"Ọmọ mẹ́fà tí mo bí ló kú sínú igbó lẹ́yìn tí Pásítọ̀ pàṣẹ káwa òbí ìjọ rẹ̀ fi ebi pa ọmọ wa kú", ìdájọ́ yóò wáyé lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Thomas Mukhwana
- Role, Africa correspondent
- Reporting from, Shakahola
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Lonii nile ẹjọ kan lorilẹede Kenya yoo dajọ Pasitọ Paul Mackenzie to n jẹjọ lori oniruuru ẹsun ipaniyan.
Mackenzie atawọn ọmọ ijọ rẹ mọkandinlọgbọn mii ni wọn fẹsun ipaniyan awọn ọmọde 191 kan.
Ẹgbẹ okunkun pasitọ naa ni wọn sọ pe wọn fipa mu awọn ọmọde wi pe wọn o gbọdọ jẹun ki wọn le ba Jesu pade.
Pasitọ naa tun maa n sọ fawọn ọmọ ijọ rẹ wi pe wọn o gbọdọ lo oogun, wọn o si gbọdọ lọ sile ẹkọ tori nnkan to lodi ni.
Mackenzie atawọn iṣomọgbe rẹ mọkandinlọgbọn ti wọn fẹsun kan ti sọ pe awọn o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe awọn ko fipa mu ẹnikẹni.
Enos Amanya Ngala to jẹ adari ẹṣọ eleto aabo Mackenzie tẹlẹ ni wọn kọkọ fẹsun kan, amọ, o di ẹlẹrii ninu igbẹjọ naa lẹyin to bẹbẹ.
Mackenzie atawọn ọmọ ẹgbẹ rẹ mii tun n koju oniruuru ẹsun miran to fi mọ igbesunmọmi ati fifi eto ẹkọ dun awọn ọmọde.
Igba akọkọ ree ti pasitọ naa yoo gba idajọ lori ẹsun ipaniyan.
Awọn alaṣẹ orilẹede Kenya fidi rẹ mulẹ pe oku eeyan to le ni irinwo ni wọn hu ninu igbo Shakahola ni Kenya nibi ti Mackenzie ko awọn ọmọ ijọ rẹ lọ.
Awọn ọkunrin mẹtadinlogun ni wọn gba ti wọn n gbẹ koto ti ko jin ti wọn sin awọn to ba ti ku si.
Owo ti ko din ni $8 ni ẹnikọọkan awọn ọkunrin to n gbẹ ilẹ naa n gba lojumọ.
James to jẹ ọkan lara awọn to n gbẹ koto naa sọ fun BBC wi pe awọn maa n ri oku eeyan mẹta o kere tan ninu koto kan.
James ni oku awọn ọmọde to ṣẹṣẹ ku lo pọ ninu awọn oku eeyan tawọn hu jade.
''A ti ri oku ọmọde mejila ti wọn sin sinu koto kan ṣoṣo ri.
Ni ṣe ni wọn ko oku awọn ọmọde naa sori ara wọn bi ẹni pe eeyan n to aṣọ,'' James lo sọ bẹẹ.
Awọn to n hu awọn oku naa jade sọ pe wọn de oku awọn ọmọde mii lọwọ ati lẹsẹ ki wọn to fi aṣọ yi wọn ninu koto ti ko jin ti wọn sin awọn ọmọ naa si.

Oríṣun àwòrán, Salim Karisa
Bo tilẹ jẹ wi pe Pasitọ Mackenzie ni awọn ọmọ ijọ lati ibomiran ni Kenya, pupọ ninu oku ti wọn hu jade jẹ awọn eeyan to n gbe lagbegbe ilu Shakahola.
Salim Karisa toun naa jẹ ọkan lara awọn to n hu oku awọn eeyan jade sọ pe ''a maa n fi alupupu gbe awọn eeyan lọ sinu igbo Shakahola.
Amọ, iyalẹnu lo jẹ wi pe iru nnkan bayii n ṣẹlẹ ninu igbo yii ti ẹnikankan ko si mọ.''
Stephen Mwiti ranti bi o ti padanu ọmọ rẹ mẹfa sọwọ ẹgbẹ Pasitọ Mackenzie.
O ranti bi o ti lọ koju pasitọ naa ẹni tawọn ọmọde atawọn obinrin wa nile rẹ.
Mackenzie fofin de awọn awọn obinrin wi pe wọn o gbọdọ fi irun silẹ sori wọn.
Idi niyii tawọn obinrin fi maa n fa ori dan ni ṣọọṣi Pasitọ Mackenzie.
Iyawo Mwiti tẹlẹ wa lara awọn ti wọn fẹsun kan pẹlu Mackenzie.
''Ọkan ninu Pasitọ Mackenzie ati emi yoo ba Ọlọrun lalejo ti mo ba pade rẹ lonii,'' o ṣalaye fun BBC.

