Iléeṣẹ́ PoS kan tún ṣíwọ́ iṣẹ́ ní Nàìjíríà, ìdí rèé

Ẹrọ POS Onafriq
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ifoworanṣẹ ori ayelujara, Onafriq, ti kede pe oun yoo fopin si ẹka Baxi agent rẹ ni Naijiria, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ naa ko sọ pe oun fẹ kogba wọle ni Naijiria.

Baxi agent naa jẹ ọkan lara awọn ohun elo ileeṣẹ ọhu ti awọn onibara wọn fi n gba owo ati fifi owo ranṣẹ ni Naijiria.

Pupọ awọn oniṣowo kekeke lo n lo Baxi naa fun ẹrọ POS lati gba owo lọwọ onibrara wọn ati lati fi owo ranṣẹ.

Oludasilẹ ati adari Onafriq, Dare Okoudjou, sọ pe pẹlu ireti nla lawọn fi wọ Naijiria amọ o ṣeni laanu pe afojusun awọn kuna ni Naijiria.

Ọdun 2021 ni Onafriq bẹrẹ iṣẹ ni Naijiria lati ilu London ki wọn to ra ileeṣẹ Baxi ti ọpọ mọ si Capricorn Digital Limited lasiko naa lati le fẹ iṣẹ rẹ loju si nipa ṣiṣẹ amulo ẹrọ POS.

Ki ni eredi ti Onafriq fi n fopin si Baxi?

Ninu atẹjiṣẹ ti wọn fi ṣọwọ si ileeṣẹ iroyin Punch, Onafriq sọ pe kii ṣe pe oun ti fẹ fi Naijiria silẹ patapata.

O ṣalaye pe eredi igbesẹ oun ko ṣẹyin bi iye owo ti oun n na lati ṣowo ṣe n pọ si lojojumọ, bi owo dọla si naira ṣe n ja wale ati bi awọn ileeṣẹ alatako mii ṣe n mu ko nira fun oun ni Naijiria.

Ileeṣẹ naa tun ṣalaye pe bi ọrọ aje Naijiria ṣe ri ṣakoba fun oun, to fi mọ bi awọn eeyan ṣe yan lati maa fi owo ranṣẹ si ara wọn lati ori ẹro ilewọ wọn.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, lati ọdun 2024 ti owo naira ti ja walẹ ni wọn ti bẹrẹ si n koju awọn iṣoro.

Bẹẹ ni wọn tun mẹnuba bi awọn eeyan ṣe n fi owo ranṣẹ sira wọn lati apo isuna kan si omiran ti wọn si n din lilo POS ku ati bi ijọba ṣe fi gbedeke si iye owo ti eeyan le fi ranṣẹ tabi gba lori ẹrọ POS.

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, iye awọn to n lo POS Baxi le ni 90,000 kaakiri Naijiria.

Ileeṣẹ naa ti bẹrẹ si n ko awọn onibara wọn to wa lori ikanni Baxi kuro bayii lọ si awọn ori ikanni mii.

Ipa wo ni igbesẹ yii loo ni lara awọn to n lo Baxi?

  • Fun awọn ti wọn wa ni igberiko, eyii n tumọ si pe wọn le ma ri owo na fun akoko diẹ ti wọn ko ba tete bọ si oju opo POS mii.
  • Fun awọn to n fi Baxi jẹun, wọn ni lati tete bọ si oju opo mii ko to pẹ ju. Lara awọn oju opo mii ti awọn eeyan naa le lọ si bayii ni ti Moniepoint, OPay tabi Palmpay
  • O ṣeeṣe ki ileeṣẹ naa padanu awọn onibara kan latari iroyin ẹlẹjẹ ti awọn eeyan le maa gbe kiri pe ileeṣẹ ọhun fẹ kogba wọle ni Naijiria. Ẹwẹ, ileeṣẹ ọhun ko kogba wọle