ariwa Warri, ipinlẹ Delta.

Ọmọ bibi ilu Itsekiri ni Uduaghan.

Gomina tẹlẹ naa lọ sile-ẹkọ Federal Government College to wa niluu Warri laarin ọdun 1968 si 1974.

Lẹyin naa lo lọ kẹkọọ gboye ni fasiti ipinlẹ Benin, gẹgẹ bi oniṣegun oyinbo ati iṣẹ abẹ, ẹka ti MBBS, to fi mọ ẹkọ nipa Anaesthesia.

Uduaghan bẹrẹ iṣẹ ṣiṣe nileese to n ṣe irin ti ipinlẹ Delta, iyẹn Delta Steel Company, gẹgẹ bi oniṣegun oyinbo.

Laarin ọdun 1989 si 1994, o tẹsiwaju iṣẹ ṣiṣe ni oriṣiriṣi ile iwosan bii Westend niluu Warri; Benoni niluu Benin ati Shell to wa niluu Ogunu.

Ọdun 1994 lo da ile iwosan aladani tiẹ silẹ, to si ni di oniruuru ipo mu ninu ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ iṣegun oyinbo ti a mọ si NMA niluu Warri, ati ipinlẹ Delta.

Nípa òṣèlú

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ to jẹ oludasilẹ fun awọn ẹgbẹ bii All Nigeria Congress Association fun ijọba ibilẹ Guus Warri; Grassroots Democratic Movement ni Uduaghan.

Yatọ si eyi, Uduaghan jẹ ọkan pataki lara oludasilẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ni gomina tẹlẹ ọhun jẹ.

Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ọdun 1999 ni Gomina igba naa, James Onanefe Ibori kede Uduaghan gẹgẹ bii kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Delta.

Nigba to wa nipo naa, lo ti daba gbigbe owo oṣu awọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera soke, ti ijọba si gba a wọle, bẹẹ lo tun ṣiṣẹ takuntakun nipa atunkọ awọn ile iwosan kan fun igbayegbadun awọn oṣiṣẹ eleto ilera ati araalu.

Lẹyin eyi, lọojọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2003, wọn tun yan Uduaghan gẹge bii akọwe agbe fun ijọba ipinlẹ Delta.

Ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2008, Uduaghan ati adajọ agba nipinlẹ Delta buwọ lu agbekalẹ ile-ẹjọ alagbeeka lati maa fi dajọ awọn to ba n tapa si ofin imọtoto laarin ilu.

Ọdun 2007 ni Uduaghan dije du ipo gomina ipinlẹ naa, to si bori labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP. Bẹẹ lo tun dije fun saa keji, to si wọle lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2011.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2008 ni Uduaghan kede pe oun ti fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, lati ba ẹgbẹ oṣelu APC lọ.

Lọdun 2019, jade du ipo sẹnetọ lẹkun Guusu Delta, to si padanu sọwọ akẹgbẹ rẹ, James Manager lẹgbẹ oṣelu PDP.

Ṣugbọn ṣa, lọdun 2020, gomina tẹlẹ naa sọ pe oun ti fi APC silẹ, lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu toun pawọpọ da silẹ.

Lẹyin gbogbo rogbodiyan oṣelu, Uduaghan kede ifẹyinti rẹ nidi ọrọ oṣelu.

Nigba to di pe oṣelu ri bakan, Uduaghan pada sidi oṣelu, to si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lọjọ kẹsan, oṣu Karun-un ọdun 2025.

Ẹgbẹ oṣelu APC ni oloogbe naa ko to di pe ọlọjọ de.