Oríṣun àwòrán, Mohamed Madi / BBC
''Gbogbo ọmọ mi mẹfa lo ku sinu igbo Shakahola, oku ọmọkunrin mi Samuel nikan ni mo ri ti mo sin,'' Mwiti lo sọ bẹẹ.
Lọdun 2003 ni Pasitọ Mackenzie da ijọ Good News International Ministries silẹ.
Ijọ naa si gbooro si pẹlu ẹgbẹẹgbẹru ọmọ ijọ kaakiri orilẹede Kenya.
Pasitọ Mackenzie ni ileeṣẹ tẹlifisan kan ti orukọ rẹ n jẹ Times TV eyi to maa n waasu lori rẹ ni Malindi.
Lara awọn nnkan ti Pasitọ Mackenzie maa n sọ ninu iwaasu rẹ ni pe lilọ ile ẹkọ tabi ile iwosan jẹ ami Satani.

Oríṣun àwòrán, Ken Mungai / BBC
Dan Paul Mackenzie to jẹ ọmọ Pasitọ Mackenzie ṣalaye pe oun maa n gbe ẹrọ kamẹra ninu ṣọọṣi ọhun.
O ni ẹyin lawọn ọmọde maa n jokoo si, awọn agba si maa n jokoo si aarin, nigba ti gbogbo ijọ maa n kọrin papọ laarọ.
Lọdun 2019 ni wọn o jọsin ninu ijọ naa mọ, ti Pasitọ Mackenzie si morile inu igbo Shakahola to si rọ awọn ọmọ ijọ rẹ wi pe ki wọn tẹle e.
Peter Shukrani ẹni ọdun mẹtalelogun sọ pe mama oun tẹle Pasitọ Mackenzie lọ sinu igbo Shakahola nigba naa.
Shukrani ṣaisan lasiko toun ati mama rẹ wa ninu igbo naa, aisan naa si le gan an tori wọn ko jẹ ki o lo oogun.
O ni awọn maa n gba aawẹ ninu igbo nigba naa, ati pe ounjẹ kekere ni wọn maa n fawọn.
Shukrani wa lara awọn eeyan ti wọn doola ninu igbo naa lọdun 2023.
O si sẹ aisan lọwọ lasiko naa, lẹyin ti iya rẹ da gbogbo oogun to yẹ ki o lo nu.
O ni mama oun gbagbọ ninu nnkan ti pasitọ naa maa n sọ pe ẹṣẹ ni ki eeyan maa loogun.
Shukrani sọ pe oun o ba ti ku, ka ni pe oun ko ri eeyan doola oun ni.

Oríṣun àwòrán, Ken Mungai / BBC
Ẹsun iṣekupa eeyan ti ko din ni 191 ni wọn fi kan Mackenzie atawọn iṣọmọgbe rẹ.
Ọpọ oku awọn ọmọde ti wọn hu jade ni wọn o le dawọn mọ tori wọn ti jẹra gan an.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọ ijọ Mackenzie lo ti ku tawọn mii si wa bi alaiwa, Shukrani gbagbọ wi pe eeyan to dara si pasitọ naa.
Shukrani ni Mackenzie ko fipa mu ẹnikẹni lati gba aawẹ, awọn eeyan lo gbagbọ ninu nnkan to ni ki wọn maa ṣe.
''Mo si ni ifẹ Mackenzie, pasitọ mi si ni,'' Shukrani lo sọ bẹẹ.
Dan Mackenzie to jẹ ọmọ pasitọ Mackenzie gbagbọ pe o yẹ ki baba oun jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
''Oun ni olori wọn, oun si ni gbogbo awọn yoku n tẹle, tori naa, apaniyan ni,'' Dan Mackenzie lo sọ bẹẹ.





























