Ta ni Tenia Abraham, òṣèré tíátà tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 32?

Oríṣun àwòrán, Tenia Abraham/Instagram
Ọfọ nla mii tun ṣẹ ni lagbo oṣere tiata Naijiria bi oṣerebinrin, to tun jẹ arinrin oge ṣe tun ki duniya pe o digba.
Tenia Abraham, ẹni ọdun mejilelọgbọn ni awọn ẹbi rẹ kede iku rẹ loju opo Instagram rẹ lọjọ meji sẹyin pe o dagbere faye ni ọjọ Kẹtala, osu Kẹwaa, ọdun 2026.
Atẹjade to wa loju opo Instagram rẹ naa ṣalaye pe ọjọ Abamẹta, ọjọ Kẹtadinlogun ni oku Tenia Abraham wọ kaa ile sun ni itẹ oku Gudu to wa ni ilu Abuja.
Ṣaaju ni awọn ẹbi rẹ ti kọkọ kede iku rẹ lori TikTok lọjọbọ, ọjọ Kẹẹdogun, ti wọn si juwe rẹ gẹgẹ bi ẹni to ni ẹbun, ọmọ to nifẹẹ awọn obi rẹ.
Atẹjade naa ṣalaye pe aisan kindinrin lo ṣokunfa iku Tenia Abraham, ti wọn si ni ọdun 1993 ni wọn bii ko to jade laye lọjọ Kẹtala.
Atẹjade ọhun sọ pe Tenia Abraham nipa ninu igbeyae awọn eeyan paapaa pẹlu iṣẹ oṣere to yan laayo, ti ipa rẹ ko si le parẹ laye mọ.
"O le ti jade laye ṣugbọn ẹbun rẹ, ẹwa atawọn iwa rere rẹ jẹ ohun ti a ko le gbagbe laelae."
Ni oṣu Kẹjọ ọdun ni Tenia Abraham gbe aworan re kan soju opo Instagram rẹ, to si kọ ọrọ si abẹ aworan naa gbogbo eeyan lo maa fi aye silẹ lọjọ kan, ki gbogbo eeyan maa fi ifẹ han sira han.
Ta ni Tenia Abraham?
Ẹni ọdun mejilelọgbọn ni Tenia Abraham Omenogor gẹgẹ bi atẹjade tawọn ẹbi rẹ fi sita ṣe sọ.
Ọdun 2020 ni irawọ rẹ bẹrẹ si ni tan nigba to gbe ipo kiini nibi idije ẹwa, to si di obinrin to rẹwa julọ ni South South.
Oṣere fiimu tẹka awọn to maa n sọ ede Gẹẹsi lo n ṣe.
O ti kopa ninu ere bii Strained, Just Wounds, The Last Jollof, Whispers to the Spirit ati bẹẹ bẹẹ lọ.





























