DSS gbé àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú jíjí àwọn àgùnbánirọ̀ tó lọ láti Ibadan sí Imo lọ sílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Channelstv
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Awọn afurasi ti ọwọ awọn agbofinro tẹ pe wọn lọwọ ninu jiji awọn agunbanirọ ti wọn gbera nilu Ibadan lati lọ sinru ilu ni Imo ti fi oju ba ile ẹjọ lọjọ Iṣẹgun.
Awọn agbofinro DSS wọ awọn afurasi naa ti wọn jẹ marun un lọ siwaju Onidajọ Chukwudifu Oputa ti ile ẹjọ giga kan ni ilu Owerri.
Ẹsun mẹta to da lori igbimọran lati jinigbe, ijinigbe ati nini ohun ija oloro lọwọ ni wọn fi kan awọn afurasi naa.
Orukọ awọn afurasi naa ni Babaginda Aliyu, Aliyu Usman aka Dongo ati Mohammed Ali. Gbogbo wọn lo si ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.
Ẹkunrẹrẹ iroyin yii n bọ laipẹ,






















