Ọ̀rọ̀ láàárín Toyin Abraham àti Funke Akindele tún súyọ lórí ayélujára, ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Funke Akindele/Toyin abrahram/instagram
Gbajumọ oṣere tiata, Toyin Abraham ti sọrọ lẹyin ti fọnran kan gba ori ayelujara nibi ti wọn ti fẹsun kan an pe alatilẹyin rẹ kan n sọrọ ti ko da nipa Funke Akindele.
Lati ọsẹ to kọja ni fọnran naa ti n tan lori ayelujara, ti awọn eeyan si n fẹsun kan pe itakurọsọ to waye laaarin Toyin Abraham ati alatilẹyin rẹ lori TikTok, Bisgold, ti wọn si n sọrọ nipa Funke Akindele.
Ninu fọnran naa, iroyin ni Bisgold n bu Funke Akindele, ti wọn si fẹsun kan pe niṣe ni Toyin Abraham n rẹrin-in labẹlẹ bi Bisgold ṣe n bu Funke Akindele.
Eyi lo ti fa ọpọlọpọ awuyewuye lori ayelujara bi awọn kan ṣe n sọ pe niṣe lo ye Toyin Abraham pa Bisgold lẹnu mọ lori bo ṣe n bu Funke Akindele dipo ẹrin to n rin.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan pe wọn tun sọrọ Iyabo Ojo lori iṣẹlẹ to ti waye laaarin wọn sẹyin nigba ifilọlẹ fiimu Iyabo Ojo.
Wọn tun fẹsun kan pe Toyin Abraham tun sọrọ nipa Kemity ati Itele, ti wọn fẹsun kan awọn to n ṣatilẹyin fuun wọn maa n ṣi oju opo ayelujara lati fi maa bu awọn akẹgbẹ wọn mii.
O ni Kemity wa lara ẹni ti oun ri bi ọmọ.
Amọ dipo ki Toyin Abraham sọrọ lori ẹsun naa, Toyin Abraham lo akọle ti gbajumọ ori ayelujara kan Bukky Majek, ẹni to jẹ ololufẹ Toyin.
Ohun ti Bukky Majek kọ soju opo rẹ ni pe awọn fẹran Toyin Abraham ati pe ko si ohunkohun to le ṣe to le buru loju awọn.
O tun kọ pe gbogbo awọn to n duro de iṣubu Toyin Abraham maa dabi ẹni to n wa iṣubu akan to maa pẹ leti omi nitori Ọlọrun lo n bu kun.
Fọnran yii lo tun bi awuyewuye to ti n waye laaarin funke Akindele ati Toyin Abraham to ti n waye fun igba pipẹ diẹ.
Lara eyi to ṣẹlẹ laipẹ yii ni bi Funke Akindele ṣe kọ lati da Toyin Abraham lohun nigba to n ki nibi ayẹyẹ Iyabo Ojo kan ti wọn ti pade ni oṣu diẹ sẹyin.
Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu Toyin Abraham lori fọnran yii ni awọn mii n sọ pe oun gan kọ lo n bu Funke Akindele ati pe ẹni to gbe fọnran naa sita nigba to jẹ pe ọrọ aarin ara wọn lo yẹ lati bawi.



























