Ìgboro ti dàrú ní France lẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn tó wáyé níbẹ̀, ọlọ́pàá mú èèyàn 1,200

Awọn oluwọde ni France
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Igboro ti daru kaakiri orilẹede France leyin ifẹhonuhan to waye nibẹ lori inira to n waye lawọn ile ẹkọ ati ọwọngogo to gbode.

O kere tan, eeyan 1,200 ni agbofinro ti fi ṣikun ofin mu lẹyin ti ifẹhonuhan naa gbọna mii yọ, ti eeyan bii 550,000 si ya si aarin igboro.

Ni Paris, ija waye laarin awọn ọlọpaa atawọn oluwọde lẹyin ti ọlọpaa gbiyanju lati fi gaasi tajutaju tun awọn eeyan naa ka.

Wọn dana sun ọpọ ile ni olu ilu orilẹede naa atawọn agbegbe mii, ina ọhun pọ to bẹẹ ti awọn orule awọn ile kan ja lulẹ.

Yatọ si awọn ile ti wọn dana sun, awọn eeyan tun bẹrẹ si n ja ṣọọbu lọpọ ibi, bi wọn ṣe n ji awọn ọja inu ṣọọbu naa ko ni wọn n ba ọpọ dukia jẹ.

Ile to n jo ati ọkunrin to gbe asia orilẹede naa dani to kọ ẹyin si kamẹra

Olootu ijọba, Sébastien Lecornu sọ pe ọlọpaa 150 lo ti farapa ninu ifẹhonuhan naa byaii.

Ni Paris, ifẹhonuhan ọhun ko kọkọ mu idarudapọ lọwọ.

Awọn kan lara awọn oluwọde naa sọ fun BBC pe awọn kii ṣe onijagidijagan, amọ atunṣe lawọn n fẹ nitori nnkan ko lọ bo ṣe yẹ lorilẹede naa.

Amọ bi iwọde naa ṣe n tẹsiwaju lawọn eeyan bẹrẹ si dana laarin adugbo ti wọn si bẹrẹ si n sọ ina si awọn ọkọ to wa lẹba ọna.

Awọn oluwọde dana sun awọn ile iṣẹmbaye

Lara awọn ile ti wọn dana sun

Lara wọn ibi ti wọn sọ ina si lawọn agbegbe iṣembaye to ṣe pataki bii Place de la République.

Wọn ko ọpọ ọja lọ ninu awọn ṣọọbu, o kere tan, wọn dana sun ile ounjẹ kan, akọroyin BBC si foju gaani ija laarin awọn kan lara awọn oluwọde naa.

Awọn ọlọpaa ko gbọregbe koju awọn kan, wọn si n fi ponpo ọwọ wọn na awọn mii ninu awọn olufẹhonuhan ọhun.

Alakoso ilu Lyon, Grégory Doucet sọ pe ibanujẹ nla lo jẹ fun pe wọn dana sun ọọfisi irinajo afẹ to wa nibẹ.

O sọ fun ileeṣẹ iroyin BFMTV pe ọọfisi naa jẹ ile iṣẹmbaye to ṣe pataki si itan orilẹede naa.

Ọlọpaa sọ pe awọn kan lara awọn oluwọde naa ko gba ọkọ panapana laaye lati lọ pa awọn ina ti wọn bẹrẹ rẹ.

A gbọ pe ado oloro kekere kan ge ọwọ ọkunrin kan ni Saint-Étienne.

Régis Juanico to jẹ alakoso agbegbe naa sọ pe irufẹ iṣẹlẹ naa kii ṣe eyii to yẹ ko waye rara.

Ki lo fa ifẹhonuhan naa?

Ṣaaju asiko yii ni gbẹgbẹrun awọn akẹkọọ ti kọkọ n ṣewọde tako bi ko ṣe si awọn olukọ to to lawọn ile ẹkọ girama orilẹede naa.

Wọn tun n sọ pe pupọ awọn ile ẹkọ naa ni ọjọ ti lọ lori rẹ.

Yatọ si awọn akẹkọọ yii, awọn ẹgbẹ oṣiṣe atawọn egbẹ mii tun n darapọ mọ wọn.

Lara awọn ẹgbẹ to darapọ mọ wọn ni gilets jaunes (tabi "yellow vest") to fẹhonuhan lodi si ọwọngogo fun ọdun kan o le lọdun 2018, eyii to jẹ ifẹhonuhan to pẹ julọ ninu itan orilẹede naa.

Minisita fun ọrọ abẹlẹ sọ pe awọn kan mọọmọ fi ifẹhonuha naa da igboro ru ati lati ba dukia jẹ ni Marseille, Rennes, Toulouse ati Angers.

Lara awọn ibi ti wọn ti ba awọn dukia jẹ julọ ni Grenoble, Avignon, Pau, Montpellier ati Valence.

Ni paris, wọn ja ile itaja aṣọ, nigba ti wọn ja ṣọọbu ti wọn ti n ta iPhone ni Lille, ti wọn si ko gbogbo foonu inu ṣọọbu ọhun lọ.